Eyi ni bawọn aṣaaju Hausa-Fulani ṣe ba Naijiria yii jẹ (16)

Mo ti mẹnuba ọrọ yii lẹẹkan, ṣugbọn bi a ba tun ṣe alaye ẹ nibi ta a de yii, ko ṣe nnkan kan. Awọn ọna ti awọn Hausa-Fulani gba lati fi mu awa to ku ni Naijiria, ti wọn si sọ wa di bọibọi wọn, ṣugbọn to jẹ nigbẹyin, gbogbo ohun to dara ni Naijiria ni wọn pada bajẹ pata. Mo ti ṣalaye fun yin bi wọn ti mu ipo oṣelu, nitori wọn sọ pe awọn ni idaji Naijiria, ti wọn si fi gbogbo agbara ja lati ri i pe ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ pin ni Naijiria, titi dori awọn ọmọ ile-igbimọ aṣofin, awọn ni wọn yoo ko idaji. Nigba ti wọn ti le mu ipo oṣelu bẹẹ, ibi ti wọn tun dojukọ ni ileeṣẹ ologun ati awọn ọmọ ogun Naijiria, wọn nigbagbọ pe bi awọn ba ti ni eleyii, ohun gbogbo bo si awọn lọwọ pata niyẹn. N ni wọn ba bẹrẹ ète buruku, nigbẹyin gbẹyin, wọn ri kinni naa mu, oun naa lo si ba wa debi ti a de loni-in. Bi wọn ṣe ṣe e niyi:

Ko too di ọdun 1960, ati ni ibẹrẹ 1960 ti Naijiria gba ominira, awọn Yoruba tiwa ati Ibo ni wọn ni awọn ọga to pọ ju lọ ninu iṣẹ ṣọja. Awọn ọga akọkọ ti wọn wa nigba yẹn ni Aguiyi Ironsi, Samuel Ademulẹgun, Babafẹmi Ogundipẹ, Ralph Ṣodẹinde ati Robert Adeyinka Adebayọ (awọn yii ti n lọ si ipo birigedia ati Mejọ-Jẹnẹra). Awọn ti wọn tẹ le wọn ni awọn ara Kanuri, bo tilẹ jẹ pe awọn jinna si awọn ti wọn wa niwaju yii diẹ, sibẹ awọn naa ni wọn tẹle wọn. Awọn yii ni Zakariya Maimalari, Umar Lawan ati Kur Muhammed (awọn yii ṣẹṣẹ n lọ si ipo konẹẹli ninu ṣọja nigba yẹn ni). Awọn ti wọn tẹle awọn yii lawọn Lẹfutẹnanti-Konẹẹli bii Emeka Ojukwu, David Ejoor, Yakubu Gowon, George Kurubo, ati awọn mi-in bẹẹ. Lẹyin eyi lo waa kan awọn mejọ (Major), awọn yii si ni alagbara.

Ninu awọn mejọ bii mẹẹẹdọgbọn to wa lakọọkọ, mẹẹẹdogun ni ti awọn Ibo, ti Yoruba jẹ mẹjọ, ti ti awọn Hausa si jẹ meji pere. Iyẹn ni pe awọn Ibo lo ni ọga to pọ ju lọ ninu iṣẹ ṣọja ko too di pe Naijiria gba ominira. Igba ti mo n sọ yii, awọn oyinbo lo n ṣe olori ṣọja, wọn o ti i gbe ipo olori to ga ju lọ fawọn ọmọ tiwa. Ṣugbon bi a ti gbominira, to si jẹ awọn Hausa ni olori ijọba, eto ti wọn bẹrẹ ni bi wọn yoo ṣe yi nnkan pada, to fi jẹ awọn Hausa yii ni yoo pada di ọga ninu iṣẹ ologun, bo tilẹ jẹ pe iriri ati imọ wọn ko to ti awọn Yoruba ati Ibo ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ, ti wọn si kawe juwọn lọ. Bi a ti gba ominira, ti akoso awọn ologun bọ sabẹ awọn ti wọn n ṣejọba yii, ọna mẹta ọtọọtọ ni wọn gba lati ba gbogbo eto to wa nilẹ jẹ, ati lati ṣe e bi awọn ọmọ ilẹ Hausa naa yoo ṣe pọ ninu iṣẹ ṣọja yii.

Muhammadu Ribadu ni minisita fun eto aabo ilẹ wa nigba naa, abẹ rẹ si ni eto ologun gbogbo wa, ohun to ba sọ lori ọrọ awọn ṣọja ni abẹ ge. Ribadu ti mo n wi yii, igbakeji Sardauna ni ninu ẹgbẹ oṣelu wọn, ka ṣaa sọ pe oun gan-an laṣoju Sarduan l’Ekoo. Ki i ka iwe iroyin, ki i gbọ redio tabi ko feti si iroyin kan, kewu ati tira lo n ka, ohun ti oun ati Sardauna ba si ti fẹnu ẹ jona nikan lo n ṣe, tabi ohun to ba wa si i lọkan. Nigba  ti wọn ti ṣeto pe wọn maa gba ipo awọn ọga ṣọja kuro lọwọ awọn eeyan tiwa, ohun ti Ribadu dojukọ niyẹn, ọna mẹta ti wọn si la kalẹ naa lo lo lati ṣe nnkan ti wọn fẹ. Akọkọ ni pe wọn faake kọri pe ki i ṣe iwe nikan ni wọn yoo maa fi gbaayan sinu iṣẹ ṣọja mọ, bi eto oṣelu ṣe wa ni wọn aa maa lo.

Eyi ni pe nigba tawọn ti wọn wa lati ilẹ Hausa ti le ko idaji ninu awọn aṣofin Naijiria, bi wọn ba fẹẹ gbaayan sinu iṣẹ ologun Naijiria naa, idaji lawọn gbọdọ ko. Iyẹn ni pe idaji awọn yoowu ti wọn ba fẹẹ gba sinu iṣẹ ṣọja, ilẹ Hausa ni wọn gbọdọ ti wa. Wọn fa ọrọ yii lọ, wọn fa a bọ, wọn pe orukọ eto jibiti ati irẹjẹ yii ni kota (Quota system), nigba to si ti jẹ awọn ni wọn pọ ju nileegbimọ aṣofin, kia ni wọn sọ ọrọ naa dofin. Ofin naa wa titi doni pe ti wọn ba fẹẹ gba ọgọrun-un ọmọ si ṣọja, ẹyin naa kuku mọ, aadọta lo maa wa lati ilẹ Hausa. Wọn tiẹ ti sun un siwaju debii pe o le jẹ ọgọta tabi aadọrin ni wọn maa rọ sinu iṣẹ naa, ti wọn aa fun Yoruba ati Ibo ni diẹ, nitori isọlẹnu lasan. Kota yii ni ibẹrẹ eto bawọn araabi yii ṣe ba iṣẹ ologun Naijiria jẹ titi di bi a ti n sọ yii.

Ohun keji ti wọn ṣe ni lati din eto bi wọn ṣe maa gba wọn siṣẹ naa ku. Tẹlẹ, bi ẹnikẹni ba fẹẹ wọ iṣẹ ṣọja ti yoo di ọga nibẹ, yoo ti ka iwe mẹwaa rẹ jade, yoo si paasi daadaa ninu gbogbo idanwo to ba ṣe. Tẹlẹtẹlẹ, bi ọmọ kan ba yege ninu iṣẹ yii, o ni iye maaki to gbọdọ gba ninu idanwo to ba ṣe, ṣaaṣa awọn ọmọ Hausa yii ni wọn le de iru maaki naa, koda bo ti le wu ki wọn kọ wọn to. Meji ni iṣẹ to maa n ja wọn kulẹ ju lọ, iyẹn naa ni ede oyinbo ati iṣẹ iṣiro. Ẹnikẹni ti ko ba si ti gba to ọgọta ninu ọgọrun-un, iru ẹni bẹẹ ko ṣee mu lọ sinu iṣẹ ologun, awọn oyinbo ti wọn n dari wọn tẹlẹ ko tilẹ ni i jẹ ko wọle. Ṣugbọn nigba to kan awọn araabi yii, to jẹ Hausa ni minisita eto aabo, to jẹ akọwe agba fun iṣẹ ologun, Hausa naa ni, to jẹ minisita kekere fun iṣẹ ṣọja, Hausa naa ni, kia lawọn yi kinni naa pada, wọn si gbe maaki tiwọn jade.

Wọn ni wọn o le fi maaki ọmọ ilẹ Hausa we ti awọn ọmọ ilẹ Yoruba ati ilẹ Ibo, pe ti ọmọ Hausa ba ti le gba maaki bii ogoji tabi marundinlogoji, ko sohun to de ti o le di ọọfisa ninu ṣọja, eyi ti ko ba ti i mọ, aa maa ka a bo ba de ile-ẹkọ awọn ologun. Bo ṣe di pe awon ọmọ ilẹ  Hausa ti wọn o le gboorun ipo ọọfisa ninu iṣẹ ṣọja laelae bẹrẹ si i di ọmọleewe ologun, ti wọn si n di ọọfisa ti wọn ba jade, lai mọ kinni kan. Oun la n ri loni-in yii, ẹyin naa kuku n ri i. Ọpọ awọn ọga ṣọja lati ilẹ Hausa, bi wọn ba sọ ede oyinbo bayii, eeyan yoo fẹrẹ sa lọ. Wọn ko fi ṣeka, nigba ti wọn o gbọ. Bẹẹ o yẹ ki wọn gbọ ki wọn too de iru ipo ti wọn wa, ṣugbọn eto irẹjẹ tawọn baba wọn ti ṣe silẹ fun wọn ko jẹ, ko sẹni to laya ninu awọn ti wọn n ṣejọba lati yi kinni naa pada, titi dori ẹgbọn tiwa, Bọọda Ṣẹgun, toun naa mọ pe kinni ọhun o daa.

Ọna kẹta tawọn aṣaaju Hausa yii fi bẹrẹ si i ko awọn ọmọ wọn sinu iṣẹ ṣọja, ti wọn si n fi wọn ṣe ọga ni lati maa lọ sileewe girama kaakiri ilẹ Hausa, ki wọn si ni kawọn ọmọ ibẹ maa mura lati di ṣọja, bi wọn ti maa n ṣe kinni naa aa ya yin lẹnu bẹ ẹ ba gbọ. Nigba ti Yakubu Gowon ṣẹṣẹ jade nileewe awọn ṣọja, wọn maa n mu un lẹyin lọ sawọn ileewe yii, wọn aa ni ki wọn wo ohun tawọn naa le da bi wọn ba wọ iṣẹ sọja. Ni bii 1961 yẹn, nigba ti wọn fẹẹ gba awọn ọmọ si ṣọja, Tanko Galadima to jẹ minisita abẹle fun iṣẹ ṣọja nigba naa mu Gowon dani, wọn lọ si Government College, ni Bida, nibẹ ni wọn ti n sọ fawọn ọmọọleewe ibẹ pe ki wọn waa wọ iṣẹ sọja, ki wọn le da bii Gowon to ba ya. Awọn ti wọn ba nileewe nijọ naa, lara wọn ni Ibrahim Babangida, AbdulSalami Abubakar, Maman Vatsa, Garba Duba, Gado Nasko, Sani Bello, Muhammed Magoro, atawọn mi-in.

Gbogbo awọn ti mo darukọ yii ni wọn pada waa di ọga ninu iṣẹ ologun, ti ninu wọn si di olori orilẹ-ede. Ohun ti ko jẹ ki awọn mi-in ninu wọn ni sabukeeti iwe mẹwaa ree, nitori wọn tẹle awọn ti wọn waa gba wọn yii lọ. Loootọ ni wọn ti fẹẹ jade, ṣugbọn wọn ko ṣedanwo oniwee mẹwaa jade. Bi nnkan ṣe buru to niyẹn. Bawọn eeyan yii ṣe fi ọbọ lọ wa to niyẹn. Bi awọn ti wọn lọ si Government College, Bida yii, ti n ṣe tiwọn, bẹẹ lawọn mi-in mu Zak Maimalari pe ko waa lọọ ba wọn sọrọ ni Barewa College, lara awọn ti wọn gbọ ọrọ lẹnu oun ni Muritala Muhammed. Bi wọn ba ti gbọ ọrọ bayii, wọn n lọ sinu iṣẹ ṣọja niyẹn. Bayii lawọn eeyan yii bẹrẹ si i rọ awọn ọmọ wọn sinu ṣọja lai kun oju oṣuwọn:  wọn mọwe wọn o mọwe, wọn paasi wọn o paasi, nibi ti ọrọ wa ti n dojuru si i niyẹn.

E tun pade mi lọsẹ to n bọ si i

Leave a Reply