Sifu Difẹnsi sọ awọn aṣẹwo mẹẹẹdogun satimọle n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ode ko dun fawọn oloṣo, iyẹn awọn ọdọmọbinrin ti wọn yan iṣẹ aṣẹwo laayo laduugbo Bodija, n’Ibadan, lopin ọsẹ to kọja yii, pẹlu bi mẹẹẹdogun ninu wọn ṣe ti ileetura ti wọn ti n ṣiṣẹ aṣẹwo dero atimọle.

Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, niṣẹlẹ ọhun waye.

Awọn oloṣo wọnyi ni wọn maa n patẹ ara wọn bii iṣu si ẹgbẹ titi lalaalẹ niwaju ileetura kan laduugbo Bodija, n’Ibadan, lati duro de awọn ọkunrin to maa ba wọn laṣepọ, to si maa fun wọn lowo.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn alakooso ileetura ta a forukọ bo laṣiiri ọhun ni wọn pe awọn oṣiṣẹ ajọ eleto aabo ilu, iyẹn Nigerian Security and Civil Defence Corps (NCDC) si wọn, wọn lawọn obinrin ọlọja alẹ wọnyi n ba ọja jẹ fawọn aṣẹwo to forukọ silẹ lọdọ awọn.

Iwadii akoroyin wa fìdí ẹ mulẹ pe awọn oloṣo kan wa ti wọn maa n polowo ara tiwọn kaakiri inu ileetura naa, ti wọn si maa n sanwo fawọn alakooso ibẹ lojoojumọ gẹgẹ bii igba ti oniṣowo ba n sanwo to fi rẹnti ṣọọbu to ti n taja.

Bi awọn to n duro sẹgbẹẹ titi ṣe maa n ri awọn ọkunrin ba wọn dowo pọ, to jẹ pe bi awọn ọkunrin to ba waa ṣe faaji nileetura yii ṣe maa n gbe wọn lawọn alafẹ to n kọja lọ paapaa maa n fi mọto gbe wọn lọ sile tabi ibikibi ti wọn ba ti fẹẹ ba wọn sun.

Gbogbo bi wọn si ṣe n rowo pa to, awọn aṣẹwo wọnyi ki i fun awọn alakooso ileetura naa ninu owo ti wọn ba pa, bo tilẹ jẹ pe iwaju ileetura to gbajumọ laduugbo Bodija yii ni wọn n lo gẹgẹ bii ṣọọbu ti wọn ti n polowo ọja wọn.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, agbẹnusọ fun ajọ NSCDC, Ọgbẹni Oluṣẹgun Oluwọle, sọ pe “awọn olugbe agbegbe ileetura yẹn ni wọn mu ẹsun wa sileeṣẹ wa nipa bi oriṣii iwa ibajẹ bii, ole jija, ariwo pipa loru ati bẹẹ bẹẹ lọ

ṣe maa n waye lagbegbe yẹn.

“Ọpọ igba ni wọn ti ja baagi ati foonu gba mọ awọn eeyan lọwọ nibẹ. Idi niyẹn ta a ṣe lọ sibẹ lati mu awọn to n di alaafia adugbo lọwọ wọnyẹn”.

ALAROYE gbọ pe ẹẹmẹta lawọn agbofinro wọnyi ṣiṣẹ naa nitori lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni wọn bẹrẹ, nigba ti wọn mu mẹjọ ninu awọn ọmọ ori-orin naa.

Lojo kẹta, iyẹn Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ni wọn tun mu eeyan meji si i nigba ti wọn mu awọn marun-un mi-in lalẹ ọjọ Satide.

Gbogbo wọn la gbọ pe wọn ti pada tu silẹ ninu ahamọ bayii lẹyin ti oniwaasu ajọ NSCDC fi ọrọ Ọlọrun gba wọn nimọran atata.

Leave a Reply