Eyi ni awọn ohun ti mo ba Aarẹ Buhari sọ lasiko abẹwo mi si i l’Abuja-Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ ati Ondo, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ati Akeredolu, ṣabẹwo si Aarẹ Buhari ni Aso Rock, niluu Abuja, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣe yii.

Eyi ko sẹyin eto aabo to mẹhẹ, to si ti fẹẹ di wahala nla laarin awọn Fulani darandaran atawọn eeyan ipinlẹ mejeeji. Eyi la gbọ pe o gbe awọn gomina mejeeji lọ siluu Abuja lati ri Buhari.

Ninu ọrọ ti gomina Ọyọ naa sọ lẹyin ipade yii lo ti ṣalaye pe oun pinnu lati waa ri Aarẹ Buhari, koun le fẹnu ara oun ṣalaye bi eto aabo ṣe ri gan-an yatọ si ahesọ to jinna soootọ tawọn eeyan n gbe kiri nipa rẹ.

‘‘Emi ati Aarẹ fikun lukun, a si sọrọ lori awọn eto ti awa naa ti ṣe ati awọn igbesẹ ti a ti gbe lati ri i pe eto aabo to fẹsẹ rinlẹ daadaa.’’

Bakan naa ni Makinde ni oun beere fun awọn ọlọpaa si i lati maa daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ati lati mojuto awọn ẹnu ibode kaakiri ipinlẹ, nitori bi ipinlẹ Ọyọ ṣe tobi ju awọn ipinlẹ mi-in lọ.

Bakan naa ni Ọọni Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi ni oun sabẹwo si Aarẹ lati rọ ọ pe ki ọrọ eto aabo ilẹ Yoruba ma di eyi ti wọn n sọ di ọrọ oṣelu.

Ṣugbọn Gomina Akeredolu kọ lati ba awọn oniroyin sọrọ.

Leave a Reply

%d bloggers like this: