Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (13)

Gẹgẹ bii ileri ti mo ṣe lori ọrọ ti a n ba bọ latẹyin, mo sọ pe n oo sọ iye awọn eeyan ti wọn wa niluu nla kọọkan ni Naijiria laarin ọdun 1952 si 1953 fun yin. Ohun ti mo ṣe fẹẹ fi ẹsẹ eleyii mulẹ ni pe eto ikaniyan naa tu aṣiri ti awọn eeyan yii bo, o si fi magomago ti awọn oyinbo ati awọn aṣaaju Fulani ṣe fun awa Yoruba ati awọn Ibo han. Ohun ti wọn sọ ni 1950 nibi ipade ni pe awọn pọ ju gbogbo eeyan to ku lọ, nitori ẹ ni wọn ṣe fun wọn ni idaji Naijiria, ti wọn ni nile-igbimọ aṣofin ati nidii ohun gbogbo, Hausa-Fulani yoo kọkọ mu idaji ki awọn ẹya to ku too maa mu. Ṣugbọn nigba ti wọn ka awọn eeyan ti wọn wa ni awọn ilu nla ati agbegbe wọn kaakiri ni ọdun 1952 si 1953, eto ikaniyan naa fi han pe irọ gbuu lọrọ naa, koda awọn eeyan yii ko sun mọ ohun ti wọn n wi rara, wọn kan rẹ awọn to ku jẹ ni.

Lati ọdun 1911, ko si igba kan ti wọn kaayan ni Naijiria ti ki i ṣe ilu Ibadan ni yoo han pe ero pọ si ju lọ. Nigba ti wọn ka ti 1952 si 1953 yii, ero to wa ni ilu Ibadan nikan jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo o din diẹ (459,196). Bi wọn ti ṣe n pariwo pe Kano tobi to nigba naa, ti wọn n ni Kano lo tobi ju lọ ni ilẹ Hausa, gbogbo awọn ti wọn ka nibẹ ko ju ẹgbẹrun lọna aadoje (130,173) lọ. Itumọ eyi ni pe ninu Ibadan nikan, eeyan yoo yọ ilu Kano mẹta, gẹgẹ bii iye awọn eeyan ti wọn wa nibẹ ni 1952. Koda, Kano meji leeyan yoo yọ ninu awọn ara Eko igba naa, nitori ẹgbẹrun lọna ọtalenirinwo ati meje o tun le (267,407) lawọn eeyan Eko igba naa. Bẹẹ Eko ti wọn ka nigba naa yii ko de gbogbo apa Agege, Ikọtun Idimu, Ọjọ, Okoko, ati awọn ilu ti wọn wọnu bẹẹ lọ, awọn ilu Eko to wa ni gbangba nikan ni wọn ka.

Ogbọmọṣọ ni ero tun pọ si ju lọ, lẹyin Ibadan ati Eko, nitori ẹgbẹrun lọna ogoje o din diẹ (139,345) lawọn ti wọn ka nibẹ. Lẹyin Ogbomọṣọ lo kan Oṣogbo, awọn eeyan ti wọn ka iye wọn lọhun-un lasiko naa si jẹ ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgọfa o din diẹ (122,728). Bi ero ti pọ ni Oṣogbo naa ni wọn pọ ni Ile-Ifẹ, nitori ero ẹgbẹrun lọna mọkanlelaaadọfa o din diẹ (110,790) ni wọn ka ni Ifẹ lasiko yẹn. Awọn eeyan ti wọn wa ni ilu Iwo paapaa ju awọn ti wọn wa ni Abẹokuta lọ. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un to le eeyan mẹfa pere (100,006) lawọn ti wọn kan ni ilu Iwo, nigba ti awọn ara Abẹokuta lọdun 1952 ti wọn ka wọn ko ju ẹgbẹrun lọna mẹrinlelọgọrin ataabọ (84,451) lọ. Iye ẹgbẹrun kan naa awọn eeyan ni wọn wa ni Ileṣa pẹlu Ọyọ, wọn kan ju ara wọn lọ diẹdiẹ ni. Nigba ti awọn ti Ọyọ jẹ ẹgbẹrun mejilelaaadọrin ati mẹtalelaaadoje (72,133), awọn ti wọn ka ni Ileṣa jẹ ẹgbẹrun mejilelaaadọrin ati mọkandinlọgbọn eeyan pere (72,029).

Ni gbogbo awọn ilu ilẹ Yoruba ti mo n darukọ wọnyi, ti a ba ti yọwọ Kano ti mo sọ ṣaaju nikan kuro, ko si ibi kankan tabi ilu kan, ti awọn eeyan ibẹ to ti awọn ilu ilẹ Yoruba ti mo sọ iye wọn yii. Bi a ba ti yọ Kano kuro, Maiduguri lo tẹle e, ẹgbẹrun marundinlọgọta o din diẹ (54,646) lawọn ti wọn wa nibẹ, nigba ti awọn ti wọn wa ni Zaria lasiko yii jẹ ẹgbẹrun mẹrinlelaaadọta din rebete (53,974). Ẹgbẹrun mẹtalelaaadọta o din diẹ (52,672) lawọn eeyan ti wọn ka pe wọn wa ni Katsina, awọn ti wọn si wa ni Ṣokoto ko ju ẹgbẹrun mejidinlaaadọta o din diẹ (47,643) lọ. Ninu awọn ilu to tun lero ni ilẹ Hausa nigba naa, Ilọrin lo tẹle awọn ti mo ti sọ wọnyi, gbogbo eeyan lo si mọ pe ilẹ Yoruba ni ilu Ilọrin, awọn Yoruba lo wa nibẹ, wọn ki i ṣe Fulani tabi Hausa, wọn gba ibẹ lọwọ wa fun irẹnijẹ lasan ni. Ẹgbẹrun mọkanlelogoji o din ṣin-un (40,994) lawọn ti wọn ka niluu Ilọrin.

Ero to wa ni Kaduna ko to ti ilu Isẹyin. Ẹgbẹrun mọkandinlogoji o din (40,794) lawọn ti wọn wa ni Kaduna yii, bẹẹ aadọta ẹgbẹrun din diẹ (49,690) lawọn ti wọn wa ni Isẹyin nigba yẹn. Ero to wa ni Jos naa ko to awọn ti wọn wa ni ilu Ẹdẹ. Ẹgbẹrun lọna mejidinlogoji ataabọ (38,527) lawọn ti wọn wa ni Jos, bẹẹ ero to wa ni Ẹdẹ lasiko yii, ẹgbẹrun marundinlaaadọta o din diẹ (44,808) ni. Gbogbo eyi fi han pe ni 1952, ko si ilu kankan ni ilẹ Hausa ti ero to wa nibẹ ju ti Ibadan, Eko, tabi Ogbomọṣọ lọ. Wọn ju wọn lọ fii-fii, bo tilẹ jẹ pe eto ikọle tiwa yatọ si tiwọn. Awa maa n kọle papọ ni, awọn ni wọn maa n kọle kan sibi, to jẹ o le fẹrẹ rin maili kan ki o too tun ri ile mi-in. Bi wọn ba kọ abule kan ti gbogbo orule to wa nibẹ ko ju mẹwaa lọ si ibi yii, o le rin to maili ọgbọn ki o too tun kan abule mi-in, orule ibẹ naa si le ma ju mẹwaa lọ.

Iyatọ to wa laarin wa naa niyẹn, awọn ni ilẹ, ilẹ to pọ, ṣugbọn ko si eeyan bii tiwa. Ohun to fa eleyii ko si le. Ki ẹgbọn waa agba, Richard Akinjide, too ku, lẹyin ti awọn Hausa-Fulani yii ti lo o lo o titi lati ba nnkan jẹ fun Yoruba, oun funra ẹ lo ṣalaye pe awọn Hausa-Fulani ko pọ ju wa lọ. O ni gbogbo ohun ti wọn ni ko ju ilẹ lọ, wọn ko leeyan. O ni bo ṣe ri bẹẹ ni pe nibi gbogbo to ba jẹ aṣalẹ, ti ko si omi, awọn eeyan ibẹ ki i pọ to ti awọn agbegbe ti wọn ba jẹ ilẹ omi, ti igbo si pọ daadaa. Ko si igbo ni ilẹ Hausa, papa lo pọ nibẹ, idi ti awọn Fulani wọn si fi maa n da maaluu kiri ree, nitori wọn n wa ibi ti maaluu wọn yoo ti maa ri omi mu. Akinjide sọ nigba naa pe Naijiria tiwa yii nikan ni ibi ti awọn eeyan ti wọn n gbe ni aṣalẹ (bii ilẹ Hausa yii) ti pọ ju awọn eeyan ti wọn n gbe ni ilẹ omi, ilẹ ọlọraa ti igbo ati omi pọ si lọ.

Ohun ti awọn oyinbo ṣe fun wa niyi. Magomago ti awọn Hausa-Fulani wọnyi si ṣe fun wa niyẹn. Awọn oyinbo lo kọ wọn ni ọgbọn buruku yii, ohun ti wọn si fi kọ wọn naa ni pe ki wọn ma jẹ ki awọn ti wọn n ṣeto ikaniyan wọ awọn ile to wa ni igberiko, awọn abule keekeeke. Nitori ẹ, ti wọn ba de abule kan, ti ile meji pere wa nibẹ, boya ọkunrin kan to n sin maaluu ati iyawo rẹ, boya gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ ko pe ogun, wọn yoo ni awọn to n kaayan yii ko le wọ inu ile awọn, nitori Musulumi lawọn, keferi si ni awọn to fẹẹ waa ka awọn yii, wọn yoo ni awọn yoo ba wọn ka awọn eeyan awọn. Bi wọn ba jade si wọn, awọn ti wọn ko pe ogun yii yoo ni ọgọrun-un meji lawọn. Ohun ti awọn ti wọn lọ sibẹ yoo si kọ silẹ fun wọn naa ree, nibi ti wọn ti n ri nọmba rẹpẹtẹ yii ree. Bẹẹ ni ki i ṣe pe wọn deede ṣe eyi, asọtẹlẹ ti wọn ti sọ fun wọn ni.

Awọn oyinbo yii ti sọ fun awọn Sardauna pe wọn ni lati ri i pe awọn eeyan ọdọ wọn pọ ju ti ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo lọ, bi wọn ba fẹẹ maa jẹ olori fun wọn o. Nitori ẹ, ojule si ojule, ati mọṣalaaṣi si mọṣalaasi lawọn eeyan yii n kede kiri fawọn eeyan wọn pe ki wọn ma jẹ ki ẹnikẹni wọ ile wọn lati ka wọn, awọn ni ki wọn maa sọ iye awọn eeyan ti wọn ba wa lọdọ wọn, ki wọn si ri i pe awọn bu mọ iye awọn eeyan naa daadaa. Wọn sọ fun wọn pe aṣiri ọrọ naa ko le tu, bi wọn ko ba ti jẹ ki awọn ti wọn n ṣe eto ikaniyan yii wọ inu ile wọn. Nigba to si jẹ awọn oyinbo ti wọn kọ wọn ni ọgbọn buruku yii naa ni wọn yoo pada waa fọwọ si iye awọn eeyan ti wọn ba ni wọn ka nibẹ, awọn ni wọn n din iye eeyan to wa nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ku, ti wọn yoo si ni awọn ilẹ Hausa lo pọ ju.

Idi kan naa ti wọn si fi n ṣe eyi ni lati le maa ko owo ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba fi tun awọn ilu ilẹ Hausa ṣe. Lati igba ti Naijiria yii ti bẹrẹ ni wọn ti n ṣe bẹẹ fun wa, ohun to si n fa wahala fun wa ree, ajaga ti awọn oyinbo ati awọn Fulani wọnyi ti fi si wa lọrun lati ibẹrẹ ọjọ aye wa ni. Ni 1962, awọn Awolọwọ ri kinni yii, wọn si gbiyanju lati yi i pada. Ṣugbọn ibi to yọri si ko daa. N oo ṣalaye eleyii siwaju si i lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply