Eyi ni beeyan mẹfa ṣe jona ku ninu ijamba ọkọ l’Ode-Aye

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹfa ni wọn jona ku, tawọn ero mi-in si tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Oke Ọla, iyana Ode-Aye, nijọba ibilẹ Okitipupa, lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii.

Ijamba ọkọ yii waye laarin ọkọ bọọsi J5 kan to kun fọfọ fun ọti ogogoro pẹlu bọọsi nla Costal to jẹ tijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ.

Ẹnikan to wa nibi iṣẹlẹ ọhun ṣalaye fun ALAROYE pe nibi ti ọkan ninu awọn ọlọkọ mejeeji tí n gbiyanju ati sare ya eyi to wa niwaju rẹ silẹ lo ti pade ọkọ mi-in toun naa n sare bọ niwaju.

Bi awọn ọkọ mejeeji ṣe fori sọ ara wọn ni ina ti sọ lara wọn, ninu eyi tawọn ero mẹfa jona ku, nigba tawọn ero yooku fara pa.

Awọn ara abúlé kan tó wa nitosi ibi tí ijamba ọkọ naa ti waye la gbọ pe wọn sa gbogbo ipa wọn lati ri ina ọhun pa, ṣugbọn ti ogogoro to wa ninu ọkọ J5 ko jẹ ki eyi ṣee ṣe fun wọn.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, oṣiṣẹ ijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ lawọn to wa ninu ọkọ Coastal naa, ilu Okitipupa ni wọn n lọ láti lọọ ba ọga agba kan nijọba ibilẹ Odigbo ṣe ayẹyẹ.

Diẹ ninu awọn arinrinajo ọhun ni wọn sọ ẹmi wọn nu nigba to ku ibusọ bii meji pere ki wọn fi gunlẹ síbi ti wọn n lọ.

Awọn eeyan to wa nitosi lasiko ti iṣẹlẹ naa waye ni wọn ko awọn to fara pa lọ silẹ-iwosan kan niluu Ọrẹ fun itọju, mọṣuari ọsibitu yii kan naa la gbọ pe wọn ko oku awọn to padanu ẹmi wọn lọ.

Leave a Reply