Eyi ni aṣiri iku to pa awọn oṣere tiata meji lẹẹkan naa

Faith Adebọla, Eko

 

Ọkan ninu awọn oṣere to gbajumọ ninu ere ori tẹlifiṣan elede eebo ti wọn pe akọle ẹ ni ‘Fuji House of Commotion’, Abilekọ Ṣọla Awojọbi Ọnayiga, to kopa ‘Ireti’ ọlọwọ ṣibi ninu ere naa ti jade laye.

Ba a ṣe gbọ, nnkan bii ọsẹ meji ni wọn ti gbe mama naa digbadigba lọ sileewosan ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti ipinlẹ Eko, iyẹn Lagos State University Teaching Hospital, latari aisan abẹnu kan to kọ lu u. Aaye ti wọn si ti n tọju awọn alaisan to le pupọ (ICU), ni wọn gba a si latari aarẹ lile koko ọhun.

 

Owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjidinlogun, oṣu Keje yii, lobinrin naa ju awa silẹ, o mi eemi ikẹyin.

Oluṣayẹwo fiimu kan to sun mọ oloogbe naa daadaa, Ọgbẹni Shaibu Husseini, lo kede iṣẹlẹ yii lori ikanni fesibuuku rẹ lori ẹrọ ayelujara, o ni: “Mo gbọ laipẹ yii pe oṣere to ṣe bẹbẹ lori tẹlifiṣan, to tun gboye jade nileewe ẹkọṣẹ tiata, Aunti Ṣọla Ọnayiga, ti dagbere faye, owurọ yii ni wọn lo dakẹ. Mama, sunre o.”

Oloogbe yii dije fun ipo aṣofin ipinlẹ Eko labẹ asia ẹgbẹ oṣelu SDP lọdun 2015 lati ẹkun idibo Ikorodu kin-in-ni, ọmọ bibi ilu Ikorodu ni.
O tun gbajumọ ninu ere tẹlifiṣan Checkmate, bẹẹ lo kopa ninu ọpọ fiimu agbelewo.

 

 

Bi wọn ṣe n tufọ Adeyiga lori ẹrọ ayelujara, bẹẹ ni iṣẹlẹ aburu mi-in tun ṣẹlẹ si gbajugbaja oṣere tiata to kopa Anita ninu fiimu ‘Domitila’ lọdun 1996, Abilekọ Ada Ameh, oun naa jade laye niluu Warri, ipinlẹ Delta.

Ilu Eko ni wọn bi obinrin arẹwa yii si lọdun 1974, iṣẹ tiata si lo sọ ọ dolokiki, tori o fakọ yọ ninu fiimu Domitila ati ere ori telifiṣan kan ti wọn p’akọle ẹ ni The Johnsons, nigba yẹn.

 

 

Olori ẹgbẹ awọn oṣere tiata, Emeka Rollas lo fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni osibitu ileeṣẹ NNPC lobinrin naa dakẹ si, lẹyin ti aisan kan kọ lu u lojiji nibi to ti ṣabẹwo si ileetaja ileeṣẹ epo kan niluu Warri, to si ṣe bẹẹ doloogbe.

Lọdun to kọja ni ọmọ kan ṣoṣo ti oṣere yii bi doloogbe

Leave a Reply