Eyi ni ajọṣe emi ati Ayinla Ọmọwura — Adewọle Onilu-ọla

Ko ma baa di pe ọjọ a ba ku la a dere, eeyan ko sunwọn laaye ti awọn eeyan maa n sọ ni ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Ẹgbe awọn ololufẹ orin Ayinla Ọmọwura (Ayinla Omowura Music Lovers Club International) ṣe tẹ pẹpẹ ayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹtadinlọgọrun-un (97), fun baba agba, Alaaji Abdulramọn Adewọle Alao (Onilu-ọla).  Wọn lawọn fẹẹ mọ riri baba naa ko too di pe ọlọjọ yoo de, awọn fẹẹ ti oju baba ṣẹyẹ to larinrin fun wọn.

Adewọle Onilu-ọla to lulu fun Oloogbe Ayinla Ọmọwura to bẹẹ to jẹ Ayinla funra ẹ pe e lọgaa oun.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2020, ni ayẹyẹ ọjọọbi ti wọn fẹẹ ṣe fun baba yii yoo waye.  Lisabi Elite Club, to wa ni Idi-Aba, l’Abẹokuta, ni eto naa yoo ti waye gẹgẹ bi wọn ṣe fi lede.

Adewọle onilu-ola la ba pe ni ejika ti ko jẹ ki ẹwu bọ lọrun Ayinla, bẹẹ naa lo si ṣe jẹ pe Oloogbe Ayinla Ọmọwura ni atanpako ti ko jẹ ki ọwọ di ilagba fun baba, kadara to wọn pọ o kuro ni wasa.

Nitori ajọṣepọ ti ko ṣee gbagbe yii, ati bi ko ṣe si beeyan yoo ṣe darukọ Ayinla ti ko ni i pe Adewọle onilu-ola ni ALAROYE fi ṣabẹwo si baba nile wọn lọsẹ to kọja, l’Abẹokuta.

Baba ba ADEFUNKẸ ADEBIYI sọrọ lori ajọsẹpọ awọn ati Ọmọwura, bii pe ana yii ni gbogbo ẹ ṣẹlẹ lo ṣe ri nigba ti Alagba Adewọle ṣi gbogbo ẹ lawẹlawẹ. Adewọle ṣi ni laakaye to pe perepere, wọn ko ṣe arán kan bayii pẹlu ọjọ ori wọn.  Bayii lo ṣe lọ.

ONILU-ỌLA

Emi ni Alaaji Abdulramọn Adewọle Alao  Onilu-ọla, Ọkọ Silifa, Baba Silifa. Emi ni mo pe Ọmọwura pe ko maa waa kọrin fun mi, ilu lemi n lu, oun n kọrin.

Mo jẹ ọmọ Imala, mo si tun jẹ ọmọ Idere Ile, titi de Abẹokuta nibi. Ile Alayande nile wa ni Ẹlẹga, l’Abẹokuta.

Iṣẹ idile ni ilu lilu jẹ fun mi, ẹgbọn baba mi torukọ wọn n jẹ Raimi Alayande lo fi ilu le mi lọwọ pe ki n maa lu u.

Mi o lọ sileewe kankan: Awọn obi mi ko ran mi nileewe, ilu lilu yii ni wọn fi kọ mi. Loju aye wọn ni wọn ti mọ pe emi Adewọle maa gbe orukọ wọn ga. Mo kọṣẹ aṣọ ofi hihun, mo ti n ṣe iyẹn tẹlẹ, ṣugbọn nigba to ya, iṣe ilu gba iṣẹ aṣọ ofi yẹn lọwọ mi.   

 

 

Ki n too pade Ayinla Ọmọwura

Mo n lulu fawọn bọisi, awọn wundia. Wọn maa n pe mi lawọn adugbo bii Mọkọla, Ajitaadun, titi de Ikereku. Awọn maa n kọrin nigba yẹn funra wọn ni, emi maa ba wọn lulu si i.

Bi mo ṣe pade Ayinla Ọmọwura

Ti mo ba lọọ ṣere nigba mi-in, awọn ti mo lọọ lulu fun aa ni ki n mu olorin wa. Niru igba yẹn ni mo maa n mu Ayinla jade pe ko waa lọọ kọrin si ilu ti mo ba lu.

Ayinla lohun orin daadaa, ọdọ ẹnikan ti a n pe ni Ọṣọ lo ti n gberin nigba yẹn. Mo maa n wa a kiri pe ko jẹ ka jọ jade ni.

Igbogila ni ode ti mo kọkọ mu Ayinla lọ ta a ti lọọ ṣere. O tiẹ sọ fun mi lọjọ ti mo fẹẹ mu un lọ si Igbogila yẹn pe oun lode orin pẹlu ọga oun. Mo ni ko lọọ sọ fun ọga ẹ pe emi naa fẹẹ mu un jade, o si lọ, ọga ẹ gba pe ko tẹle mi, ṣugbọn o ni ko ma pẹẹ de o, ba a ṣe lọ niyẹn.

Afi ba a ṣe de ibi ere yẹn ti wọn sọ fun wa pe wọn ti ṣe ikomọ ta a tori ẹ wa lanaa, a o le ṣere kankan mọ. Haa, irọlẹ la dẹ debẹ, ilẹ ṣu wa sibẹ ni. Mo waa ni ki wọn ba mi wa ina gaasi ta a maa n tan nigba yẹn (Gas lamp) mo ni a maa bẹrẹ ere naa ni, a o ṣaa ni i pada s’Abẹokuta bẹẹ.

Bi Ayinla ṣe n kọrin ti emi n lulu niyẹn. Ayinla dẹ mọ ọn jo, bi mo ṣe ni ko ma jo sorin to n kọ niyẹn, la ba kọja si isọ awọn ẹlẹran. Awọn bii meloo ta a jọ lọ naa n gbe orin naa, bo ṣe di pe awọn eeyan waa n wo wa niyẹn ti wọn n fun wa lowo. Onitọrọ, onisisi, oniṣike kan, bi wọn ṣe n fun wa lowo niyẹn. Ibi ta a ti ri owo mọto ta a fi pada wa sile niyẹn.

Igba to tun di ọsẹ keji, wọn tun pe mi pe wọn fẹẹ ṣile nibi kan, mo tun pe Ayinla pe ko waa kọrin. Wọn tun pe wa lẹẹkẹta nibomi-in, igba yẹn ni mo waa ro o pe o yẹ ka kuku jọ maa ṣere yii ni. Ko ma lọ sibomi-in mọ, ba a ṣe jọ bẹrẹ si i ṣe e latigba naa niyẹn.

Bi elegun ba fẹẹ ki eegun oun gbayi, wọn maa sọ fun mi pe ki n jẹ k’Ayinla waa tọkun ẹ, oun lo maa kọrin nibẹ, ti emi maa lulu.

Emi ni Ọlọrun fi ṣe sabaabi ina Ayinla to tan. Emi ni mo maa n fi ilu mi darin pe ‘Ẹ dibo f’Ayinla, Ayinla ọmọ Wuramọ.’ Awọn eeyan maa ba wa gbe orin yẹn, ba a ṣe maa kọ ọ lọ kọ ọ bọ niyẹn, titi to fi dohun.

Irun eeyan ti Ayinla Ọmọwura jẹ

Eeyan daadaa ni, ki i fiṣẹ ṣere. Ṣugbọn beeyan ba fẹẹ fi ohun ti ko tọ lọ ọ, ko ni i gba. Ki i gba iwọsi rara.

Iha ti Ayinla kọ si mi nigba aye ẹ

O gba mi lọgaa ẹ o, Ọlọrun dẹ ni ko fi kọrin fun gbogbo aye pe, ‘‘Adewọle Alao Onilu-ọla, Alao oniya-o-mebi, iwọ lọga ọmọ Wuramọtu. Bi mo ba ti r’Alao, ẹru kan o tun ba mi mọ, Adewọle akọmọlede, afilu da wọn lara loju agbo, ọwọ Adewọle adidun ni, ẹni ba ti ri wa lagbo, a fi naira yẹ Adewọle si….’’

Nigba ti Ọlọrun dẹ kadara pe a jọ maa ṣiṣẹ ni, o jẹ ki ohùn rẹ ba ilu temi naa mu. Emi ni mo kọkọ ṣe sababi fun un, bi mo ba lulu, oun aa kọrin si i, to ba kọrin ti ko daa to, ma a sọ fun un, ẹsẹkẹsẹ naa lo dẹ ti maa yi i pada ti gbogbo ẹ aa dẹ bọ si i.

Ohun to fa ija laarin wa

K’Ọlọrun ma fi aṣetaani ṣe wa lẹnu iṣẹ wa. Ṣe ẹ mọ pe gbogbo ohun to ba daa naa ni o maa n fẹẹ ri bakan. Ṣugbọn nigba ti mo waa ri i pe ẹni to pe mi lọgaa ti fẹẹ sọ mi di ọmọọṣẹ, ohun to fa ija niyẹn. Ṣugbọn nigba tawọn eeyan nla nla ti wọn n fi wa yangan niluu Ẹgba ti da si i, a jẹ ko tan nigba ti wọn pari ija naa fun wa.

O to ọdun meji ta a fi ja

Bẹẹ ni, o to ọdun meji ta a fi ja ti kaluku n ṣe tiẹ lọtọọtọ. Ki i ṣe pe mo dawọ duro lai ṣiṣẹ nigba yẹn, emi naa n tirai, mo n paarọ awọn olorin bii ẹni paarọ aṣọ ni. Igba ti mo ri olorin ti ohùn rẹ sun mọ ti Ayinla ni wọn pari ija fun wa, ba a ṣe tun pada niyẹn. Ayinla paapaa naa ko ri onilu gidi bii emi nigba ta a ja, afigba ti wọn pari ija fun wa ni gbogbo ẹ too pada bọ si i foun naa.

Ka ni mi o gba ki wọn pari ija yẹn fun wa nigba naa, wọn aa ti pa emi naa, nitori a o mọ pe bi iku ẹ ṣe maa waye kia niyẹn. Awọn eeyan aa ro pe mo fi ẹjẹ sinu tutọ funfun sita ni, wọn aa si fẹẹ gbẹsan lara mi. Mo si dupẹ f’Ọlọrun, nigba ta a pada lẹyin ija, ajọṣepọ wa tun daa si i ni. Ṣebi ẹyin naa gbọ rẹkọọdu ta a ṣe lẹyin igba yẹn, ‘Omi tuntun ti ru’ la pe e.

Bi Ayinla ṣe ku

Mi o si nibẹ lọjọ naa, ṣugbọn mo ri i lọjọ bii meloo kan si ọjọ to ku yẹn. Oun ati Bayewumi to jẹ maneja ẹ ni wọn ni gbolohun asọ. Ọkada ẹgbẹ, Suzuki ti Bayewumi n gun kiri lai wa si puratiisi ẹgbẹ wa mọ lo dija silẹ, owo ta a pa ninu ẹgbẹ la fi ra ọkada yẹn nigba ti Bayewumi ko ti i fi ẹgbẹ wa silẹ. Ayinla waa loun maa gba ọkada yẹn lọwọ ẹ, mo sọ fun un nigba naa pe ko ma ba Bayewumi ja, mo ni ṣe ko mọ iye mọto toun funra ẹ n gun ni, ti yoo waa maa ja nitori maṣinni lasan, ṣugbọn lọjọ ti wọn lo ri maneja ẹ yii nile ọlọti kan lo ni oun ṣaa maa gba ọkada yẹn lọwọ ẹ dandan, bo ṣe di pe o ṣaa ja siku fun un niyẹn.

Ootọ ni pe o paṣamọ iku ẹ ko too ku

A lọọ wo ere awọn onigbagbọ ti wọn ṣe lasiko iku Jesu, Ayinla naa ba wa lọ. Ba a ṣe jẹun tan nibẹ lo sọ pe oun ri i pe ẹni to sun mọ Jesu lo fi i han awọn to pa a. O ni Judaasi wa ninu awọn elegbe oun yii naa, ni kaluku wọn ba n sọ pe ‘bii emi bi?’ Ayinla aa ni rara, iwọ kọ. Ṣugbọn nigba to kan Bayewumi, Ayinla sọ pe oun ni Judaasi naa, niyẹn ba binu, a ṣaa ba wọn pari ẹ lọjọ yẹn. Oṣu kẹfa lẹyin ẹ ni iku ẹ tọwọ Bayewumi wa.

Lẹyin ti Ayinla Ọmọwura ku…

Ki i ṣe pe ẹgbẹ tuka lẹyin ti Ayinla ku, aburo ẹ ta a n pe ni Dauda wa ninu wa tẹlẹ naa, awọn famili atawọn ma-jẹ-o-bajẹ ni ki Dauda maa tẹsiwaju. Oun naa ṣe e fun bii ọdun meloo kan, ṣugbọn ko da bii. Ọmọ Ayinla, Akeem naa kọrin, o da tiẹ silẹ ko too ku.

Iku Ayinla maa n ko ọgbẹ ọkan ba mi

Titi dasiko ti a n sọrọ yii ni ọrọ Ayinla n ko ọgbẹ ọkan ba mi, orukọ ẹ ko ṣee ma da ni. Iku

Awọn ti wọn sọ pe mo sin ọwọ ni mo fi n lulu to dun…

Irọ niyẹn o, mi o sin ọwọ kankan o. Ṣe ẹ mọ pe ohun teeyan ba mọ ọn ṣe, bii idan lo maa n ri, ohun to ṣẹlẹ gan-an niyẹn, ajẹbi niṣẹ ilu lilu fun mi. Mi o dẹ lulu fi baayan ja tabi ba eeyan jẹ.

‘’Ẹ kuro ni titi, nọmba yin o jade’ ti mo lu, ki i ṣe pe mo fi n pẹgan ẹnikẹni. Awọn mọto ti ko ba ni nọmba l’Ekoo nigba yẹn ni mo n ba wi, mo fi kilọ fun wọn ni, nitori awọn ọlọpaa maa n mu mọto ti ko ba ni nọmba ni. Itumọ ẹ niyẹn, eebu kọ.

Iku Ayinla mu ifasẹyin ba mi gan-an

Ba a ṣe n darukọ ẹ yii gan-an n mu ọgbẹ ọkan ba mi, orukọ ẹ ko ṣee ma da ni. Ka ni Ayinla wa laye ni, bi mo ṣe n fẹsẹ rin kiri lai ni mọto yii ko ni i ri bẹẹ, o maa ti ra mọto fun mi. Airi mọto lo yii paapaa jẹ ki agba tete kan mi, nitori wahala ti mo n ṣe pọ. Ka ni Ayinla wa laye ni, wahala yẹn ko ni i to bayii fun mi. Mo lo mọto lasiko ta a ja yẹn, awọn kan ni wọn ra a fun mi, wọn tun ra irinṣẹ paapaa, igba to ya lo gori odo.  Mi o le ra omi-in mọ lẹyin to ku tan, igba ti nnkan fẹẹ maa daa pada lo ku lojiji.

Ẹ wo ile ti mo kọ, ko ju bayii naa lọ, mi o ti i kọ ọ tan. Agba ti de si mi bayii, ohun ti mo fẹ ni pe kawọn ọmọ Naijiria ran mi lọwọ, ki wọn sọ mi di ọlọla pẹlu awọn ẹbi mi. Mo fẹ ki wọn ba mi tun ile yii ṣe, ki wọn ba mi ṣe gilaasi sawọn windo onigi ta a ko sibẹ yii. Mo fẹ ki wọn ba mi ṣe ṣia onitimutimu.

Aṣiri alaafia mi titi dasiko yii

Mi o ni oogun kan ti mo n lo, itẹlọrun ni mo ni. Mi o ki i wo aago alaago ṣiṣẹ, bi mo ri gaari, ma a mu, bi aaye ounjẹ gidi ba si yọ, ma a jẹ ẹ, mi o si ba teeyan jẹ. Ohun to gbe mi ro niyẹn. Ọlọrun ti to ọjọ iku kaluku fun un, beeyan n lo oogun, tọjọ iku ba de, o maa ku, beeyan ko si lo nnkan kan, bi asiko ko ba ti i to, ko ti i to naa ni.

Imọran mi fawọn onilu to n bọ lẹyin

Ki wọn kọ iṣẹ wọn daadaa, ki wọn mọ ọn, nitori bi wọn ba fi nnkan leeyan lọwọ bii temi ti wọn fun lọpa ilu lati kekere yii, afi ko tun lọọ kọ ọ daadaa, ko mọ ọn ju bẹẹ lọ, ohun to le mu aṣeyọri wa niyẹn.

Wọn ni awa olorin maa n fẹran obinrin

Ki i ṣe bẹẹ naa la ṣe fẹran obinrin. Emi naa o fẹyawo pupọ nigba yẹn, mi o fẹ ju mẹta tabi mẹrin lọ.

Ọja lasan ni wọn fi ija ti wọn n ja nigba yẹn ta, Fatai Olowonyọ ati Ayinla ko ja ija gidi

Ṣe ẹ mọ pe ko le ma ri bẹẹ, ki i ṣe pe Ayinla Ọmọwura ati Fatai Olowonyọ n ja ija kan to le ju nigba yẹn, wọn kan fi n taja lasan ni. Ti wọn ba pade ara wọn nita, ti ki i ṣe lagbo ere, wọn jọ n jẹ, wọn jọ n mu ni. Ṣebi igba kan naa wa ti Ojindo ati Aka n sọrọ sira wọn bii ija, ko le ṣe kiru ẹ maa waye.

Ayinla ati Barista …

Orin ti Ayinla kọ pe ‘ Ki o ma ṣe jẹ n gbọ o, Ayinde, pe wọn ji ẹ lorin lo, ko jẹ jẹ bẹẹ, ọrọ apara ni’ Ko fi bu Barisita. Iwọnba pe o wa Barisita lọ sile ti wọn ni ko waa fiili fọọmu ko too le ri i lo dun un, lo fi ni koun waa fiili fọọmu kẹ, nigba to jẹ Barista naa ni kaputeeni awọn ẹgbẹ to fẹran orin oun, bo ṣe yipada niyẹn, to kuro nile Barisita.

Orin to waa kọ pe Ayinde ki o ma ṣe jẹ n gbọ yẹn, Ayinla kan kọ ọ ni tiẹ ni, Barisitia kọ lo n ba wi. Ayinde to dẹ darukọ yẹn, ẹnikan ninu wa lo n jẹ Ayinde, iyẹn lo n sọ, orukọ kan papọ ni.

Leave a Reply