Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (8)

N ko koriira awọn Hausa-Fulani, nitori ko sohun ti mo fẹẹ fi ikoriira wọn ṣe. Ṣugbọn ni tootọ, mo koriira iwa awọn aṣaaju wọn, nitori arẹnijẹ ni wọn, ole ati ọlẹ pọ ninu wọn, awọn ti wọn fẹran lati maa rẹ mẹkunnu jẹ ki wọn le maa jaye ọlọba. Mo n sọ eleyii nitori awọn kan ti wọn n beere leyin ọrọ ti mo sọ nipa Ilọrin lọsẹ to kọja pe ṣe mo koriira awọn Fulani ni. Ọmọ ale ni yoo ri inu ti ko ni i bi. Bi ẹ ba wo ohun tawọn Fulani ṣe fun Yoruba n’Ilọrin, ati ohun ti wọn ṣi n mura lati ṣe lọwọlọwọ bayii, ko sẹni ti yoo ri  iru awọn eeyan bẹẹ to maa fẹran wọn. Fulani ni yoo gba ilẹ onilẹ, ti wọn yoo gba ohun-ini ẹlomiiran, ti wọn yoo si fẹ ki awọn ọmọ awọn ti wọn ni nnkan naa maa waa ṣiṣẹ sin awọn. Awọn ki i ṣiṣẹ, alarinkiri ni wọn, ṣugbọn bi wọn ti n rin kiri yii ni wọn yoo maa jẹ nnkan tawọn ẹlomiiran fi aye wọn ṣiṣẹ fun, titi ti ti wọn yoo fi jẹ wọn pa. Ibi tawọn Hausa-Fulani ba Naijiria de, ibẹ la wa ti ohun gbogbo daru mọ wa lọwọ yii.

Ẹ jẹ ki a maa ba itan wa bọ. Nibi ti mo sọ itan mi de ni ibi tawọn Hausa-Fulani ti wọn wa nibi ipade apapọ ti wọn kọkọ ṣe nilẹ yii lori ofin ti wọn yoo fi maa ṣejọba Naijiria lẹyin ta a ba gbominira ti ta ku pe awọn fẹ Eko, awọn si fẹ ki wọn fawọn ni idaji Naijiria nileegbimọ aṣofin. Eto ti awọn ti wọn dabaa ofin ti wọn n ṣepade le lori yii lati ilẹ Yoruba ṣe ni lati ri i pe Eko bọ si abẹ Western Region, nigba to ṣe pe ilẹ Yoruba ni. Ṣugbọn awọn Hausa-Fulani ti wọn wa nipade naa ko fẹ. Wọn ni ti awọn yoo ba ṣe Naijiria, ti awọn aa si fi ilu Eko ṣe olu ilu fun Naijiria naa, afi ki Eko yii ma si labẹ ẹni kan, ko jẹ abẹ ijọba apapọ ni yoo wa, ki Eko danfo gedegbe. Ọrọ yii o ye awọn mi-in nipade ti wọn wa yii, awọn kọọkan lo ye. Ṣugbọn kinni naa ye awọn Hausa ati awọn oyinbo ti wọn n ti wọn lẹyin, wọn mọ pe ẹni to ba l’Eko lo lagbara.

Ọmọ ina la a ran sina: ainiṣọkan, ilara ati ọtẹ to ti n ba Yoruba ja lati ọjọ yii, ati ailebara-ẹni-ṣe to wa laarin Yoruba ati Ibo fara han nibi ipade yii, nitori awon Hausa-Fulani wọnyi dẹ Yoruba si Yoruba, wọn tun dẹ awọn Ibo si Yoruba, ọgbọn ti wọn lo ti Eko fi bọ si wọn lọwọ niyen. Ọjọ Satide, ọjọ kẹrindinlogun (16), oṣu Kin-in-ni (1) 1950 ni wọn bẹrẹ ijiroro lori pe ṣe ki Eko bọ saarin ilẹ Yoruba tabi ko wa gedegbe, ko jẹ ti Naijiria pata labẹ ijọba apapọ. Ọjọ nla lọjọ naa, nitori niṣe lawọn Hausa-Fulani to wa nibi ipade yii ta kete ti wọn n woran bi Yoruba ti n fa ọrọ mọ Yoruba lẹnu, nitori ọrọ Eko, ati bi Ibo ti n ja ọrọ gba mọ Yoruba lẹnu nitori ọrọ Eko yii kan naa. Niṣe lo da bii pe wọn o mọ rara pe ohun ti yoo jẹ wa niya gidi lọjọ ọla lawọn n ṣe. Kaka ki wọn fohun ṣọkan, ki wọn gba Eko silẹ Yoruba, ija ni wọn n ja ti kinni naa fi bọ lọwọ wọn.

Bọde Thomas lo kọkọ sọrọ, o ni oun fara mọ abadofin ti awọn igbimọ to jiroro lori ofin tẹlẹ gbe kalẹ pe ki awọn da Eko pọ mọ ilẹ  Yoruba, o lohun to daa ju lati ṣe niyẹn. Aṣoju Eko ni Bọde Thomas nipade yii, o si lẹnu lati sọ ohun to sọ. Ṣugbọn bo ti sọrọ ni gbogbo awọn Ibo to wa nipade dide lohun kan, wọn ni ko sohun to jọ bẹẹ. Wọn ni ko sẹni ti yoo gba ki wọn so Eko mọ ijọba West lae, afi ti wọn o ba ni i fi i ṣe kapita fun Naijiria mọ lo ku. Bi Ibo ba dide bẹẹ, ti wọn ba sọ pe awọn ko gba, ọrọ naa gbọdọ yeeyan daadaa. Orogun ni Ibo ati Yoruba, paapaa lori ọrọ idagbasoke ati ilu Eko yii gan-an. Iwọnba awọn ti wọn ti kawe nigba naa ti wọn jẹ ọmọ Ibo, Eko ni wọn pọ si ti wọn n ba awọn Yoruba ọmọwe to pọ ju wọn lọ ta kanngbọn. Bẹẹ si lawọn oniṣowo nla nla aarin wọn naa.

Igbagbọ wọn ni pe bi Eko ba bọ si ọwọ Yoruba, Yoruba yoo fi iya jẹ awọn, wọn ko ni i jẹ ki Eko ṣee lo fun awọn bi awọn ti fẹ mọ. Ṣugbọn wọn mọ pe ti Eko ba jẹ ti ijọba apapọ, ko sẹni kan to ni in niyẹn, ara to ba si wu awọn lawọn le da nibẹ, ko sẹni ti yoo halẹ kan mọ awọn. Ohun ti awọn ṣe fẹ ki Eko wa gedegbe ree, paapaa nigba ti Azikiwe to jẹ ọmọ Ibo wa nile-igbimọ, to n sọju Eko lapapọ. Nitori ẹ, bi awọn Ibo ba ṣe ohun ti wọn ṣe yii, iba leeyan yo bu wọn mọ. O yẹ ki awọn Yoruba ti wọn wa nibẹ mọ bi wọn yoo ṣe tu wọn, ti wọn yoo jẹ ki wọn mọ pe ti ọwọ Hausa ba tẹ Eko, adanu to maa ti ibẹ wa maa pọ ju oore ti wọn ro pe o wa nibẹ fun awọn lọ o.  Awọn Yoruba tiwa ko ṣe bẹẹ o, awọn gan-an ni ija tiwọn buru ju.

Ẹni to kọko fọ wahala yii loju ni Ọmọọba Adeleke Adedoyin, ọmọ Ọba Rẹmọ ni o, ṣugbọn ninu ẹgbẹ NCNC, ẹgbẹ Azikiwe, lo wa, koda, oun ati Azikiwe jọ lọ sileewe kan naa ni. Niṣe lo dide nipade to ni iru ọrọ wo lawọn ti wọn fẹẹ da Eko pọ mọ ilẹ Yoruba n sọ yẹn. O ni o ma dun oun o, o dun oun gidi pe Azikiwe ko wa sipade naa, ṣugbọn baba ko si, baba wa ni. O ni bi oun ṣe n sọrọ yii, gbogbo awọn oludibo Eko pata ni wọn wa lẹyin oun, wọn si ti fohun ṣọkan pe ki oun ṣoju wọn, ki oun si sọ fun ipade naa pe awọn Eko ko fẹẹ darapọ mọ Western Region o, wọn ko fẹẹ wa laarin awọn Yoruba to ku, wọn fẹẹ da duro ni. Ṣugbọn bi ẹgbẹ awọn ọmọ Eko ti gbọ ọrọ to sọ nipade yii, niṣe ni wọn gbe atẹjade kan jade lọjọ kan naa, wọn ni ko sẹni to ran Adedoyin niṣẹ to n jẹ yii, koda, ko dagbere fun oludibo Eko kan ko too lọ. Awọn gẹgẹ bii ọmọ Eko, awọn fẹẹ wa laarin awọn Yoruba to ku ni o.

Lọjọ keji, ọrọ yii kan naa ni wọn tun n fa nipade yii. E. A Bankọle sọ pe oun ti gba aṣẹ lọdọ Ọba Eko, pe ki wọn da ilu Eko mọ ilẹ Yoruba to ku ni yoo ba wọn lara mu. Ṣugbọn Ibiyinka Ọlọrun-Nimbẹ, oloṣelu NCNC mi-in, ni laelae, Eko ko ni i si labẹ West.  Ẹni kan ti ko si ninu ipade yii, ṣugbọn to lokiki gan-an ninu ọro ilu igba naa, H. O. Davies, kọwe gbọọrọ sinu Daily Times lọjọ keji, o ni ohun tawọn eeyan fi n fẹ ki Eko bọ si aarin ilẹ Yoruba ni pe ede kan naa ni wọn jọ n sọ, aṣa kan naa ni wọn ni, ṣugbọn ọrọ Naijiria tobi ju bẹẹ lọ, bi a ba fẹ ki Naijiria wa, afi ki Eko wa lominira ara ẹ, ko ma si labẹ Western Region. Awọn aṣaaju Eko mẹrin mi-in sọrọ, H.S.A Thomas, Oloye Masha, T. A. Doherty ati Ọgbẹni A. F. Masha, gbogbo wọn lo sọrọ si Adedoyin, pe ki lo n ṣe e ti ko ṣe ẹni kan ri, ara Yoruba l’Eko wa, Yoruba ni Eko, ẹni kan ko si gbọdo ya wọn kuro laarin ara wọn.

Aṣoju awọn ọlọja Ebute-Ero, Ọmọọba Aminu Kosọkọ, tilẹ sọrọ, o ni awọn onijẹkujẹ kan ni wọn n lẹdi pọ mọ awọn ọmọ Ibo lati ya Eko kuro lara ilẹ Yoruba, ko sọmọ Eko ti ko fẹẹ ba ilẹ Yoruba to ku ṣe. Ṣugbọn nitori pe awọn ti wọn n sọ pe awọn ko fẹ Eko lara ilẹ Yoruba yii, oloṣelu NCNC ni wọn, ọmọwe taara – lọọya ni Adedoyin, lọọya ni H. O. Davies, dokita ni Nimbẹ, NCNC si ni gbogbo wọn – wọn jade lati ba awọn aṣoju lati ilẹ Ibo ati lọdọ awọn Hausa ti wọn ti n tan wọn sọrọ, nigba ti wọn si dibo lori ọrọ naa, awọn mọkandinlọgbọn ni wọn dibo pe ki wọn ya Eko kuro lara ilẹ Yoruba, awọn mẹrinla pere ni wọn dibo pe ki wọn ma ṣe bẹẹ. Ọjọ kọkandinlogun, osu kin-in-ni, 1950 yii, ni wọn ṣe bẹẹ, ọjọ ti wọn ya Eko kuro lara ilẹ Yoruba labẹ ofin niyẹn.

Bi ẹnu Yoruba ba ko nipade yii ni, Eko yoo wa lọwọ wa nigba naa, ṣugbọn nitori ainiṣọkan ati ọgbọn agbọnju, awọn Hausa-Fulani ti ko ni lọọya, ti wọn ko ni dokita gba Eko. Idi niyi to fi jẹ ni gbogbo aye awọn oloṣelu atijọ, awọn Hausa ni wọn n ṣe minisita ilu Eko: Muhammaadu Ribadu, Musa Yaradua, ati Shagari. Awọn ni wọn pin gbogbo ilẹ Ikoyi ati Victoria Island, ti wọn si ko awọn eeyan wọn wa si Ọbalende rẹpẹtẹ. A oo maa sọ bi wọn ṣe gba idaji Naijiria lọsẹ to n bọ.

3 thoughts on “Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (8)

  1. Huuuuun Kolorun saanu wa, inu buruku, keeta, ote tutu, jamba, manafiki ati rikisi awon Aarun wonyii na nba Yorùbá ja lojo titi pe ni o je enu wa sokan ka si ni ilosiwaju. Yorùbá kii fe ku paapaa to ba n rije daadaa fun idi eyi won ko ko ki gbogbo ilu padanu nnkan ribiribi tori apo ara won

Leave a Reply