Eyi ni bi awọn agbebọ ṣe pa awọn ara Ikarẹ-Akoko mejilelogun ti wọn n bọ lati ipinlẹ Bauchi

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mejila la gbọ pe ọwọ ti tẹ lori iṣẹlẹ iṣekupani to waye ni oju ọna Rkuba, niluu Jọs, nipinlẹ Plateau, nibi ti awọn janduku kan ti pa eeyan bii mejilelogun ti wọn jẹ eeyan ipinlẹ Ondo.

ALAROYE gbọ pe ibi eto adura ọlọdọọdun kan ti wọn n pe ni Zikir prayer lawọn eeyan naa lọ ni ipinlẹ Bauchi. Nigba ti wọn n pada bọ lọjọ Abamẹta, Satide, ni awọn ọdọ Irigwe da bọọsi marun-un ti awọn eeyan naa kun inu rẹ lọna, ti wọn si ṣakọlu si wọn. Mejilelogun la gbọ pe o ku ninu wọn, ti ọpọ ninu wọn si fara pa. Bẹẹ ni awọn ọlọpaa ri awọn mejilelogun mi-in doola gẹgẹ bi wọn ṣe sọ.

A gbọ pe awọn ọdọ Irigiwe yii ti sọ pe ọjọ Abamẹta naa ni awọn fẹẹ lọọ sin awọn eeyan awọn ti wọn pa nipa oro nitori wahala to ti n waye lagbegbe naa laarin awọn Musulumi ati Onigbagbọ, si Bassa. Awọn eeyan naa ni awọn ọlọpaa ni awọn gbagbọ pe o kọju ija si awọn ẹlẹsin Musulumi ti wọn n bọ lati ipinlẹ Bauchi, ti wọn n pada lọ si Ikarẹ-Akoko yii, ti wọn si pa mejilelogun ninu wọn.

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn Musulumi ti awọn onijaadi ẹṣin yii yinbọn pa nipinlẹ Plataeu laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ọhun.

Ninu atẹjade kan to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Ọlabọde Ọlatunde, lo ti juwe iṣẹlẹ ọhun bii nnkan ibanujẹ patapata, to si ni oun ba gbogbo awọn mọlẹbi awọn to ku naa kẹdun pupọ lori ajalu airotẹlẹ to waye naa.

O ni kete ti oun gbọ ohun to ṣẹlẹ loun ti kan si ojugba oun to jẹ Gomina ipinlẹ Plateau, Simon Lalong, lati fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, tí abọ iwadii ti oun ṣe si fihan pe aṣiṣe ati asimu patapata lọrọ iku awọn Musulumi to wa lati ilu ipinlẹ Ondo naa jẹ.

Arakunrin ni oun ri i gbọ pe lati bii oṣu diẹ sẹyin ni ija ajakuata ti n waye laarin ẹgbẹ awọn Musulumi kan atawọn Kiristiẹni to wa lagbegbe Oke-Ọya, o ni iṣẹlẹ ọhun ki i sọrọ ẹlẹyamẹya, bẹẹ ni ko waye rara lati fi doju ogun kọ awọn ajoji tabi awọn ẹya kan.

Awọn arinrin-ajo lati ilu Ikarẹ Akoko ọhun lo ni wọn ṣe akọlu si lẹyin ti wọn ṣeesi lọọ gba agbegbe ti wahala ti n waye laarin awọn Musulumi atawọn Kristiẹni l’Oke-Ọya, leyii to ṣokunfa iku ọpọlọpọ, ti awọn mi-in si tun fara pa yannayanna.

Gomina Akeredolu ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lati mọ ọkọọkan awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ ibanujẹ naa kijọba le mọ bi yoo ṣe kan si ẹbi wọn fun igbesẹ to yẹ.

Bakan naa lo parọwa fawọn eeyan ipinlẹ Ondo ki wọn fọwọ wọnu, ki wọn ma si ṣe dabaa ati ṣe idajọ iṣẹlẹ ọhun lọwọ ara wọn nitori ijọba ṣetan ati ri i daju pe idajọ ododo waye lori iṣẹlẹ awọn to ku naa.

Leave a Reply