Eyi ni bi awọn Fulani to ji mi gbe ni Lanlatẹ ṣe pa ọkọ afẹsọna mi

Obinrin oniṣowo kan, Modupẹoluwa Oyetọṣọ, wa ninu ọfọ iku ọkọ afẹsọna rẹ lọwọlọwọ bayii, adanu naa si pọ fun un. Awọn Fulani ni wọn yinbọn pa ọkọ rẹ nigba ti wọn n ti oko igbalode nla ti wọn n da si agbegbe Lanlatẹ, nijọba ibilẹ Ibarapa, bọ.

Modupẹ so fun awọn oniroyin Twinklefiles pe bi awọn ti n toko bọ ni bii aago marun-un irọlẹ lawọn Fulani naa fo ja gbangba lati inu igbo ti wọn sa pamọ si, ti wọn si mura lati da awọn lọna. Ni ọkọ afẹsọna rẹ to n wa mọto yii ba gbiyanju lati fi ọgbọn yọ lọwọ wọn. N lawọn Fulani naa ba da ibọn bolẹ. Ọmọbinrin naa tẹ siwaju bayii pe:

“Ipakọ ni ibọn naa ti ba ọkọ afẹsọna mi, n lẹjẹ ba n tu kọọ kọọ jade. Mi o tete mọ ohun ti mo maa ṣe nigba to jẹ awa meji naa ni. Mo ro pe mo le gba ẹmi ẹ la ni, mo gbiyanju lati da ẹjẹ naa duro ṣugbọn ko ṣee ṣe, nitori mọto funra rẹ ko duro: o n sare lọ, o fẹẹ fori sọgi. Bi mo ṣe gbiyanju lati da mọto naa duro, ti iyẹn duro bayii, niṣe lawọn Fulani yii de, ni wọn ba wọ mi jade. Bi wọn ti wọ mi jade ni wọn bẹrẹ si i gbe mi sare lọ, wọn fẹẹ tete kuro nitosi ibẹ, wọn si fi ọkọ afẹsọna mi silẹ loun nikan fun iku pa.

“Bi a ti wọ inu igbo ni wọn ti mu okun gidigba kan jade, ni wọn ba fokun naa de mi lọwọ, okun yii ni ọkan ninu wọn si n fa to fi n wọ mi lọ ninu igbo nibẹ. Fulani kan lo n wọ mi lọ o, Fulani mi-in wa lẹyin mi ti iyẹn n ko ẹgba bo mi ti mo ba ti fẹẹ duro, tabi ti mi o  ba le sare daada mọ. Igba kan wa ti mo ṣubu, niṣe ni wọn kogi bo mi ti wọn tun fa mi dide, ti wọn ni ki n maa sare lọ. Gbogbo agabra mi ni mo lo lati fi sare, nitori ojo kuku tiẹ n rọ.

“Ori mi lojo yẹn ti bẹrẹ, ori mi naa lo da le, nitori a kan n rin kiri inu igbo ni, ko si ibi ti a maa duro si, ko si si abẹ orule kan ti a le sa si. Igba kan wa ti a de ibi odo nla kan bayii, nitori ojo to n rọ, ọgbara ojo naa pọ gan-an. Ọkan ninu wọn lo kọkọ rọra kọja ninu odo yii, lẹyin to ti lọ lo ni ki awọn to ku maa bọ, ni wọn ba ti emi siwaju, pe ki n kọkọ lọ. Emi o ga to wọn, aya mi si ja gan-an lati wọ inu odo yii. Ṣugbọn nigba ti wọn tun kogi bo mi, mo bẹrẹ si i wọ inu odo naa lọ. Ọkan ninu won naa lo mu okun dani lati maa fi fa mi titi ti mo fi rin de odi keji.

“Nigba ti wọn de ibi kan ti wọn ro pe ko si ewu fawọn mọ, wọn da mi jokoo, wọn waa yọ foonu ọkọ afẹsọna mi ti wọn ti mu ninu mọto jade, won yọ siimu to wa ninu ẹ, wọn fi siimu naa si inu foonu mi-in, wọn wa ni ki n pe baba mi, ki n si sọ fun un pe aadọta miliọnu Naira lawọn maa gba, ti wọn ko ba fẹ ki wọn pa mi sinu igbo nibẹ. Baba mi bẹrẹ si bẹ wọn, o sọ fun wọn pe ọjọ Satide ni, ko ṣeni kan to n ko owo sile. Ati pe oṣiṣẹ-fẹyinti loun, oun ko ri iru owo bẹe ri. Ibẹ ni ọkan ninu wọn ti yinbọn sọọkan ọdọ mi ‘gbabu!’ o ni baba mi ro pe ere lawọn n ṣe ni. Wọn ni bi awọn ko ba ri owo yẹn gba, awọn maa pa mi, awọn dẹ maa wa ẹni to maa wa ara ẹya ara mi lọkọọkan lọdọ awọn.

“Ni bii aago mẹsan-an alẹ ni baba mi de Eruwa, wọn waa bẹrẹ si da a laamu, Ọna mẹta ni wọn ni ki wọn lọ ko too di pe wọn ṣẹṣẹ ni ko ju owo naa silẹ nibi kan, ohun ti wọn fẹẹ mọ ni boya awọn eeyan kan tabi awọn agbofinro n tẹ le e. Nigba ti wọn gbe owo naa fun wọn, wọn pe ẹni ti wọn fi silẹ ko maa ṣọ mi pe ko maa mu mi bọ. O to iṣẹju mẹẹdogun ka too ja si ibi ti baba mi wa, koda a kọja lara awọn to ku, mo ba wọn nibi ti wọn ti n ka owo ti baba mi gbe wa. Bi mo ṣe  bo lọwọ wọn niyẹn o. Mo mọ pe Fulani ni wọn, nitori mo maa n ri awọn Fulani daadaa nbi ti a ti n ṣoko, mo si mọ aṣọ wọn ati ede ẹnu wọn. Eto aabo ko da ladugboo Lanlatẹ yii rara o, awọn alaṣẹ gbọdọ tete moju to o!”  

Leave a Reply