Eyi ni bawọn agbebọn ṣe fẹmi eeyan mọkanla ṣofo laarin ọjọ meji

Faith Adebọla

Igbe ẹkun ati aro lo gbode kan nipinlẹ Zamfara lasiko yii, paapaa nijọba ibilẹ Gusau, to wa lolu ilu ipinlẹ naa, eeyan mẹfa lawọn janduku agbebọn pa bii adiẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ọjọ keji, Tusidee, ni wọn tun ṣeku pa awọn ọlọpaa meje, yatọ si ọgọọrọ araalu ti wọn ji gbe.

Iṣẹlẹ ti ọjọ Aje waye ni ilu Rijiya, nijọba ibilẹ Gusau, lafẹmọju ọjọ naa.

Olugbe ilu ọhun kan, Mustapha Ibrahim, sọ fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN) pe, “Bo ṣe ku diẹ kilẹ mọ, tawọn Musulumi n lọọ kirun fẹẹrẹ lawọn agbebọn naa ṣadeede ya bo ilu wa, wọn bẹrẹ si i yinbọn gbau gbau si ẹnikẹni ti wọn ba ri, mo kọkọ ro pe wọn n yinbọn naa lati da jinnijinni bo awọn eeyan ni, ṣugbọn nigbẹyin, oku eeyan mẹfa la ṣa jọ, wọn si ji awọn obinrin atawọn ọmọde kan wọgbo, wọn sa lọ.”

Ibrahim tun sọ pe lasiko akọlu naa, awọn agbebọn ọhun n ya ẹnu ọna ile kan si omi-in, wọn n fipa gba ounjẹ ti wọn ba ri, wọn gba agbado, irẹsi, elubọ, jero, ọka baba atawọn nnkan isebẹ mi-in, lẹyin naa ni wọn n ji awọn onile naa gbe.

O lawọn o ti i le sọ pato iye ẹni ti wọn ji gbe, tori awọn agbebọn naa sọ awọn ile kan dahoro pata.

Ṣugbọn atẹjade kan latọwọ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara lọjọ Wẹsidee yii fidi iṣẹlẹ to waye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, mulẹ, ASP Mohammed Shehu sọ pe awọn agbebọn naa lọọ lugọ de awọn ọlọpaa ti wọn n ṣẹri pada lati ibi ti wọn ti lọọ ṣe patiroolu pẹlu ọkọ ọlọpaa ti wọn gbe lọ ni, ọna Tofa si Magami ni ilu Gusau, ni wọn ti jade si wọn lojiji, wọn ṣina ibọn fun wọn, wọn si pa meje ninu awọn ọlọpaa naa bii ẹran.

Lẹyin ti wọn pa wọn tan, wọn lawọn ọdaju afẹmiṣofo ẹda naa ko ibọn ati nnkan ija awọn ọlọpaa naa, wọn tun dana sun ọkọ awọn ọlọpaa naa, wọn si sun oku wọn pẹlu, bo tilẹ jẹ pe awọn diẹ ninu awọn ọlọpaa naa sa mọ wọn lọwọ pẹlu ọgbẹ ibọn.

Shehu ni awọn janduku to ya bo awọn ọlọpaa yii pọ bii baba eṣua ni, oun lo jẹ ki wọn le bori awọn agbofinro naa.

O lawọn ti ko oku awọn ọlọpaa naa lọọ si mọsuari ọsibitu Yarima Makura Specialist Hospital, to wa ni Gusau, fun ayẹwo.

Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa, IG Alkali Usman, ti fi ẹdun ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ yii, o ni o kọ oun lominu bawọn janduku agbebọn naa ṣe n gbokun si i ninu iwa buruku wọn, ṣugbọn o sọrọ idaniloju pe bo ti wu ki wọn ṣe to, ago lo maa de adiẹ wọn gbẹyin, awọn agbofinro yoo kapa wọn dandan ni.

Atẹjade kan ti Alukoro agba fun ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba, fi lede lorukọ ọga rẹ lọjọ Wẹsidee sọ pe ọgbẹ ọkan lo jẹ fun ọga agba patapata awọn ọlọpaa pe awọn ọmọọṣẹ rẹ n bogun rin.

O lawọn ṣẹṣẹ gba awọn irinṣẹ tuntun kan lati ilu oyinbo, to tubọ maa pese aabo to peye fawọn ọlọpaa lẹnu iṣẹ wọn, awọn si maa tete pin awọn irinṣẹ ọhun kaakiri.

Lara awọn nnkan eelo ati irinṣẹ naa ni akoto, ẹwu ati bata akọtami, atawọn nnkan ija oloro ti wọn maa fi dana ya awọn olubi atawọn ọdaran to n fẹmi araalu ṣofo.

Leave a Reply