Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (9)

Mo n tẹnu mọ ipade ofin ilẹ wa ti wọn ṣe ni ọdun 1950 yii pupọ, nitori mo fẹ kawọn eeyan mọ pe nibẹ ni iṣoro wa ti wa ni, ibẹ lo ti bẹrẹ. Bi a ba le ri ọna pada si idi ijokoo yii, ti a tun ohun to bajẹ lọjọ naa ṣe, Naijiria yoo dara. Lọjo ti wọn ti ko ijokoo ijọba Naijiria kuro l’Ekoo lọ si Abuja, ọjọ naa lawọn Hausa-Fulani ko ti ba Yoruba du Eko mọ, ati awọn Ibo naa. Ṣugbọn ẹ boju wẹyin ki ẹ wo o, awọn ti wọn n pariwo lọjọ kin-in-ni ana pe ti wọn ba fẹẹ fi Eko ṣe olu ilu Naijiria, ko ni i jẹ ti ẹnikẹni ninu Yoruba, Ibo tabi Hausa, ti wọn si fi ẹtan bayii gba Eko lọwọ awa Yoruba, awọn yii kan naa ni wọn ko gba bayii ki ẹnikẹni sọ pe Abuja ki i ṣe ti Hausa. Bo tiẹ jẹ pe wọn ti fi owo ijọba apapọ Naijiria sanwo rẹpẹtẹ fawọn ti wọn ni Abuja lati sọ ọ di ti gbogbo Naijiria, sibẹ, ati kekere ati agba Hausa-Fulani, ko sẹni to gba pe Abuja jẹ ti ẹlomiiran ju tiwọn lọ. Gbogbo ohun tijọba n ṣe sibẹ, bii pe ogun tiwọn ni ni wọn ka a si.

Mo sọ fun yin tẹlẹ pe ọrọ ijọba Naijiria yii, ṣokoto agbawọ ni, bi ko fun wọn lọrun ẹsẹ, yoo ṣo wọn leekun, rẹgi lohun ẹni n ba ni mu. Awọn ti wọn n ṣejọba yii ko mọ ojutuu ijọba ti wọn n ṣe. Loootọ ni wọn mọ ọgbọn alumọkọrọyi, arekereke ati ete oṣelu, ṣugbọn ko si ọgbọn tabi imọ eto iṣakoso kan bayii lori wọn. Bi wọn ba ni agbara lọwọ, wọn yoo ṣi agbara naa lo titi awọn ti wọn n lo agbara le lori yoo fi maa pariwo pe awọn ko gba mọ; bi wọn gbe wọn si ile-owo, won yoo si sọ ile-owo naa dahoro to jẹ wọn yoo jẹ gbese kẹyin ni. Mo ti sọ fun yin pe ẹni ti yoo da aṣọ fun ni, ti ọrun rẹ ni kẹ ẹ kọkọ wo. Ẹni to ba fẹẹ ṣejọba Naijiria, ẹ kọkọ wo bi tọhun ti ṣe ileeṣẹ toun funra ẹ da silẹ si. Ileeṣẹ wo lọmọ Hausa kan da silẹ nilẹ yii ri, yatọ si iṣẹ kata-kara, bii ti Dangote, nibi ti wọn yoo ti maa fi agbara ijọba rẹ awọn oniṣowo to ku jẹ.

Buhari lo n ṣejọba yii. Njẹ ẹyin ko kiyesi iyatọ to n waye lẹyin ti Abba Kyari ti ku. Ẹ ko ti i ri i pe awọn mi-in ti gba agbara. Nigba ti Kyari wa laye, awọn ile-igibimọ aṣofin wa wa nibẹ, wọn ko le sọrọ; awọn minisita ti wọn ni awọn n ba Buhari ṣiṣẹ ko foju ara wọn ri Buhari, sibẹ, wọn ko le sọrọ; Kyari lo n paṣẹ fun wọn, oun lo n gba iṣẹ Buhari ṣe. Ẹni ti yoo ba gbo o lẹnu, yoo dẹ Magu, olori EFCC, si i; kia ni wọn yoo ni iyẹn ti ko owo kan jẹ nigba kan, ọna ẹwọn ni wọn n ran an lọ yẹn. Nitori pe ole buruku lawọn naa, ti wọ̀n ko si fẹẹ ṣẹwọn, ko si minisita tabi oṣiṣẹ ijọba, tabi oloṣelu kan to jẹ gbin, ohun ti Kyari ba ti ṣe labẹ ge. Bi ẹ ba fẹẹ mọ bi agbara Kyari ti to, ati bo ṣe jẹ loootọ ni Buhari funra ẹ ko mọ ohun to n lọ ninu ijọba ẹ yii, ọrọ Magu yii ni kẹ ẹ fi ṣe akawe. Magu fi ọdun marun-un wa nipo olori EFCC, ipo naa ko si bofin mu.

Ọna ti ko fi bofin mu ni pe ẹnikẹni ti Buhari ba fẹẹ yan si iru ipo bayii, dandan ni kawọn aṣofin Naijiria fọwọ si i. Ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla, ọdun 2015 (09/11/15), ni Buhari yan Magu, tipatipa lo si fi fi orukọ ẹ ranṣẹ ninu oṣu keje, 2016, si awọn aṣofin pe ki wọn ba oun fọwọ si i. Lẹyin oṣu kẹfa to ti yan an bii olori EFCC niyẹn o. Amọ nigba ti awọn aṣofin yẹ iwe oriṣiiriṣii wo nipa Magu yii, wọn lọrọ ẹ ko daa, iwa buruku wa lọwọ ẹ. Ileeeṣe DSS, awọn ọtẹlẹmuyẹ to jẹ tijọba apapọ naa ni wọn kọwe sawọn aṣofin bẹẹ. Ijọba apapọ lo yan Magu, ileeṣẹ to n ṣewadii awọn ọdaran fun ijọba apapọ naa lo sọ pe ẹni ti Buhari fẹe mu yii, ọdaran ni. Bo ba jẹ nibi ti ijọba to lojuti wa, to si jẹ loootọ ni Buhari mọ ohun to n lọ, lẹsẹkẹsẹ ni wọn yoo yọ iru ẹni bẹẹ nipo. Ṣugbọn nitori pe ọwọ Kyari ni agbara wa, to jẹ oun naa lo wa lẹyin Magu, niṣe ni wọn ni Buhari ti sọ pe ko maa ṣe iṣẹ ẹ lọ.

Nigba ti ariwo tun pọ pe ki wọn yọ ọkunrin yii, wiwa nibi to wa yẹn ko ba ofin mu, kaka ki Buhari yọ ọ, o tun fi orukọ ẹ ranṣẹ si awọn aṣofin yii kan naa lọjọ kejilelogun, oṣu kin-in-ni, ọdun 2017, awọn aṣofin yii tun lawọn ko le fọwọ si orukọ ẹ nitori awọn DSS ti sọ pe ọdaran ni. Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹta, ọdun 2017, ni wọn ti kọwe bẹẹ si Buhari o, latigba naa si ni Magu ti n ṣe iṣẹ ti ko bofin mu yii lọ. Koda bi ko ba jẹ Kyari ku ni, wọn ti tun ṣeto lati fi orukọ ẹ ranṣe sawọn aṣofin tuntun yii ki wọn le fọwọ si i fun wọn. Ẹ waa wo Magu naa to n dẹru ba igba, to n dẹru ba awo, Magu ti Kyari n lo lati ki ori gbogbo oloṣelu sabẹ, Magu ti awọn to yi Buhari ka n lo lati fi dẹru ba Buhari funra ẹ, ẹ wo iye owo ti wọn n ṣẹ mọ ọn lọwọ, ẹ wo aduru ohun toun nikan ti ṣe. Buhari wa laye ko ku, oun si ni olori ijọba. O yẹ ka beere lọwo ẹ pe nibo lo wa ti gbogbo eleyii fi n ṣẹlẹ! Ni mo ṣe sọ fun yin pe ootọ ni wọn ni ete oṣelu, laakaye lati ṣejọba dadaa ko si lori wọn.

Aburu to ba Naijiria lati inu oṣu kin-in-ni, ọdun 1950 niyi, nigba ti wọn ṣepade, ti awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa taku pe afi ki wọn da Naijiria si meji, ki awọn mu apa kan, ki Yoruba ati Ibo maa ko apa kan to ku lọ.  Awọn ti wọn ṣiṣẹ lori ofin yii tẹlẹ ti fọwọ si i pe ile-igbimọ aṣofin ti wọn yoo ni ni Naijiria yii, awọn eeyan mẹrinlelaaadọrin (74) lo maa wa nibẹ. Ilẹ Ibo yoo mu eeyan mejilelogun wa; ilẹ Yoruba naa aa mu eeyan mejilelogun wa; ilẹ Hausa yoo si mu ọgbọn eeyan wa. Ṣugbọn nigba ti wọn depade Ibadan yii, awọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa lawọn ko ni i gba ni tawọn. Alavan Ikoku, ọkan ninu awọn aṣoju lati ilẹ Ibo ni abadofin lati fun awọn Hausa ni ijokoo ọgbọn yii ti daa to, bi wọn ba fẹẹ fi ẹmi imoore han; bẹẹ ni Arthur Prest, ọkan ninu awọn ti wọn n ṣoju West lati apa ilẹ Ibinni ni ko tiẹ yẹ ki awọn aṣoju ilẹ Hausa yii sọ ọrọ naa di ariyanjiyan rara.

Tafawa Balewa lo kọkọ sọrọ lọdọ wọn, ohun to si wi ni pe awọn eeyan awọn nile ko ni i gba ki awọn mu ohun mi-in wa sile ju idaji ijokoo nile igbimọ aṣofin Naijiria lọ. Muhammaadu Wali lati Borno ni ohun gbogbo loun tilẹ le gba, ṣugbọn pe ki awọn ma gba idaji ijokoo nilẹ Hausa yẹn, oun ko le fọwọ si i. Bẹe Wali yii wa ninu awọn ti wọn gbe abadofin ti wọn n jiroro le lori yii kalẹ o. Ẹẹmaya Borno naa sọ pe ni gbogbo aye ti oun ti n gbọ itan wọn, bi adugbo kan ba ṣe pọ to ni aṣoju to maa wa lati ibẹ ṣe maa pọ to. Charles Onyema toun wa lati ilẹ Ibo tilẹ ni, ni toun o, ko si idi kan ti wọn fi gbọdo fun ilẹ Hausa ni ijokoo ọgbọn, ti ilẹ Ibo ati ilẹ Yoruba yoo waa ni ijokoo mejilelogun mejilelogun pere. O ni ko yẹ ki adugbo kan ni aṣoju ju adugbo keji lọ, ohun to dara ju niyẹn, oun naa loun yoo si fara mọ. Ewo ni ti ki ilẹ Hausa ni aṣoju ju awọn to ku lọ!

Ọọni Adesọji Aderẹmi mu iyatọ ba ọrọ yii ṣaa o. Kabiyesi ki awọn igbimọ to ṣiṣẹ lori abadofin naa pe wọn ku iṣẹ gidigidi, ṣugbọn o fi kun ọrọ rẹ pe nitori ki ajọṣepọ to dara le wa, awọn aṣoju lati ilẹ Yoruba, iyẹn West, yoo fara mọ ohun ti awọn aṣoju lati ilẹ Hausa yii n fẹ. Ọba Akran lati Badagry ni ohun to n fa wahala yii ko ju pe iye awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin ti wọn n sọ yii ti kere ju ni, ki awọn kuku fi kun iye wọn, ohun ti yoo dara ju niyẹn. Ṣugbọn ni ti awọn aṣoju lati ilẹ Ibo, wọn ni ko si ohun tawọn Hausa yii le wi, wọn ko ni i ni ju ijokoo ọgbọn lọ nile-igbimọ aṣofin naa, iyẹn ti to wọn. Ọkan ninu awọn aṣoju lati ilẹ Ibo yii, Ernest Egbuna, ni ohun tawọn eeyan lati ilẹ Hausa wọnyi n beere fun ko mọgbọn dani, bẹẹ ni ko sẹni ti yoo gba iru ẹ. O ni bawo ni agbegbe to ku yoo ṣe jẹ mejilelogun mejilelogun, ti ilẹ Hausa nikan yoo waa jẹ ọgbọn.

Egbuna ni awọn Hausa yii mọ pe ohun tawọn n beere fun ko daa, awọn eeyan kan ti wọn si fẹ ki ipade naa daru, ti wọn ko fẹ ki wọn ri kinni kan mu jade nibẹ ni wọn n ti awọn aṣoju lati ilẹ Hausa yii. Ohun ti Egbuna n sọ ni pe awọn oyinbo ni wọn wa lẹyin awọn Hausa yii, awọn ni wọn n lo wọn lati sọ ohun ti wọn n sọ, ti wọn si n beere ohun ti ko ni ṣee ṣe. Oyinbo ko fẹẹ gbejọba silẹ, to ba waa di karangida pe ki wọn gbejọba silẹ, wọn ko fẹẹ gbejọba le awọn to lọgbọn bii tiwọn lọwọ, awọn ti ko lọgbọn eto ijọba kan lori ni wọn fẹẹ fi tipatipa gbe kinni naa fun, ki wọn le maa ri wọn kọnturoolu ni. Nibi yii ni Ọba Zaria igba naa, Jafaaaru Dan Isiyaku, ti binu rangbọndan. Boun ṣe binu ni Ọba Katsina, Usman Nagogo, tẹle e. Wọn ni asiko ti Naijiria maa pin si wẹwẹ lawọn de yii, pe awọn Hausa ko ni i ṣe Naijiria mọ. Wọn n halẹ mọ awọn eeyan wa, awọn ko si mọ; wọn fẹẹ gba Naijiria lọwọ wọn, wọn ro pe awọn Hausa yii ko mọ ohun ti wọn n ṣe.         

Ta ni Ọba Zaria yii, ta si n Ọba Katsina, bawo ni tiwọn ti jẹ gan-an? N oo ṣalaye ẹ lọsẹ to n bọ.

Leave a Reply