Eyi lohun to n fa ede aiyede laarin emi ati Arẹgbẹṣọla – Gomina Oyetọla

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, ti sọ pe ọpọlọpọ ariwo ati ahesọ to n lọ kaakiri nipa oun ati Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla to gbejọba fun oun lo jinna si ootọ.

Oyetọla ṣalaye pe ajọṣepọ to dan mọnran lo wa laarin awọn mejeeji, ṣugbọn ọna iṣejọba to yatọ sira wọn lo n fa aawọ.

Nibi eto kan ti ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ OSBC fi ṣe iranti ayẹyẹ ọgbọn ọdun ti wọn da ipinlẹ Ọṣun silẹ ni Oyetọla ti sọ pe oun ko le ṣiṣẹ ta ko ẹni ti oun ṣiṣẹ labẹ rẹ gẹgẹ bii olori oṣiṣẹ lọọfiisi gomina fun odidi ọdun mẹjọ.

O fi kun ọrọ rẹ pe “Ibaṣepọ wa dan mọnran, mo ri i gẹgẹ bii arakunrin mi, ko si wahala kankan. Mo ṣin in titi to fi ṣaṣeyọri fun odidi ọdun mẹjọ, bawo ni mo ṣe waa maa ṣiṣẹ ta ko o bayii?

“Ṣugbọn nigba ti a ba n sọrọ nipa iṣejọba, ero ati afojusun awa mejeeji yatọ, ko si le ṣe ko ma ri bẹẹ. Ọtọọtọ ni nnkan to maa n wu ọmọ-iya meji gan-an, eleyii ko gbọdọ di ariwo rara.”

Nigba to n sọrọ nipa wahala inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọṣun, Oyetọla sọ pe ko si ija kankan ninu ẹgbẹ naa rara, erongba lo kan yatọ sira wọn.

O ni bo pẹlu bo ṣe jẹ pe ohun ti awọn kan n reti latibi iṣejọba oun kọ ni wọn ba, sibẹ, eleyii ko di afojusun iṣejọba oun lọwọ rara, oniruuru iṣẹ idagbasoke lo si n lọ laarin ipinlẹ Ọṣun.

Gomina sọ pe ẹni alaafia ni oun, ipinlẹ alaafia ni wọn si mọ Ọṣun mọ, idi si niyi ti alaafia fi gbọdọ maa jọba ninu ẹgbẹ APC ati ni ipinlẹ Ọṣun lapapọ.

O ni mọlẹbi kan ni ẹgbẹ oṣelu APC jẹ, awọn si mọ ọna ti awọn n gba lati yanju aawọ to ba ṣẹlẹ laarin awọn, idi niyi ti ko fi dara lati maa gbe ara awọn lọ sile-ẹjọ niwọn igba to jẹ pe awọn le yanju ohun gbogbo to ba ṣẹlẹ nitubi-inubi.

Gomina waa ki gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ku ayẹyẹ idasilẹ ọgbọn ọdun, o dupẹ lọwọ awọn ti wọn ṣiṣẹ takuntakun fun aṣeyọri ipinlẹ naa, o si ṣeleri lati ma ṣe ja awọn araalu kulẹ ninu igbẹkẹle wọn ninu iṣẹjọba rẹ.

 

Leave a Reply