Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (15)

Mo fẹ ki ẹ tun mu ọrọ ti mo fẹẹ sọ yii si ọwọ osi: To ba jẹ bi eto sẹnsọ orilẹ-ede yii ṣe wa naa lo wa, to ba jẹ pe a ko ri eto ikaniyan daadaa kan ṣe, to jẹ ibi ti awọn Hausa-Fulani ti gbe iye awọn ti wọn wa ni Naijiria si lati ọdun 1950 wa naa la ṣi wa, ko si bi orilẹ-ede wa yoo ṣe nilọsiwaju. Nibi eto ikaniyan, nibi ti wọn ti ni awọn Hausa-Fulani pọ ju awa to ku lọ ni Naijiria, nibi ti nnkan ti daru fun wa wa niyi. Bi a ko ba ṣe atunṣe sibẹ yẹn, ko si ibi ti a oo gba ti a oo fi ri atunṣe mi-in si ọrọ ara wa. Ohun kan to fun Hausa lagbara lori gbogbo awa to ku ni Naijiria niyi, awọn naa mọ bẹẹ, nitori ẹ ni wọn ko ṣe ni i ṣeto ikaniyan to yanju nilẹ yii, gbogbo eto sẹnsọ yoowu ti wọn ba ṣe, ojooro ati eru ni wọn yoo fi ṣe e. Laipẹ yii, wọn fi ọkunrin Ibo kan ṣe olori ileeṣẹ eleto ikaniyan yii, ṣugbọn kia ni wọn yọ o danu, ti wọn fi Hausa mi-in si i.

Ki lo de ti wọn ṣe bẹẹ! Awọn eeyan yii mọ pe ipilẹ agbara awọn niyẹn, wọn mọ pe bi iyẹn ba ti bọ lọwọ awọn, ko si ohun ti awọn yoo ri ṣe ni Naijiria mọ. Nitori ẹ ni wọn ko ṣe ni i fi Ibo tabi Yoruba si ipo alaga eto ikaniyan yii, wọn ko fẹ ohun ti yoo da ẹru abosi ti awọn ti di lati ọjọ yii nu. Awọn ti wọn n ro pe Hausa Fulani ko gbọn, ibi ti wọn yoo ti kiyesi ara niyi. Awọn ti wọn si n ro pe awọn eeyan naa ko mọ ohun ti wọn n ṣe, ati awọn ọmọ ale ti wọn wa laarin awọn ẹya to ku ti wọn n ta awọn eeyan wọn, ti wọn n sọ pe awọn eeyan yii fẹ rere fawọn, ibi ti wọn yoo ti mọ naa ree. Ipo meji pataki lo wa nilẹ yii ti wọn ko ni i fi Yoruba tabi Ibo ṣe olori wọn, iyẹn naa ni ipo olori awọn ṣọja, ati ipo olori awọn ti yoo ṣeto ikaniyan fun wa. Fulani tabi Hausa ni wọn yoo fi sibẹ, bi wọn ba si fi ẹlomi-in s i i, ki ẹ ti mọ pe ọkan ninu awọn ẹru wọn ni, ohun ti wọn ba fẹ ni ẹni naa yoo ṣe.

Nigba ti wọn ti fi agidi da eto ikaniyan 1962 ru, ti wọn ṣeto ikaniyan mi-in, ti Balewa ati Sardauna fi miliọnu mejọ eeyan kun awọn ara ilẹ Hausa, lati igba naa ni ko ti si ikaniyan ti wọn yoo ṣe ni ilẹ yii ti awọn eeyan naa ko ni i ju awa ẹya to ku lọ. Mo ti sọ ọ fun yin tẹlẹ, eto ikaniyan kọ ni wọn ṣe ti wọn fi ni iye ti wọn ni yii, magomago ati irẹjẹ ti ko si iru rẹ nibi kan ni gbogbo awọn orilẹ-ede Afrika to ku ni. Niwọn igba ti wọn si ti ṣe bẹẹ ti wọn ti mu un jẹ, ti wọn ti fi agidi ni awọn lawọn pọ ju wa lọ, ti wọn si ni awọn aṣofin ti wọn jẹ idaji gbogbo Naijiria, ti wọn n gba idaji ohun gbogbo ti a ba pin nilẹ yii, ko tun si nnkan mi-in ti wọn n ṣe ju bi iru agbara bẹẹ ko ṣe ni i bọ lọwọ awọn lọ. Ọna ti agbara naa ko si fi ni i bọ ni ki wọn ri i pe ko si Ibo tabi Yoruba to gberi ju wọn lọ, ki wọn si ni agbara lori awọn ọmọ ogun gbogbo.

Loju awon baba wa yii naa ni wọn ṣe gba olori ileeṣẹ ologun lọwọ wọn, lẹyin ti wọn ti gba agbara ile-igbimọ aṣofin ati tijọba lọwọ wọn. Agbara ṣọja ti awọn Hausa-Fulani wọn yii tete ri gba lẹyin ti Naijiria gba ominira lo tubọ ba nnkan jẹ, oun lo si sọ awọn eeyan to ku di ọmọlẹyin fun wọn. Awọn eeyan kan maa n ṣe aṣiṣe kan, wọn yoo ni awọn Hausa-Fulani lo ni ṣọja, awọn ni ologun akọkọ. Mo ti sọ fun yin pe eleyii ki i ṣe bẹẹ, o pẹ gan-an ki awọn ọmọ ogun Fulani too dara pọ mọ awọn ọmọ ogun Naijiria. Ohun to fa a ni pe awọn Fulani lati Ṣokoto ko fẹẹ ri awọn oyinbo ti wọn waa ṣejọba ni Naijiria nigba naa. Wọn koriira wọn, nitori wọn ni kereferi ni wọn, nigba to ti jẹ Kristẹni ni wọn. Ikoriira ti wọn ni fun wọn yii ni awọn eeyan agbegbe wọn ko fi si ninu awọn ṣọja akọkọ ni Naijiria, awọn Fulani kọ ni wọn bẹrẹ iṣẹ ṣọja rara.

Titi ti wọn fi kapa awọn Fulani yii ni 1903, gbogbo ero ọkan wọn ni pe awọn lawọn yoo kapa awọn oyinbo ati awọn keferi ti wọn n lo gẹgẹ bii ṣọja wọn. Nigba ti Lord Lugard fẹẹ bẹrẹ si i ṣa awọn ọmọ ogun jọ fun iṣẹ ṣọja rẹ ni 1897, ko duro ni ilẹ Hausa, Lọkọja, nitosi nibi, ni ilẹ Yoruba to wa ni Kogi bayii lo wa, nibẹ lo si ti n ṣa awọn ọmọ ogun rẹ jọ. Awọn ọmọ ogun to kọkọ ri mu ni awọn Agatu ati awọn Garra, awọn lo kọkọ n lo, ati awọn ọmọ ogun Ibadan ti wọn jẹ jagunjagun gidi nigba naa. Awọn yii ni ṣọja akọkọ ti Naijiria ni, lẹyin naa ni wọn ko awọn Tapa ni Nupe ati igiripa ni Borgu mọ wọn, ko si Fulani tabi Hausa ninu awọn yii, bẹẹ awọn ni Lugard fi bẹrẹ sọja nilẹ, nitori awọn Fulani lawọn ko le ba keferi ṣe, eewọ ni wọn ka a si, ogun Jihaadi lawọn le ja, Fulani lo si gbọdọ je olori awọn.

 Nigba tawọn ọmọ ogun yii n lọọ gba Ṣokoto, kidaa awọn ọmọ ogun Ibadan ni Lugard ko dani, ọmọ Yoruba ni wọn, ko si ẹya mi-in ninu wọn. Gbogbo eleyii wa ninu akọsilẹ itan igbesi-aye Lord Lugard funra ẹ, ko si aṣiwi tabi aṣisọ ninu rẹ rara. Ko too di igba yii, awọn jagunjagun kan wa nilẹ Ibo ati Naija Delta lọdọ awọn Ijaw, awọn ni ileeṣẹ ti wọn n pe ni Royal Niger Company n lọ, ileeṣẹ yii lo ni Naijiria tẹlẹ, awọn ni wọn si ta wa fawọn oyibo alawọ-funfun lati Britain. Ọrọ ọjọ mi-in leyii. Ṣugbọn awọn ileeṣẹ RNC ni wọn n lo awọn ọmọ ogun Ibo diẹ, ọmọ Naija Delta diẹ. Awọn yii ni wọn n lo bii ọlọpaa, ti wọn si n lo wọn bii jagunjagun ni gbogbo agbegbe naa fun ileeṣẹ yii, nitori ẹ ni ko si ṣe gbọdọ yaayan lẹnu pe nigba ti wọn bẹrẹ ṣọja, awọn yii naa dara pọ mọ wọn.

Gbogbo awọn yii, Kristẹni ni wọn, tabi ka sọ pe Kristẹni lawọn Fulani ro wọn si, nitori wọn wa lati Isalẹ-odo-Ọya, wọn ko si ba wọn ṣe. Eyi ni pe ko si awọn Hausa Fulani wọnyi ninu awọn ọmọ ogun Naijiria, afi lẹyin ti awọn ṣọja Lugard wọnyi ṣẹgun wọn ni Ṣokoto, ti wọn ṣẹgun wọn ni Kano, ati awọn ilẹ Hausa to ku gbogbo. Ohun ti wọn n sọ ni pe ogun Anọbi ni awọn n ja, ilakaka lati sọ gbogbo aye di Musulumi lawọn n ṣe, ọta kan ṣoṣo ti awọn si ni ni awọn oyinbo ti wọn n gbe ẹsin Krisitẹni kiri, nitori loju wọn nigba naa, keferi lawọn ẹlẹsin Kristẹni yii, awọn ti awọn n sin ẹsin tiwọn yii ni awọn jẹ onigbagbọ ododo. Nibẹrẹ pẹpẹ, epe ni wọn maa n ṣẹ fun Lugard ati awọn ọmọ ogun rẹ, ti wọn yoo ni o fẹẹ waa le wọn jade ni ibujokoo awọn, o si fẹẹ fi ẹsin tirẹ bori ẹsin awọn. Ko si Fulani to fẹẹ ṣe ṣọja, awọn Hausa naa ko si fẹẹ ṣe.

Mo fẹ ki ẹ maa fi ọkan ba awọn ọrọ yii lọ o. Ibẹrẹ itan awọn ṣọja wa ni mo n mẹnuba fun yin yii, ki n le fi han yin pe nigba ti a kọkọ bẹrẹ iṣẹ ologun igbalode nibi, ko si awọn Hausa-Fulani yii nibẹ, keferi ni wọn ka awọn ti wọn n ṣe ṣọja oyinbo si lọdọ wọn. Tori bẹẹ, ko gbọdọ ya ẹnikẹni lẹnu pe nigba tawọn ṣọja yii bẹrẹ iṣẹ taara, awọn Ibo atawọn Yoruba ni wọn n jọga nibẹ, awọn ni olori ologun. Ṣugbọn lẹyin ti ijọba bọ sọwọ awọn Balewa, wọn ti ọwọ bọ kinni naa loju, wọn da gbogbo eto to wa nilẹ pata lati wọ iṣẹ ṣọja ru, wọn gbe nnkan mi-in jade, wọn bẹrẹ si i sọ awọn ọmọ wọn di olori awọn ṣọja. Bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa dija, o tun di ariwo, sibẹ, wọn ṣe e ni aṣegbe o. N oo salaye ọna ti wọn gbe e gba fun yii lọsẹ to kọja, ṣugbọn nigba ti wọn ti ri iyẹn naa ṣe ni aṣegbe, lọjọ naa ni gbogbo agbara pata ti kuro lọdọ wa.

Ẹ jẹ ka maa ba a bọ.

Leave a Reply