Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (12)

Awọn ọrọ ti mo n sọ yii ṣe pataki gbaa. O ṣe pataki pupọ nitori ajaga to wa lọrun wa yii. Ati nitori pe ti ẹni kan ba dide laarin wa ti yoo ba gba wa ninu ohun ti a ko si yii, ki tọhun le mọ ọna ti yoo tọ, ko si le mọ ohun ti yoo fi ja: ki tọhun mọ idi ti gbogbo ohun to wa nilẹ yii fi ri bayii, ko si mọ ibi ti awọn baba wa ti ṣe aṣiṣe tiwọn. Ẹni ti ko ba mọ, yoo mọ to ba ya. Awọn eeyan miiran ko mọ pe nnkan n ṣe wa ni Naijiria. To o ba n sọrọ, wọn yoo ro pe bo ṣe yẹ ki nnkan ri naa lo ri yii, nitori wọn ko mọ aye miiran ju aye ibajẹ ati inira to wa ni Naijiria yii lọ ni. Awọn ti wọn ti jade, ti wọn ti lọ sawọn ilu nla, ti wọn ti ri bi oju titi wọn ṣe ri, ti wọn ri i bi ina ki i ṣee lọ nibẹ, ti wọn ri i bi intanẹẹti ṣe rọrun fawọn eeyan wọn to, ti omi wa, ti ohun gbogbo wa bo ṣe yẹ nikan lo le mọ ohun ti mo n wi. Bi wọn ti n ṣejọba aye kọ ni wọn n ṣejọba ni Naijiria yii, bo ba si n lọ bẹẹ, a ko le gbe e ja, yoo fọ mọ wa lori lọjọ kan ni. Epe kọ!

Ẹyin naa kuku gbọ owo buruku tawọn eeyan ti wọn sun mọ Buhari n ko jẹ. Nigba ti ẹ ba ṣiro iru owo bẹẹ, ti ẹ si wo ipo pataki ti awọn akowojẹ yii wa, yoo ye yin pe iṣoro n bẹ ki Naijiria too lu aluyọ. Tabi orilẹ-ede wo lo tun wa lagbaaye ti wọn ti n ko iru owo bayii jẹ, owo to yẹ ki wọn fi ṣe ohun meremere fawọn araalu, to yẹ ki wọn fi pese awọn nnkan amayedẹrun fun wọn. Wọn yoo ko owo naa jẹ, wọn yoo ṣe oju tau, nigba ti wọn mọ pe ko si ẹni to maa mu awọn si i. Ọpọ eeyan lo ti n ba mi sọrọ pe ṣebi Ibo ati Yoruba naa n kowo jẹ, esi ti mo si n fun wọn ni pe ohun ti ijọba apapọ n ṣe naa lawọn ti wọn n ba wọn ṣiṣẹ n ṣe. Ohun tawọn alagbara nidii ijọba apapọ ba fi lelẹ lawọn ti wọn jọ n ṣe ẹgbẹ oṣelu kan naa yoo ṣe. Bi ẹni kan ba ji owo ti wọn sọ ọ sẹwọn gbere, tabi to paayan, ti wọn pa oun naa, ti wọn ko fi ti ẹgbẹ tabi ti ẹya si i, aburu ilẹ yii yoo dinku.

Awọn ti wọn n ṣejọba wa ko lọgbọn ijọba ati eto ilu lori ni. Ọlọrun si mọ pe ododo ni mo n sọ. Ọgbọn to wa lori wọn ko ju ọgbọn ka ja ohun olohun gba, ka si lo agbara ipalara tabi itajẹsilẹ lati fi gba kinni naa gbe lọwọ awọn to ni in, ko ma si ohun tẹni kan le ṣe fun wọn. Lati igba ti wọn ti gba Naijiria ni wọn ti n ṣe e, titi di oni yii ti ilẹ mọ, ohun ti wọn si n ṣe naa niyẹn. Gbogbo ohun-ini Naijiria, abẹ ijọba apapọ ni wọn ko o si. Bi wọn ba wa epo bẹntiro ni Naija-Delta, tabi ti wọn pa owo ni igberi-okun Eko, Abuja ni wọn yoo ru owo naa lọ, nibẹ ni wọn yoo ti pin in fun wọn. Nibẹrẹ, ko ri bẹẹ tẹlẹ. Ti wọn ba pa owo ni ipinlẹ kan, funra wọn ni wọn yoo na owo wọn, ti wọn yoo fun ijọba apapọ ni diẹ nibẹ lati fi gbọ bukaata tiwọn. Nitori pe ko sowo gidi kan to n jade nilẹ Hausa ni wọn fi ṣofin pe ohun gbogbo, tijọba apapọ ni.

Ṣugbọn ni bayii, wọn ti ri awọn goolu kan ti wọn n wa lati ilẹ Hausa, ohun to si le mu owo wọle lati ilẹ okeere ni. Njẹ ẹ mọ ohun tawọn to n ṣejọba Buhari yii ṣe, wọn gbe ofin tuntun kan jade lojiji ti yoo jẹ ti ilẹ Hausa nikan, nibi ti wọn ti n wa goolu yii, pe awọn ipinlẹ ti wọn ni goolu yii ni yoo maa paṣẹ, ti wọn yoo si maa ta goolu wọn. Bi awọn ilẹ Hausa ti wọn ni goolu ba n wa a, ti wọn n ta a funra wọn, ki lo ṣẹlẹ si awọn ti wọn n wa bẹntiroolu lọdọ wọn, ki lo ṣẹlẹ si awọn ara Eko to jẹ oju-omi ni ọrọ-aje tiwọn wa. Ṣugbọn wọn maa n ro pe awọn lọgbọn lori ni, wọn aa ro pe awọn gbọn ju awọn to ku lọ. Bẹẹ, ọgbọn ori wọn, ete ni, ki i ṣe ọgbọn to ni anfaani ninu. Ṣebi ẹyin naa mọ igba ti wọn gbe ọrọ RUGA de, ti wọn fẹẹ gba ilẹ Yoruba ati Ibo fawọn Fulani, bi ariwo ko ba pọ, bi wọn yoo ti ṣe niyẹn. Ete ti wọn n pe lọgbọn niyẹn.

Eyi to buru ni pe bi wọn ba gbe awọn aṣa palapala yii de, awọn eeyan tiwa ni wọn yoo lo, ti wọn yoo maa ba wọn polongo, ti wọn yoo ni awọn n ṣe oṣelu, ti wọn yoo ni ẹgbẹ awọn lo wa nijọba. Ẹyin ti ẹgbẹ oṣelu yin wa nijọba, ti ẹ ko mọ ohun ti ijọba naa n ṣe, ti ẹ ko mọ ọna ti ijọba naa n tọ, ti ẹ oo si maa pariwo oponu kiri pe ẹyin lẹ n ṣejọba. Bẹẹ awọn ti wọn n ṣejọba wa ni kọrọ ibi kan ti ẹyin ko foju ri, wọn n jẹ yin pa, wọn n jẹ awọn ọmọ yin pa, wọn n jẹ iran yin pa. Bẹẹ lẹ n tẹle wọn bii agutan, titi ti wọn fi ko laakaye yin lọ. Nitori pe ilọsiwaju ko ba wọn nilẹ Hausa, wọn ṣe e ṣe e, wọn di ilọsiwaju ilẹ Yoruba naa lọwọ. Awọn ọmọ ko fẹẹ kawe mọ, awọn ti wọn kawe ko mọwe ọhun, nitori wọn ti ri awọn ọmọ ilẹ Hausa ti wọn ko kawe, ti wọn ko mọwe, sibẹ, to jẹ awọn ni wọn n lowo ju, awọn ni wọn si n di ọga nidii iṣẹ ijọba. Bawo leeyan ṣe n ṣe bẹẹ, orilẹ-ede wo lo n ṣe bẹẹ ti i nilaari.

Irẹjẹ ni! Irẹjẹ naa si bẹrẹ lati aye igba ti wọn ti sọ pe awọn Hausa-Fulani yii ni wọn ni idaji Naijiria yii ni. Mo sọ fun yin pe titi di igba ti wọn fi ṣepade yii ni 1950, ko si eto ikaniyan, sẹnsọ, gidi kan to fi i mulẹ pe awọn Hausa pọ leeyan ju awọn Yoruba ati Ibo lọ. Lati ibẹrẹ pẹpẹ ni ija ati owu-jije ti wa laarin awọn oyinbo ti wọn n ṣejọba Guusu Naijiria (ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo) pẹlu awọn oyinbo wọn n ṣejọba Ariwa Naijiria (ilẹ Hausa). Idi ni pe nigba naa, ilu oyinbo ni wọn ti n fun wa lowo ti a n na fun idagbasoke. Nitori pe awọn eeyan n ṣiṣẹ, wọn si n lowo nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, ti ko si sẹyin ilẹ Hausa, ọna kan naa ti awọn oyinbo ti wọn n ṣejọba ilẹ Hausa fi le gba owo lati ilu oyinbo ni lati sọ pe awọn eeyan ti wọn wa nilẹ Hausa yii pọ ju ero to wa nilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba lọ. Nibi ti ọrọ yii ti kọkọ bẹrẹ niyẹn.

Nigba to ya, ijọba awọn oyinbo yii bẹrẹ si i yawo lọwọ awọn ijọba Guusu Naijiria (South) lati fi ṣe eto idagbasoke ni Ariwa (North) akosilẹ oriṣiiriṣii lo fi eleyii han. Owo ti wọn ba ya lọdun yii, wọn ko ni i le da a pada titi ti ọdun mi-in yoo fi pe. Nigba ti wọn ko kuku ri owo yii da pada ni awọn oyinbo ni Britain kuku paṣẹ pe ki wọn ma fi owo naa ṣe owo yiya mọ, ki wọn kuku maa fi i ṣe owo iranlọwọ lati ọdọ awọn ara Guusu si ọdọ awọn ara Ariwa, nitori pe ero to wa nibẹ pọ. Bẹẹ ọrọ naa ki i ṣe pe ero to wa nibẹ pọ, awọn oyinbo yii dọgbọn bẹẹ lati maa ri owo gba lati ọdọ ijọba wọn ni Britain ni, ati lati maa ri owo iranlọwọ gba lati ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo. Owo iranlọwọ ti wọn n ṣe nigba naa, owo ti Yoruba ati Ibo fi n ran ilẹ Hausa lọ  wọ nibẹrẹ ajọṣepọ wa, owo naa ni ijọba awọn Fulani n fi tipatipa gba lọwọ wa bayii, ti wọn si ni tiwọn ni Naijiria.

Ki i ṣe pe wọn pọ ju wa lọ rara lati ibẹrẹ gẹgẹ bi awọn eeyan ti n wi. Kinni kan ṣẹlẹ lasiko ti wọn ṣeto ikaniyan lawọn ilu nla nla ni Naijiria lọdun 1952 si 1953, iyẹn lẹyin ti wọn ti ṣepade ti wọn ṣe yii tan, ti wọn ni ilẹ Hausa lo ni idaji Naijiria. Nigba ti wọn ṣeto ikaniyan awọn ilu nla yii, ko si ilu kankan ni Naijiria to sun mọ ilu Ibadan rara. Nigba naa paapaa, ilu Ibadan ni ilu keji to tobi ju lọ ni gbogbo ilẹ Afrika. Nigba naa, ko si ilu nla kan to tobi to ilu kankan ni ilẹ Yoruba yii, ikaniyan ọdun 1952 si 1953 yii si tu aṣiri ohun gbogbo tawọn eeyan yii ṣe pe wọn pọ ju wa lọ. N oo sọ iye awọn ti wọn ka ni ilu nla kọọkan lọsẹ to n bọ, ati ọgbọn buruku mi-in tawọn oyinbo yii atawọn Hausa-Fulani da lati yi nnkan pada fun wa. Ati igba naa lawọn Hausa-Fulani yii ti wa lori aga irẹjẹ, aga ayederu, aga tipatipa, ti wọn si tibẹ ba Naijiria jẹ patapata.

3 thoughts on “Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (12)

  1. Ero teminiwipe ki yoruba pada sile kawatun ilewa se . Eyiti ase ninu oko eru to gee . Tiabasinsowipe one nation ni ilu Nigeria yi. Ewo inu wahala ati ipayin keke ni omo yoruba simawa titidi ola. Ejeki awusa gbegbe awusa . Ki yibo gbe igbe yibo. Ki yoruba gbegbe yoruba. Owa wa ku si owo onikaluku wa . Biase mawase eto arawasi. Mosibo na

Leave a Reply