Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (11)

Ọgbọn buruku wa ninu awọn oyinbo. Gbogbo ohun ti Fulani ṣe fun wa, ati ohun ti wọn n ṣe lọwọlọwọ bayii fun wa, awọn oyinbo lo ta wa fun wọn. Ọgbọn buruku ni wọn lo fun wa. Bẹẹ ni ki i ṣe pe awọn baba wa yii ko kuku gbọn, wọn gbọn daadaa, awọn kan fi inu wenu lasan ni. Wọn ti ro pe bi awọn ti ri ni awọn Hausa wọnyi ri, pe eyi to ṣe koko ju lọ ni pe ki awọn oyinbo yii kọkọ kuro ni Naijiria, ti wọn ba ti kuro, ohun gbogbo yoo dẹrọ, awọn aṣaaju Naijiria yoo mọ bi wọn aa ṣe yanju ọrọ ara wọn. Ṣugbọn gbogbo eyi ti awọn n ro lọkan kọ ni Hausa ati oyinbo n ro: oyinbo n ro bi oun yoo ṣe fi ẹsẹ kan duro ni Naijiria lẹyin ta a ba gba ominira, oyinbo si mọ pe awọn ko le lo Yoruba tabi Ibo fun iru aṣa palapala bẹẹ, Hausa-Fulani nikan lo ṣee lo fun wọn. Awọn Hausa-Fulani yii naa si ṣe bii ẹni pe awọn ko lọgbọn lori, bẹẹ ohun ti wọn fẹẹ ṣe wa ninu wọn.

Mo n ṣe alaye yii nitori awọn eeyan wa kan to n bi mi pe nigba ti awọn Hausa-Fulani n ba ilẹ yii jẹ, ki lawọn Yoruba tiwa n wo. Eeyan yoo beere pe kin ni wọn n wo loootọ, ṣugbọn ẹni to ba mọ ipilẹ ọrọ yoo mọ pe, nibẹrẹ pẹpẹ, ifẹ Naijiria ni Yoruba ni, ohun ti a si fi ko si akolo awọn to ku naa niyẹn. Gẹgẹ bi mo ti wi lọsẹ to kọja, lẹyin ti awọn eeyan wa ti jiroro lori ofin Naijiria, ti awọn Hausa ti ta ku pe afi ki awọn gba Eko, afi ki awọn si ni idaji Naijiria, wọn gbe gbogbo akọsilẹ naa lọ si London, nibi ti awọn alaṣẹ agba pata lọhun-un yoo ti fọwọ si i. Ṣe gbogbo ohun ti wọn jiroro le lori ni Naijiria yii, eyi ti awọn ọga wa yii ba fọwọ si naa ni a oo pada maa lo bii ofin wa. Nigba ti awọn oyinbo yẹ iwe ofin yii wo daadaa, wọn ṣe kinni kan to pa Yoruba lẹnu mọ. Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn ko fọwọ si i ki Eko jẹ ti Naijiria, wọn ni ti Yoruba ni.

Bi ọrọ naa ba ye yin bi mo ti n ṣe alaye ẹ bọ, ṣe ẹ mọ pe awọn Hausa yii kọ nibi ipade Ibadan pe ki Eko jẹ ti Yoruba, ti wọn ki awọn too le maa ṣe Naijiria, afi ki Eko ma si lara Western Region, ko da wa lawọn fẹ, ti awọn ọmọ Yoruba bii Adeleke Adedoyin si tori ọrọ oṣelu ti wọn ni bẹẹ lo dara ju lọ. Nigba ti awọn oyinbo yoo ṣe ofin yii, wọn ni lara Western Region ni Eko yoo wa, nitori ilẹ Yoruba ni, ede kan naa ni wọn n sọ, aṣa kan naa ni wọn si ni, bi eeyan ba ya wọn sọtọ, yoo di idagbasoke wọn lọwọ ni. Ni inu awọn Yoruba ba dun, ati oloṣelu ati awọn ọjọgbọn, wọn n jo lori ọrọ naa ni. Ṣugbọn oyinbo ti gba nnkan nla to ju gbogbo eyi lọ, nitori wọn ti fọwọ si i ki Hausa ni idaji Naijiria. Wọn ti fọwọ si i pe nigba ti a ba fẹẹ ni awọn aṣofin nile-igbimọ apapọ, idaji lawọn Hausa yoo ni, Yoruba ati Ibo ni yoo ni idaji to ku.

Eleyii ko daa fun wa rara, ṣugbọn nitori pe wọn ti ni awọn ko gba Eko lọwọ wa mọ, awọn agbaagba Yoruba ro pe ofin to dara gan-an ni. Nitori bẹẹ, nigba ti wọn dibo nipari ọdun 1951, ti onikaluku ẹgbẹ oṣelu mu ipinlẹ tirẹ: ti NPC tawọn Sardauan mu ilẹ Hausa, ti NCNC tawọn Azikiwe mu ilẹ Ibo, ti Action Group mu ilẹ Yoruba, ohun to ṣẹlẹ ni ileegbimọ aṣofin apapọ yatọ siyẹn. Ni ile igbimọ yii, eniyan mejidinlaaadọjọ (148) ni wọn yan lọ sibẹ. Ninu awọn mejidinlaaadọjọ yii, ọmọ ileegbimọ aṣofin mẹrinlelaaadọrin (74) lo wa lati ilẹ Hausa. Awọn  mẹtadinlogoji (37) wa lati ilẹ Yoruba, metadinlogoji mi-in si wa lati ilẹ Ibo. Nibi ti ọbẹ ti ba idi wa niyi. Idi ni pe ẹnu Ibo ati Yoruba ko ni i papọ lae lae, bi ọrọ kan ba si ti ṣe bii ọrọ, ti wọn ba fẹẹ dibo si i, bi awọn Ibo ko ba tẹle Hausa-Fulani lọ, Yoruba yoo ba wọn lọ. Nidii eyi, awọn Hausa-Fulani yii ni yoo ni ibo to pọ ju, awọn ni wọn yoo bori ninu ohun gbogbo ti wọn ba ni awọn fẹ.

Ṣugbọn aṣiri yii o tete tu ninu ijọba 1952, koda titi wọ 1957, ati ti 1960. Awọn oyinbo ti lọ tan ki awọn aṣaaju Ibo ati Yoruba too mọ pe nnkan ti ko daa ti ṣe awọn. Aṣiri ọrọ yii ko tu ni 1952 nitori awọn oyinbo ni wọn ṣi n ṣejọba, wọn kan fi awọn eeyan tiwa si ipo minisita ni. Ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu ni wọn ti mu awọn ti wọn fi ṣe minisita, iye eeyan kan naa ni wọn si mu ni ilẹ Ibo, ilẹ Yoruba, ati ilẹ Hausa. Koda, nigba to ya, wọn mu eeyan lati ilẹ Yoruba ati Ibo ju ti ilẹ Hausa lọ, nitori ko si onimọ pupọ lọdọ tawọn Hausa to le di awọn ipo wọnyi mu. Ṣugbọn ohun ti awọn oyinbo yii n ṣe ye wọn, wọn fẹẹ fun awọn Hausa yii ni idanilẹkọọ ati iriri to ga, ti wọn yoo fi le maa ṣejọba lẹyin ti wọn ba lọ, bo tilẹ jẹ awọn naa ni wọn yoo ṣi maa gbe ilu oyinbo paṣẹ ohun ti wọn ba fẹ ki wọn ṣe fun wọn.

Nibi ti wahala kọkọ ti bẹrẹ ni ni 1953, ninu oṣu kẹta, ọdun naa. Anthony Enahoro, ọkan ninu awọn aṣofin labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AG dide pe ki wọn jẹ ki Naijiria gba ominira kuro lọdọ awọn oyinbo, o pẹ tan titi ọdun 1956. Enahoro ni eyi tawọn oyinbo ṣe ti to, ki wọn maa waa lọ, awọn ọmọ Naijiria yoo ṣejọba ara wọn funra wọn. Ọrọ naa dun mọ awọn ọmọ ẹgbẹ AG to ku ninu, ati awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC paapaa. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ NPC to jẹ Hausa ni gbogbo wọn lawọn o gba. Wọn ni ki ẹnikẹni ma da iru ọrọ bẹẹ silẹ lasiko yii rara, nitori awọn ko ti i ṣetan lati gba ominira kuro labẹ oyinbo ni tawọn. Nigba ti wọn ni ki wọn dibo sọrọ naa boya ki awọn da a silẹ tabi ki awon ma da ọrọ ọhun silẹ, awọn Hausa fi ibo yanju awọn Yoruba ati Ibo, nitori gbogbo wọn lo dibo wọn soju kan. Alaga ile-igbimọ aṣofin naa to jẹ oyinbo ni si fi aṣẹ si eyi, o ni ko saaye ijiroro lori ọrọ ofin ominira.

Ọrọ naa dun awọn ọmọ ẹgbẹ AG, wọn ni bawo ni wọn yoo ṣe ṣe bẹẹ, ni wọn ba fibinu bọ sita. Bi wọn ti n lọ lawọn aṣofin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ NCNC naa tẹle wọn, ni inu ileegbimọ naa ba ku kidaa awọn Hausa nikan. Awọn onworan ti wọn jẹ ọmọwe ọmọ Yoruba ati Ibo, ti wọn kan maa n waa feti si ijiroro wọn ni ileegbimọ yii, bẹrẹ si i bu awọn Sardauna ati gbogbo awọn aṣofin ti wọn wa lati ilẹ Hausa, wọn ni Mọla ajẹgooro ni wọn, ẹru oyinbo ti ko fẹran ominira. Nigba ti kinni naa yoo kuku tilẹ da oju gbogbo ọrọ to ti wa nilẹ tẹlẹ ru, ọjọ yii jẹ ọjọ tawọn Hausa wọnyi n pada si ilu wọn l’Oke-Ọya. Lati ile ijọba yii ni awọn eeyan ti ho le wọn lori titi ti wọn fi de idikọ reluwee ti wọn n ba pada lọ sile. Bẹe lawọn eeyan wa bu wọn titi ti wọn fi ri ibi sa lọ. Lọjọ yii ni Sardauna tun ni awọn ko ni i pada ṣe Naijiria bi Eko ba wa labẹ ilẹ Yoruba.

Bo si ṣe wi yẹn naa lo ri, nitori nigba ti wọn pada lọ si London ni 1953 lati ṣe atunyẹwo ofin ti wọn ṣe ni 1950 si 1951, wọn gba Eko kuro lọwọ ilẹ Yoruba, wọn ni ti Naijiria ni. Bẹẹ lo jẹ ohun mejeeji ti awọn Hausa yii beere fun nibi ipade akọkọ n’Ibadan pada waa to wọn lọwọ. Wọn beere fun Eko, wọn ri Eko gba; wọn beere fun idaji Naijiria, wọn ri iyẹn naa gba. Ṣugbọn o ku kinni kan ti wọn fẹẹ ṣe ti wọn ko ti i ri ṣe daadaa, iyẹn ni bi wọn yoo ṣe ṣe eto ikaniyan, sẹnsọ, ti yoo fi han pe loootọ, idaji Naijiria ni ilẹ Hausa jẹ. Nitori titi di asiko 1950 ti wọn dana ofin yii, ko ti i si ikaniyan gidi kan to sọ pe idaji Naijiria nilẹ  Hausa. Gbogbo eto ikaniyan ti wọn n ṣe ko too digba naa ki i lọ deede, bii ki wọn kaayan nibi kan ki wọn ma ka wọn nibi kan ni, ati pe ko sẹni to ka eto naa si, nigba to jẹ awọn oyinbo lo n ṣejọba wọn.

NI 1952 si 1953, won gbọdọ ṣeto ikaniyan tuntun, eyi ti yoo fi han pe awọn araabi yii lo ni idaji Naijiria loootọ. Ṣugbọn ki lawọn eeyan yii ṣe. Ẹ jẹ ka maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply