Eyi lawọn ọmọ igbimọ ti yoo ṣeto gbigba iṣakoso ipinlẹ Ọṣun fun Adeleke

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti gbe igbimọ ẹlẹni mẹtadinlogoji ti yoo ṣagbatẹru eto bi yoo ṣe gba iṣakoso ipinlẹ Ọṣun latọwọ Gomina Oyetọla kalẹ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, nijọba yoo bọ lọwọ ẹgbẹ oṣelu APC to ti n ṣejọba bọ lati ọdun mejila sẹyin nipinlẹ Ọṣun, si ọwọ ẹgbẹ PDP.

Lati mu ki eto gbigba iṣakoso naa rọrun, gẹgẹ bi akọwe ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọladele Bamiji, ṣe ṣalaye ni Adeleke ṣe yan awọn to dangajia, akọṣẹmọṣe, ti wọn si ti lamilaaka lẹnu iṣẹ wọn lẹkajẹka, lati gbe igbesẹ naa.

Ọladele ni Dokita Muyiwa Ọladimeji ni yoo jẹ alaga igbimọ naa, nigba ti alakooso eto ipolongo ibo wọn, Ọnarebu Sunday Bisi, yoo jẹ igbakeji rẹ. Ọnarebu Bamidele Salam to jẹ aṣoju-ṣofin l’Abuja lọwọlọwọ ni yoo jẹ akọwe igbimọ ọhun, Sir Adekunle Adepọju yoo si jẹ igbakeji rẹ.

O fi kun un pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni gomina tuntun yoo bura fun awọn ọmọ igbimọ naa.

A oo ranti pe ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje ti a wa yii nidibo gomina waye nipinlẹ Ọṣun, ajọ eleto idibo, INEC, si kede pe Adeleke ni ibo 403,371 nigba ti Oyetọla ni ibo 375,027, eyi to mu ki wọn kede rẹ gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori.

Ijọba ibilẹ mẹtadinlogun ni Adeleke ti jawe olubori, nigba ti Oyetọla ri ijọba ibilẹ mẹtala ninu idibo ti awọn ẹgbẹ oṣelu mẹẹẹdogun ti kopa ọhun.

Leave a Reply