Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (10)

Ki i ṣe pe Ọba Zaria Jafaaru Dan Isiyaku lọgbọn kan lori to ju ti awọn eeyan wa ti wọn wa nibi ipade ọdun 1950 ti wọn ti pin Naijiria si meji yii lọ o. Bẹẹ ni ki i ṣe pe Usman Nagogo ti i ṣe ọba Katsina igba naa ni laakaye kan ti a ko ri iru ẹ ri. Ṣugbọn kinni kan mu awọn ọba mejeeji yatọ, iranṣẹ oyinbo ni wọn. Ko too di pe wọn di ọba, ojulowo iṣẹ ti wọn ṣe laye wọn, iranṣẹ laarin awọn eeyan wọn ati oyinbo ni, iyẹn laarin awọn araalu wọn ati awọn oyinbo ti wọn n ṣe akoso adugbo wọn nigba naa. Nidii eyi, ko si igbesẹ kan ti wọn gbe ti ki i ṣe awọn oyinbo yii lo kọ wọn. Lati ilẹ ni awọn oyinbo yii ti sọ pe ti wọn ko ba ti fẹ ki wọn rẹ wọn jẹ ni Naijiria, ki wọn ri i pe awọn gba idaji orilẹ-ede naa lọwọ awọn to ku. Wọn ti sọ fun wọn pe ti wọn ba depade, ti awọn to ku ba ni awọn ko gba, ki wọn ni awọn ko ṣe Naijiria mọ ni.

Ṣugbọn eleyii naa ko ba ti ṣee ṣe fun wọn bi ko ba jẹ iṣọkan nla to wa laarin awọn ati awọn ti wọn jẹ oloṣelu laarin wọn. Ṣebi Tafawa Balewa wa nibẹ, Ahmadu Bello wa nibẹ, ṣugbọn wọn ko gbori lọwọ awọn ọba ti wọn ko tiẹ gboyinbo yii, ohun ti awọn ọba yii ba ti sọ lawọn naa n sọ. Bẹẹ ni ti awọn naa, ninu gbogbo wọn, ko sẹni kan bayii to kawe de yunifasiti ninu wọn. Bẹẹ ni. Ninu gbogbo awọn ti wọn waa ṣoju ilẹ Hausa nibi ipade Ibadan ti wọn ṣe ninu oṣu kin-in-ni 1950, ko si ẹyọ ẹni kan bayii to kawe de yunifasiti, awọn to kawe jinna ki wọn too di oloṣelu ninu wọn, iṣẹ tiṣa ni wọn n ṣe, ko si ẹni to jade yunifasiti ninu wọn. Ṣugbon ati awọn ti wọn mọwe o, ati awọn ti wọn ko mọwe o, ati awọn ọba wọn ni o, ati awọn oloṣelu wọn ni o, gbogbo wọn ti fẹnu ko pe ohun kan naa lawọn yoo ṣe, ọrọ kan naa lawọn yoo sọ, ko si sẹni to gbọdọ yi i pada ninu awọn.

Nitori bẹẹ lo ṣe jẹ nigba ti ọrọ naa fẹẹ maa le, Ọba Zaria yii ju bọmbu ọrọ lulẹ. Ede Hausa lo fi sọrọ, o ni ede ti oun yoo sọ ti yoo ye awọn ti wọn wa nibẹ niyẹn, ki wọn ba oun tumọ rẹ fawọn ti ko ba gbọ. O ni bi gbogbo awọn ti wọn wa nipade yii ko ba ti gba pe ki ilẹ Hausa ko idaji Naijiria lọjọ naa, awọn yoo yapa kuro ni Naijiria, awọn ko ni i ba ẹnikẹni jẹ Naijiria mọ, wọn yoo maa ṣe tawọn lọtọ, ki awọn to ku naa maa ṣe tiwọn lọtọ, awọn yoo pada si bi awọn ti ṣe wa ko too di ọdun 1914 ti Lord Lugard so awọn pọ mọ Yoruba ati Ibo, ti awọn si di Naijiria. Bo ti sọrọ tan ni Usman Nagogo, ọba ti Katsina dide, toun naa ni gbogbo ohun ti Jafaaru sọ yii, ọrọ oun nikan kọ o, ọrọ gbogbo awọn ọba ti awọn wa nibẹ ni, ọrọ naa si ni gbogbo awọn ti awọn wa lati ilẹ Hausa pata sọ, pe ti ko ba ri bẹẹ, ki wọn beere ẹni ti ko ba fara mọ ọn ninu awọn.

Ko si ẹni kan to nawọ o, ko si si ẹni kan to ta ko awọn ọba yii, gbogbo awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa dakẹ rọrọ bii omi to ṣe bii ẹni pe oun ko le gbe ni lọ ni. Ahmadu Bello lo kuku tiẹ waa fọ gbogbo ẹ pata. Oun ni bi wọn ba fi ọrọ naa si ibo didi, iyẹn ni pe ti wọn ba ni awọn yoo dibo lori ọrọ yii, pe boya ki awọn Hausa ko idaji Naijiria tabi ki awọn ma ko o, awọn ko ni i dibo kankan, gbogbo awọn ti awọn wa lati ilẹ Hausa ko ni i kopa ninu ibo naa, awọn Ibo ati Yoruba ni yoo dibo ara wọn funra wọn. Nibi tọrọ pin si niyi, nitori bi ọrọ ba le bayii, ibo ni wọn yoo di lati fi yanju ẹ, ṣugbọn Ahmadu Bello ti ni awọn o ni i dibo, ko si ṣẹni to wa lati ilẹ Hausa to ni tiẹ lo sọ yẹn, gbogbo wọn tun gba bẹẹ ni. Bello gbọn, o mọ pe ẹni mejidinlogun lawọn nibi ijokoo yii, bẹẹ apapọ Yoruba ati Ibo jẹ mẹrindinlọgbọn, pe ti awọn eeyan naa ba dibo wọn soju kan naa, wọn yoo bori awọn. Ohun to ṣe sọrọ bẹẹ niyẹn.

Nigba  ti ọrọ de ibi yii, Egbuna, aṣoju kan lati ilẹ Ibo, ni ki wọn ma da Ahmadu Bello lohun, ki wọn jẹ ki awọn dibo si ọrọ naa o jare. Nigba ti wọn dibo naa tan loootọ, awọn mẹrindinlọgbọn ti wọn jẹ lati ilẹ Yoruba ati Ibo ni wọn dibo pe ofin ti wọn ti gbe wa yẹn naa ni ki awọn lo, ki ilẹ Hausa ni aṣoju ọgbọn, ki awọn to ku naa ni mejilelogun mejilelogun. Ṣugbọn awọn nikan ni wọn dibo, ko si ẹyọ aṣoju kan lati ilẹ Hausa laarin wọn. Oloye Thomas tun dabaa pe bi ọrọ ti ri yii, ki wọn jẹ ki awọn fi kun iye awọn aṣofin ti yoo wa nile-igbimọ aṣofin yii. O ni ki wọn jẹ ki awọn aṣoju ti yoo wa lati ilẹ Hausa jẹ marundinlaaadọta (45) yatọ si ọgbọn ti wọn jẹ tẹlẹ, ki awọn ti wọn yoo wa lati ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo si jẹ mẹtalelọgbọn, yatọ si mejilelogun ti wọn jẹ tẹlẹ. Ni wọn ba tun dibo si ọrọ naa, ṣugbọn awọn mẹrindinlọgbọn ti wọn dibo ti akọkọ naa ni wọn tun dibo ẹẹkeji, awọn Hausa wọnyi ko ba wọn da si i. Nijokoo ba tuka.

Nigba ti ijokoo tun bẹrẹ, alaga ipade naa, Gerald Howe, ni ki awọn aṣoju Naijiria yii jọ gbe ọrọ naa wo laarin ara wọn, ki wọn si faaye diẹdiẹ silẹ funra wọn, ki awọn le kuro lori ọrọ naa. Ọọni Ile-Ifẹ lo kọkọ sọrọ le e, o ni o yẹ ki awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa yii mọ pe Yoruba ti ṣe fun wọn to, awọn si ti fi aaye loriṣiiriṣii silẹ fun wọn, ṣugbọn nibi ti ọrọ de yii, awọn aṣoju lati ilẹ Hausa yii naa gbọdọ tun ero wọn pa, ki wọn sun diẹ, gegẹ bi awọn to ku ti n ṣe fun wọn. Tafawa Balewa lo kọkọ sọrọ le ọrọ ti Ọọni sọ, o ni koko ipade ti awọn waa ṣe gan-an lawọn n sọrọ le lori yii,  nitori ki awọn Hausa gba idaji orilẹ-ede Naijiria ni yoo sọ bọya awọn yoo maa ṣe Naijiria pẹlu awọn to ku tabi awọn yoo maa ba tawọn lọ. Eyi lo ṣe jẹ pe nigba ti awọn eeyan kan ba n sọ pe Ojukwu lati ilẹ Ibo lo kọkọ ni ki Naijiria pin si meji, wọn ko mọ itan ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ni wọn ṣe n sọ ohun ti wọn n sọ.

Awọn Hausa yii ta ku delẹ, wọn ni ohun kan ṣosọ ti awọn le gba ni ki alaga ipade naa kọ ọ silẹ pe awọn aṣoju lati ilẹ Hausa sọ pe awọn ko ni i ṣe Naijiria bi wọn ko ba ti fun awọn Hausa ni idaji o. Kaka ki awọn tiwa naa si dide ki wọn ni awọn naa o ni i ṣe Naijiria bi wọn ba ti fun awọn Hausa ni idaji o, ko sẹni to sọ bẹẹ, ti awọn Hausa yii ni wọn kọ silẹ. Nigba ti awọn oyinbo to n ṣe olori wa gbe ọrọ yii de ilu oyinbo, wọn ko yẹ ẹ wo lẹẹmeji ti wọn fi ni ohun ti awọn Hausa yii n beere lo dara ju lọ. Bẹẹ ni wọn ṣe kọ ofin yii jade, ofin naa si fun awọn Hausa ni idaji Naijiria. Iyẹn ni mo ṣe sọ pe ki i ṣe pe a dibo, tabi pe sẹnsọ ni wọn ka ti wọn fi ni idaji Naijiria ni ilẹ Hausa, eto lasan ni. Ṣugbọn aburu wo wa ni idaji Naijiria ti awọn Hausa yii gba mu ba wa? Aburu naa pọ ju, ohun ti wọn si fi ba Naijiria naa jẹ titi doni niyẹn. Ẹ jẹ ka pade lori ẹ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply