Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (14)

Awọn ọrọ ti mo n sọ wọnyi, mo fẹ ka ṣe akọsilẹ ati afọkansi wọn daradara. Alaye ti mo n ṣe wọnyi, ka fi le mọ ibi ti nnkan ti wọ wa ni. Bi a ba mọ ibi to ti wọ wa, a oo le mọ ohun to yẹ ni ṣiṣe. Ṣe ẹ ri i lati 1960 ti ijọba Naijiria ti bọ sọwọ awọn eeyan wa lawọn baba wa gbogbo lati ilẹ Yoruba ti ri aṣiṣe wọn. Nigba ti yoo fi di ọdun 1961 si 1962, aṣiṣe naa ti foju han debii pe wọn kabaamọ ohun ti wọn ṣe nibi ipade Ibadan ọdun 1950 ti mo sọrẹ ẹ fun yin. Wọn ri i pe awọn Sardauna ti gba Naijiria lọwọ awọn, wọn ti fi ara wọn ati awọn ọmọ tiwọn si ipo aṣaaju ni Naijiria, yoo ṣoro gan-an lọjọ iwaju lati gba a pada lọwọ wọn. Bo ba jẹ nigba ti tawọn ọba ilẹ Hausa yii n halẹ pe awọn fẹ ki Naijiria pin lawọn eeyan tiwa naa ni bi Naijiria ba fẹẹ pin ko pin ni, ọrọ naa ko le bajẹ mọ wa lọwọ to bẹẹ. Ṣugbọn nnkan ti bajẹ, ko too waa di 1962 ti wọn n mura atunṣe.

Igba yẹn ni wọn ti mura pe eto ikaniyan ti awọn ba tun ṣe, awọn yoo ri i pe ko si aaye magomago ninu ẹ, wọn fẹẹ ṣọ awọn Sardauna lọwọ, ki wọn ṣọ wọn lẹsẹ, lati ri i pe wọn ko tun lu Yoruba ni jibiti lẹẹkan yii, wọn fẹ ki kaluku mọ iye to jẹ gan-an. Igba tawọn Balewa tiẹ sọ pe awọn gba oyinbo kan ko waa ṣeto ikaniyan yii, idunnu lo jẹ fawọn eeyan tiwa nilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, wọn mọ pe ko ni i si eru ninu ohun ti oyinbo ba dari fun wọn. Ohun to gbe J. J. Warren delẹ wa ree, oun loyinbo to ba wa ṣeto ikaniyan ni 1962. Awọn Sardauna ti wọn fẹẹ gba agbara lọwọ wọn naa o sun, ṣe wọn mọ pe agbara kan naa ti awọn ni ni ariwo pe awọn lawọn pọ ju ni Naijiria, bi agbara yẹn ba si ti bọ, nnkan ṣe wọn niyẹn. Ọgbọn ti wọn da ni lati ri i pe ẹnu awọn eeyan naa ko ko, wọn wa ọna lati tu wọn ka.

Azikiwe ti wa ninu ijọba, wọn ti gbe aparutu agbara kan le e lọwọ. Nitori ẹ, ki i ri ohun to buru rara ninu ohun tawọn Balewa tabi Sardauna ba ṣe. Ẹyin wọn lo wa. Awolọwọ nikan ni iṣoro wọn. Awolọwọ pẹlu ẹgbẹ Ọlọpẹ ẹ. Awọn eeyan yii kuku mọ pe aburu lawọn ṣe fun wa, wọn si mọ pe aṣiri ọrọ naa fẹẹ tu. Lo ṣe jẹ bi wọn ti mọ pe eto ikaniyan n bọ ni 1962 lawọn naa ti bẹrẹ eto lati da ẹgbẹ Awolọwọ ru, tabi ti wọn fi le pa Awolọwọ funra ẹ saye, ti o fi ni i lagbara lati di wọn lọwọ ohunkohun ti wọn ba n ṣe. Akintọla ni wọn ri lo lati fi ba tiwa jẹ. Lojiji ni Sardauna bẹrẹ si i fa oju ẹ mọra. O n paara Ibadan, o n sọ pe oun waa ki i. Asiko yii naa ni Akintọla bẹrẹ si i ta Awolọwọ lẹnu, to ni Awolọwọ ti lo saa tiẹ, ko jẹ ki oun naa lo saa toun.

Nigba to fi maa di ibẹrẹ ọdun 1962, Sardauna ti mu Akintọla, o ti kọ ẹyin oun ati Awolọwọ sira wọn. Akintọla ko gba Awolọwọ bii ọga mọ. Ohun to n wa yii ru bo o loju ti ko fi mọ pe Sardauna n tan oun ni. Ohun to fa a niyẹn to jẹ titi ti wọn fi bẹrẹ sẹnsọ 1962 yii, ti wọn si pari ẹ, ninu hilahilo ni ilẹ Yoruba wa, ko sẹni to roju ara wọn. Ẹgbẹ Action Group ṣeto ipade gbogbogboo si Jos ninu oṣu keji, kaka ki Akintọla to jẹ olori ijọba Western Region wa nipade, o  wa n’Ibadan to n gba Sardauna lalejo. Sardauna mọ pe ẹgbẹ awọn Awolọwọ nipade o, o si mọ pe ko si ẹni ti wọn bi daadaa bẹẹ ninu awọn ọmọlẹyin oun to jẹ ṣe bẹẹ soun nibi ipade ẹgbẹ tawọn.

Ṣugbọn nitori pe Akintọla n wa agbara, oun o fura si gbogbo eyi, o ro pe Sardauna fẹẹ gbeja oun ni. Ibinu ọrọ yii lawọn ọmọ ẹgbẹ fi yọ kuro ninu ẹgbẹ Action Group ibi ipade Jos yii. Ni gbogbo igba ti ija yii wa n gbona gan-an ninu oṣu karun-un, 1962, eto ikaniyan n lọ lọwọ ni Naijiria, bẹẹ ijọba Western Region ko raaye dari awọn eeyan tiẹ, ija buruku yii o jẹ. Ọjọ kẹtala, oṣu karun-un, 1962, ni wọn ti bẹrẹ eto naa, gbogbo igba ti ijọba Balewa si n fi ipa gba ijọba Western Region lọwọ ẹgbẹ AG, ti wọn fi Moses Adekoyejọ Majẹkodunmi ṣe olori ijọba ibẹ, wọn ṣi n ṣeto ikaniyan yii lọwọ. Ta lo roju sẹnsọ nilẹ Yoruba! Ohun ti awọn Sardauna gbe kalẹ, ti Akintọla ati awọn ọmọ Yoruba to ti i lẹyin ko mọ niyẹn.

J. J. Warren kuku ba iṣẹ naa jalẹ, ṣugbọn oun funra ẹ ri magomago tawọn Hausa yii ṣe, atawọn Ibo naa. Pẹlu ẹ naa, nigba ti wọn ka awọn eeyan tan, apapọ ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo ju ilẹ Hausa lọ. Awọn eeyan miliọnu mejilelogun ni wọn ri ka nilẹ Hausa, mẹtalelogun miliọnu ni apapọ ilẹ Ibo ati Yoruba. Niṣe lawọn Balewa yari. Warren to ṣeto sẹnsọ ni ilẹ Ibo ati ilẹ Hausa ni ojooro wa, awọn si le ṣe atunṣe diẹdiẹ to wa nibẹ, ti gbogbo nnkan si maa ri bo ṣe yẹ ko ri. Ibẹru leleyii fun Sardauna atawọn eeyan ẹ, wọn ro pe Warren fẹẹ tọwọ bọ nnkan loju fawọn ni. Wọn mọ pe awọn ibi kan wa ti wọn o kaayan nilẹ Hausa yii, to jẹ wọn kan bu iye kan fawọn to ṣeto ni; aṣiri ẹ ti tu si Warren lọwọ, atunṣe to fẹẹ ṣe niyẹn.

Waziri Ibrahim ni minista fun eto idagbasoke ilu nigba naa, abẹ ẹ ni eto ikaniyan yii wa. Wọn ni ki Warren fi bi wọn ṣe kaayan nilẹ Hausa silẹ, ti ilẹ Ibo nikan ni ko tun ṣe, oyinbo ni iyẹn o ṣee ṣe. O ni ibi mẹtẹẹta lawọn gbọdọ ṣe, nitori wahala to n wa nilẹ Yoruba ko jẹ ki awọn eeyan kọbiara si eto ikaniyan ọhun, wọn ko si ri ọpọ eeyan ka nibẹ. Waziri beere lọwọ Warren pe ṣe ti wọn ba tun eto naa ṣe, njẹ o ṣee ṣe ki ilẹ Hausa pọ ju apapọ ilẹ Yoruba ati Ibo lọ. Warren ni pẹlu ohun ti oun ti ri yii, bi awọn ba tun eto naa ṣe, awọn eeyan ilẹ Hausa maa dinku gan-an ni, nitori wọn ko to iye ti wọn kọ siwee waa foun. Waziri gbe ọrọ pada fawọn Balewa, Sardauna ni iyẹn o le ṣee ṣe, Hausa gbọdọ pọ ju Yoruba ati Ibo lọ, bi bẹẹ kọ, iya le jẹ awọn.

Ni wọn ba sọ fun Warrren pe o gbọdọ tun eto naa ṣe ti yoo fi jẹ Hausa lo pọ ju, lọkunrin yii ba ni oun o le ṣe bẹẹ. Nipari oṣu kin-in-ni, 1963, Waziri ba gbe iwe lọ si ile-igbimọ aṣofin pe ki wọn jẹ ki awọn le Warren lọ, nitori ko ṣe iṣẹ ẹ daadaa. Awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCNC lawọn o gba, awọn ti AG naa lawọn o fẹ, ni wọn ba binu jade. Awọn aṣofin ilẹ Hausa to jẹ awọn ni wọn pọ ju jokoo, ni wọn ba fọwọ si i pe ki wọn le Warren lọ. Nigba ti wọn le Warren lọ, Balewa gba iṣẹ naa, ni wọn ba tun kaayan ni 1963. Nigba ti wọn ka wọn tan, to jọ pe ko tun to iye ti wọn fẹ, ijọba Balewa ṣe ayipada nla kan. Wọn fi miliọnu mejọ  ataabọ kun iye awọn eeyan ti wọn wa nilẹ Hausa.

Gbogbo ohun ti mo n sọ yii, Akintọla mọ daadaa pe magomago ni, nitori nigbẹyin, miliọnu marundinlọgọta ni wọn pe gbogbo Naijiria, ilẹ Hausa ni awọn ni miliọnu ọgbọn o le, wọn ko eyi to ku fun ilẹ Yoruba ati Ibo.  Michael Okpara, olori ijọba ilẹ Ibo naa mọ o.  Ṣugbọn ni gbogbo igba ti Okpara n lọ si kootu, to n fa wahala lori ọrọ sẹnsọ yii, to n so pe ko daa, irọ ati iyanjẹ ni, Akintọla dakẹ jẹẹ, ko le wi kinni kan, nitori o mọ pe agbara Sardauna loun fi wa nile ijọba, oun ko si gbọdọ ṣe ohun kan ti yoo lodi si ohun ti Sardauna ba fẹ. Bo ṣe jẹ ọna kan ṣoṣo ti wọn iba fi bọ ninu ajaga to wa lọrun wa titi doni yii, Akintọla ati awọn ọmọ Yoruba ẹyin ẹ bii Fani-Kayọde, Ayọ Roṣiji, Richard Akinjide, Adisa Akinloye, Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi, ati awọn mi-in bẹẹ tun ba a jẹ niyẹn. Wahala ti eleyii tun mu dani, n oo maa tẹ siwaju lori ẹ lọsẹ to n bọ.  

Leave a Reply