Eyi ni bawọn Fulani ṣe tun ya wọnu oko oloko n’Ibadan, eeyan mẹta ni wọn ji gbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

O kere tan, eeyan mẹta lawọn Fulani ajinigbe tun ji gbe n’Ibadan nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yìí nikan ṣoṣo.

Inu oko tọkọ-tiyawo kan, to wa l’Abule Alabameji, laduugbo Sanyo, n’Ibadan, lawọn ẹruuku ọhun kọkọ ya wọ tibọntibọn, ti wọn si palẹ awọn mejeeji mọ bii igba ti aṣa ba gbe oromọdiẹ lọ.

Ko to wakati kan lẹyin naa lawọn ikọ ajinigbe mi-in tun lọọ ji ọkunrin kan gbe ninu ọkọ tiẹ naa laduugbo Soka, n’Ibadan, nibi ti ko jinna pupọ si abule ti wọn ti ji awọn ololufẹ meji gbe ṣaaju.

Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bíi ọsẹ meji sẹyin ni won ji oṣiṣẹ ileefowopamọ kan ati agbẹ kan gbe n’Ibadan yii kan naa.

Miliọnu marun-un naira la gbọ pe wọn san ki awọn ọbayejẹ eeyan naa too tu wọn silẹ ninu igbekun.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe “Awọn ajinigbe ji awọn tọkọ-tiyawo kan gbe ni nnkan bii aago meji ọsan kọja ogun iṣẹju.

“DPO teṣan Sanyo ti lọ sibẹ lati bẹrẹ iwadii lati mu awọn ọdaran naa. Ireti si wa pe laipẹ rara ni iwadii wa yoo seso rere.”

Leave a Reply