Eyi ni bi aarẹ ẹgbẹ Rotaract Club ilu Iwo ṣe ku nibi to ti n gba bọọlu

Florence Babaṣọla, Osogbo

Bii ala lọrọ naa ṣi n jẹ loju gbogbo awọn eeyan ilu Iwo, paapaa ju lọ, awọn ọmọ ẹgbẹ Rotaract Club, ko sẹni to gbagbọ pe ẹni ti wọn ri lai ti i pe wakati kan le ṣe bẹẹ dero ọrun alakeji.

Lati ọdun kan sẹyin ni Shuaib Iṣọla ti n ko ẹgbẹ Rotaract ilu Iwo (Rotaract Club of Iwo Community Based) jẹ gẹgẹ bii aarẹ, ọjọ Aiku, Sannde, ijẹta, gan-an lo si ti wa ninu alakalẹ pe yoo gbe ipo fun aarẹ mi-in, ṣugbọn lọjọ naa ni iku wọle, to si mu un lọ.

Gbogbo eto lo ti pari lori nnkan ti wọn fẹẹ ṣe, eleyii to yẹ ko waye ni Iris Club House, Oke-Odo, ilu Iwo, ṣugbọn gẹgẹ bii ọdọkunrin, Shuaib sọ pe oun fẹẹ lọ o gba bọọlu, gẹgẹ bii iṣe rẹ, pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ lori papa iṣere ileewe St Mary’s Grammar School, niluu Iwo, ki eto ọhun too bẹrẹ.

Ko pẹ ti wọn bẹrẹ bọọlu ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ naa ni ede-aiyede bẹrẹ laarin Ahmed, to n gbe lagbegbe Atanda ati Shuaib Iṣọla, lojiji ni ọrọ naa si di ija nla.

Ahmed gba Shuaib lẹṣẹẹ, ṣe niyẹn mu ẹyin lọ silẹ, lọrọ ba di bo o lọ o yago, awọn ti wọn jẹ agba nibẹ ni wọn ṣugbaa Shuaib, wọn si gbe e lọ sileewosan Jẹnẹra, niluu Iwo.

Ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, ileewosan ni wọn ti sọ fun wọn pe Shuaib ti jade laye, bẹẹ ni ariwo ẹkun sọ ninu ile wọn, ti gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ Rotaract ilu Iwo, ti wọn n pe ara wọn ni Rota Empire, si bara jẹ gidigidi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ. O ni bo tilẹ jẹ pe awọn mọlẹbi Shuaib ti gbe oku rẹ lọ sile, ti wọn si kọ jalẹ pe awọn ko le yọnda oku rẹ fun ayẹwo kankan, sibẹ, awọn ti mu Ahmed.

Ọpalọla ni Ahmed yoo ran awọn ọlọpaa lọwọ lori iwadii wọn nipa iṣẹlẹ naa.

Oniruuru nnkan lawọn ọmọ ẹgbẹ Rotaract n kọ sori ẹrọ ayelujara feesibuuku Shuaib. Gbogbo wọn ni wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ẹni to niwa agba, to si maa n fi gbogbo igba wa ire ọmọ ẹgbẹ.

Leave a Reply