Eyi ni awọn ti Buhari ṣẹṣẹ yan gẹgẹ bii olori awon ọmọ ogun gbogbo nilẹ wa

Lẹyin gbogbo ariwo ti awọn ọmọ Naijiria ti n pa latọjọ yii wa, lana an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni Aarẹ Muhammadu Buhari, ṣe ohun ti awọn ọmọ orilẹ-ede yii n fẹ pe ko paarọ awọn to fi ṣe olori eto aabo, n lo ba yọ gbogbo awọn to wa nibẹ danu, to si fi awọn eeyan mi-in rọpo wọn.

Njẹ aẁọn ọga ologun wo ni wọn gbaṣẹ adari bayii lori eto aabo ikọ ẹṣọ kọọkan ni Naijria, ati pe ki lawọn iriri wọn, ẹ maa ba wa ka lọ.

Olori eleto aabo pata ni Ọgagun agba, iyẹn Major- General Leo Irabor. Ọdun 1965 ni wọn bi i ninu oṣu kẹwaa ọdun. Ọmọ ilu kan ti wọn n pe ni Ika, lapa Guusu ipinlẹ Delta lọkunrin ọhun n ṣe. Ọkan lara awọn ikọ Regular Course 34 ti ẹkun ileeṣẹ ologun, Nigerian Defence Academy ni.

Oun yii naa lọga agba to ṣẹṣẹ fi iṣẹ silẹ gẹgẹ bi oludari eto ikọni ni olu ileeṣẹ eto aabo ilẹ wa.

Ileewe giga Yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ lo ti kawe gboye imọ iṣẹ ẹrọ, bẹẹ lo tun ni iwe ẹri master’s meji lati Yunifaisiti Ghana, niluu Accra, ati Bangladesh University of Professionals, ni Dhaka.

O ti figba kan jẹ apaṣẹ agba fun awọn ikọ LAFIYA DOLE, ni apa Ariwa-Iwọ-oorun ilẹ Hausa lọhun-un, bẹẹ lo tun ti figba kan dari awọn ẹṣọ oloogun ti wọn wa ni agbegbe Lake Chad Basin.

Ọgagun-agba Ibrahim Attahiru ni ọga agba fawọn ṣọja bayii. Nomba idanimọ rẹ ninu iṣẹ ṣọja ni 8406, ọjọ kẹwaa, oṣu kẹjọ ọdun 1966 ni wọn bi i. Ọmọ Kaduna nijọba ibilẹ Ariwa ipinlẹ naa lo n ṣe, ọkan pataki si lo jẹ ninu ikọ Regular Course 35, ti ileeṣẹ oloogun, iyẹn Nigerian Defence Academy.

Ki wọn too gbe iṣẹ tuntun yii fun un gẹgẹ bi olori awọn Ṣọja ni Naijiria bayii, ọkunrin yii ti kọkọ di ipo ọga apaṣẹ 82 Division ti ileeṣẹ ologun Naijria, ni Enugu mu.

Bakan naa lo ti figba kan dari ikọ Lafiya Dole. Oun yii naa lo gbaṣẹ lọwọ Ọgagun Leo Irabor lọdun 2017.

Nigba ti ko ri awọn Boko Haram da lọwọ kọ ni wọn gbaṣẹ lọwọ ẹ. Nigba yẹn ni Ọgagun Tukur Buratai, paṣẹ fun un pe ọwọ ẹ gbọdọ tẹ ọkunrin janduku afẹmiṣofo olori Boko Haram nni, Abubakar Shekau, yala oku ẹ tabi aye ẹ.

Nitori ti ko ri olori Boko Haram yẹn mu gan-an ni wọn ṣe gbaṣẹ lọwọ ẹ nigba yẹn.

Ọkunrin ọmọ Yoruba kan naa wa ninu awọn ologun ti Buhari ṣẹṣẹ gbe iṣẹ nla ọhun fun, Air Vice Marshal Isiaka Ọladayọ Amao, lorukọ ẹ.

Ọga agba ni, nileeṣẹ ologun oju-ofurufu, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹsan-an ọdun 1965 ni wọn bi i sipinlẹ Enugu, ṣugbọn ọmọ Oṣogbo nipinlẹ Ọṣun ni.

Ọdun 1984, ninu oṣu kin-in-ni lo darapọ mọ ileeṣẹ ologun oju ofurufu, nigba to si di ogunjọ oṣu kejila ọdun 1986 lo gbaṣẹ gẹgẹ bii jagunjagun to le wa ọkọ ofurufu.

Ipinlẹ Kaduna lo ti bẹrẹ eto ẹkọ bi eeyan ṣe le wa ọkọ baluu loju ofurufu  laarin ọdun 1987 si ọdun 1989. Bakan naa lo tun tẹ siwaju ninu eto ẹkọ ọhun ni Kano laarin ̀ọdun 1990 si 1992, bẹẹ gẹgẹ lo tun k̀ọ ọ si ni Kainji laarin ọdun 1993 si ọdun 1999, eyi to sọ ọ di onimọ nla bo ṣe n tẹ siwaju.

Ninu ilakaka ẹ naa lo tun ti kawe nipa iṣẹ to yan laayo yii si i ni Kaduna laarin ̀ọdun 2004 si 2005. Oriṣiriiṣi ẹkọ nipa iṣẹ oloogun lo ti kọ, paapaa nileewe awọn ologun ni Jaji; bẹẹ lo tun kẹkọọ ni India;  China, Zaria, ati ni Karachi, lorilẹ ede Pakistan.

Olori awọn ẹṣọ ologun tuntun ori omi ni Rear Admiral Awwal Zubaru, ọjọ kejilelogun ọsu kẹrin ọdun 1966 ni wọn bi i, ọmọ ipinlẹ Nasarawa ni, nipinlẹ Kano.

̀Ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan-an ọdun 1984, lo darapọ mọ iṣẹ ologun, ẹka ti ori omi, to si gba oye Lieutenant lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹsan an ọdun 1988.

Ọpọ ẹkọ ati iriri nla loriṣiriiṣi lo ti ni nidii iṣẹ ologun, bẹe lo ti kẹkọọ kaakiri awọn orilẹ-ede bii South Africa atawọn ibomi-in lagbaye.

 

Leave a Reply