Eyi ni bi awọn Sifu Difẹnsi ṣe ba oyun oṣu mẹta jẹ mọ Funmilayọ lara n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Nitori bi awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo ilu, iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps (NSCDC), ta a mọ si Sifu Difẹnsi ṣe lu oun atọkọ ẹ nilukulu nigboro Ibadan, oyun oṣu mẹta ti bajẹ mọ obinrin naa, Funmilọla Adekọya, lara.

Ọkọ obinrin naa, Ọgbẹni Francise Adekọya, lo kọkọ riya he nigba ti meji ninu awọn eeyan yii ti a ko mọ orukọ wọn, pẹlu ọkunrin kan ti wọn jọ pera wọn ni oṣiṣẹ to n gbowo ori fun ijọba ipinlẹ Ọyọ, lọọ ka oun atiyawo ẹ mọ ṣọọbu wọn to wa nileetaja igbalode kan ti wọn n pe ni Gbangbalọlọunwa Complex, lagbegbe ka Idi-Ọpẹ, ni Imalefalaafia, Oke-Ado, n’Ibadan, lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii, ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

Owo ti tọkọ-tiyawo yii ko ri san lo mu ki wọn fiya jẹ Ọgbẹni Francise. Bi ara ṣe ta iyawo ẹ (Funmilọla), to ni ki wọn fi ọkọ oun silẹ ni wọn ki oun paapaa mọlẹ, ti wọn si bẹrẹ si i rọjo iya le e lori.

Loju ẹsẹ lobinrin ọlọmọ kan to loyun ekeji sinu yii dákú, ko too di pe awọn dokita fidi ẹ mulẹ pe oyun oṣu mẹta to ni ti bajẹ mọ ọn lara lẹyin ti awọn araadugbo ti sare gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan lagbegbe naa.

Diẹ lo ku ki oju ọkọ paapaa fọ nibi ti awọn ọdaju eeyan ti wọn pera wọn laṣoju ijọba yii fiya jẹ ẹ de.

SIfu Difẹnsi to fiya jẹ tọkọ-taya

Nigba to n royin bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye, Ọgbẹni Francise ṣalaye pe “Awọn eeyan yẹn ko ṣafihan nnkan kan to le jẹ ka mọ pe loootọ ni wọn jẹ aṣoju to n gba owo-ori fun ijọba. Ṣadeede ni wọn kan de, ti wọn ni ka maa san ẹgbẹrun meji naira (N2,000) gẹgẹ bii owo-ori ta a ni lati san sapo ijọba ipinlẹ Ọyọ.

“Mo dahun pe mi o lowo lọwọ bayii nitori awa naa ko ti i pawo kankan laaarọ ọjọ yẹn, ati pe ẹ ko sọ fun wa ti tẹlẹ pe ẹ n bọ, a ba ti mura yin silẹ. Bi wọn ṣe da a ságídí niyẹn. wọn ni awọn maa ti ṣọọbu mi ti mi o ba rowo san.

“Wọn ti wọ mi jade ninu ṣọọbu mi. Nibi ti wọn ti fẹẹ fagídí ti ṣọọbu mi ni mo ti yari mọ wọn lọwọ. Bi wọn ṣe bẹrẹ si i lu mi niyẹn.

“Kinni ina kan bayii ti wọn mu lọwọ ni wọn kọkọ tẹ si mi lara. Niṣe niyẹn gbe mi bii igba ti ina ilẹtiriki ba ṣọ́ọ̀kì eeyan. Lẹyin naa ni wọn fin gaasi tajútajú si mi loju, ti mi o si rina ri nnkan kan laarin iṣẹju marun-un.”

“Nibi ti iyawo mi ti n da wọn lẹkun ni wọn ti fi kinni ina yẹn gbe oun naa, to si ṣubu lulẹ, to daku gbọnrangandan. Ọpẹlọpẹ awọn araadugbo ti wọn sare ba mi gbe e lọ sọsibitu.

“Awọn dokita sọ pe Ọlọrun lo doola ẹmi iyawo mi nitori oyun oṣu mẹta to wa lara ẹ ti bajẹ. O ṣi wa lọsibitu to ti n gbàtọ́jú di bi mo ṣe n sọrọ yii.”

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, agọ ọlọpaa to wa ni Iyaganku, n’Ibadan  lọkunrin to pera ẹ lẹnjinnia kọ̀ǹpútà yii kọḳọ fẹjọ sun. Ohun ti awọn ọlọpaa si sọ ni pe awọn ko le mu awọn Sifu Difẹnsi naa nitori pe oṣiṣẹ ijọba apapọ lawọn jọ jẹ, iṣẹ agbofinro kan naa lawọn si jọ n ṣe.

Ọkunrin ti wọn fiya jẹ pẹlu iyawo ẹ yii ti waa rọ ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Ṣeyi Makinde, lati ṣewadii iṣẹlẹ yii, ki wọn si gbe igbesẹ to ba yẹ lori rẹ.

Alukoro ajọ NSCDC nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Oluwọle Oluṣẹgun, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni nitori pe Ọgbẹni Fracise atiyawo ẹ lu awọn oṣiṣẹ ajọ naa lawọn naa ṣe fọwọ ba wọn lati le gba ara wọn silẹ lọwọ iya àjẹkú dórógbó.

O fi kun un pe oṣiṣẹ awọn ti wọn lu yii naa wa nileewosan to n gbatọju lọwọ bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ileewosan naa.

Agbẹnusọ fun Gomina Makinde, Ọgbẹni Taiwo Adisa, ti sọrọ lori iṣẹlẹ yii, o lo ya oun lẹnu pe ẹnikẹni le ṣe bẹẹ lo agbofinro lati jẹ ọmọ ipinlẹ yii niya lọna aitọ.

O sọ gbangba pe ijọba ko ran ẹnikẹni niṣẹ lati fipa gbowo ori lọwọ araalu nitori ni kete ti gomina yii ti dori aleefa lo ti gbe iṣẹ owo-ori gbigba le ileeṣẹ aladaani kan lọwọ, ati pe ọna to bofin mu lawọn eeyan naa fi n ṣiṣẹ ti ijọba gbe le wọn lọwọ ọhun.

Leave a Reply