Eyi ni awọn amuyẹ ti ẹni to ba fẹẹ jẹ Alaafin gbọdọ ni – Baba Iyaji

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ko din ni eeyan mọkandinlọgọfa (119) to ti n jijadu bayii lati di Alaafin tuntun.

Baba Iyaji, Oloye Mukaila Afọnja, iyẹn olori awọn ọmọ ọba  ilu Ọyọ, lo sọ eyi di mimọ faye gbọ.

Tẹ o ba gbagbe, lati ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2022 yii, ti Ọba Lamidi Ọlayiwọla (Adeyẹmi Kẹta) ti waja, lori itẹ Alaafin ti ṣofo.

Latigba naa ni ijijadu ti bẹrẹ lori ẹni ti yoo gori itẹ ọhun, o si fẹẹ jẹ pe lojoojumọ lawọn ọmọ oye n pọ si i.

Pẹlu bo ṣe jẹ pe ko ti i to ọgọrin (80) ọjọ

ti Ọba Adeyẹmi waja si asiko yii, ti awọn ọmọ oye si ti to mọkandinlọgọfa (119), o han gbangba pe lojoojumọ lọmọ oye n pọ si i latigba ti alafo nla ti ṣi silẹ laafin Ọyọ.

Ṣugbọn bi awọn ọmọ oye ṣe n pọ si i lojoojumọ yii, Baba Iyaji ti i ṣe olori awọn ọmọọba ti sọ pe ẹni to ba pataki aṣa, paapaa, eyi to ba le sọ ede Yoruba pọnbele ti ko ni amulumọla ninu ninu awọn ọmọ oye naa ni wọn yoo fi jọba.

O fi kun un pe akitiyan ti n lọ lọwọ laarin awọn Ọyọmesi, igbimọ awọn afọbajẹ ilu Ọyọ lati mu ẹni kan ṣoṣo ti ipo naa tọ si ju lọ ninu awọn mọkọọkandinlọgọfa naa.

Leave a Reply