Eyi ni ba a ṣe ṣawari ọgọọrọ awọn Hausa/Fulani to fẹẹ ya wọ ipinlẹ Ondo pẹlu ọpọlọpọ oogun abẹnugọngọ-Ẹṣọ Amọtẹkun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọgọọrọ awọn eeyan kan lati agbegbe Oke-Ọya, lawọn ẹṣọ Amọtẹkun ṣawari l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, lasiko ti wọn gbiyanju lati gba ọna ẹburu wọ ipinlẹ Ondo.

Awọn eeyan ọhun to to bii mọkanlelaaadọjọ (151) ni wọn ṣawari ninu ọkọ ajagbe mẹta ọtọọtọ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Sango, eyi to wa loju ọna marosẹ Akurẹ si Ikẹrẹ-Ekiti, ni nnkan bii aago mẹfa aabọ aarọ ọjọ naa.

Ohun to mu kọrọ awọn ti wọn mu ọhun mu ifura lọwọ ni ọna ti wọn gba fi ko wọn sinu awọn ọkọ ajagbe naa pẹlu bo ṣe jẹ pe aarin apo ẹwa ati irẹsi ni wọn ha wọn mọ ki awọn ẹṣọ alaabo ma baa ri wọn.

Eto duro-ka-yẹ-ọ-wo tawọn ẹsọ Amọtẹkun n ṣe fun awọn ọkọ lọwọ kaakiri ipinlẹ Ondo latari ọrọ eto aabo to mẹhẹ lo ṣokunfa bi wọn ṣe da awọn ọkọ ajagbe ọhun duro, kayeefi lo si jẹ fun awọn ẹṣọ alaabo ọhun nigba ti wọn ri i bi wọn ṣe sin awọn eeyan bii ẹja mọ inu awọn ẹru ti wọn ko.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, adari ẹṣọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni ko sẹni to le mọ pe iye awọn eeyan to to bẹẹ wa ninu awọn ọkọ akẹru naa lai da wọn duro.

O ni alaye tawọn eeyan naa ṣe fawọn ni pe ipinlẹ, Katsina, Kano ati Jigawa, lawọn ti n bọ, ati pe ilu Akurẹ ni ọpọlọpọ awọn ti fẹẹ duro, nigba tawọn yooku si n lọ si Oṣogbo, nipinlẹ Ọsun.

Adelẹyẹ ni awọn ṣi n tẹsiwaju ninu ifọrọwanilẹnuwo ti awọn n ṣe fawọn eeyan ọhun lọwọ nitori ko si eyi to ri esi gidi fun awọn nigba tawọn n beere ọrọ lọwọ wọn.

Ọpọ awọn ajoji ọhun lo ni wọn mọ ibi ti wọn ti n bọ loootọ, ṣugbọn ti wọn ko le sọ ni pato ibi ti awọn n lọ, o ni ohun kan ṣoṣo ti ọpọ wọn n tenumọ ni pe ṣe lawọn kan wọ ọkọ ṣaa, tawọn si n bọ nipinlẹ Ondo.

O ni awọn ọkada mẹwaa pẹlu ọpọlọpọ oogun abẹnu gọngọ ti wọn tun fẹẹ ko wọle lọna aitọ lawọn ṣawari laarin ẹru, nibi ti wọn ko wọn pamọ si.

 

Olubadamọran fun gomina lori eto aabo ọhun ni ọna ẹburu tawọn kan n gba ya wọle lati agbegbe Oke-Ọya lewu pupọ lasiko yii tawọn eeyan ẹkun Guusu Iwọ-Oorun nla iṣoro ipenija eto aabo kọja

O ni igbesẹ tawọn fẹẹ gbe lẹyin ti iwadii ti awọn n ṣe lọwọ ba ti fidi rẹ mulẹ pe awọn arinrin-ajo ọhun ko lẹbọ lẹru ni lati da eyikeyii ti ko ba ti ni ibikan to n lọ pato pada si ipinlẹ olukuluku wọn.

Adari ẹsọ Amọtẹkun ọhun ni loootọ lofin Naijiria faaye gba ẹnikẹni lati lọ sibi to ba wu u kaakiri awọn ipinlẹ to wa lorilẹ-ede yii, ṣugbọn ẹni ti yoo ba rin iru irinajo bẹẹ lasiko yii gbọdọ nibi to n lọ ati nnkan pato to fẹẹ lọọ ṣe nibẹ.

Leave a Reply