Eyi ni bi awọn janduku ọlọkada ṣe fibinu fọ ọga ọlọpaa lori l’Ekoo, wọn pa a patapata

 Faith Adebọla, Eko

 Ko sẹni ti yoo ri fọto ọga ọlọpaa, CSP Kazeem Sumọnu Abọnde, ti wọn lawọn ọlọkada kan ṣeku pa l’Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii, ti aanu rẹ ko ni i ṣeeyan, pẹlu bi ẹjẹ ṣe wẹ oku rẹ latori delẹ ninu aṣọ ọlọpaa to wọ, ibinu ni wọn fi pa agbofinro naa nipa ika.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lawọn ti da awọn ọtẹlẹmuyẹ sigboro, wọn si ti bẹrẹ iwadii labẹlẹ lori iṣẹlẹ buruku to waye naa.

Bi Adekunle Ajiṣebutu ṣe sọ f’ALAROYE ninu atẹjade to fi ṣọwọ si wa, o ni oloogbe naa wa lara awọn ti wọn yan lati maa mu awọn ọlọkada ti wọn n rufin irinna l’Ekoo, titi kan awọn ibuba ti wọn ba fura pe awọn adigunjale ati ẹlẹgbẹ okunkun fara pamọ si. Wọn o si ṣẹṣẹ maa ṣiṣẹ ọhun, loorekoore ni, iṣẹ ọba yii ni wọn lọọ ṣe laduugbo Ajao Estate, nijọba ibilẹ Oṣodi/Isọlọ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.((((

Ajiṣebutu ni wọn ti mu awọn ọlọkada kan to lufin, wọn gba ọkada wọn, wọn tun mu awọn afurasi ọdaran kan pẹlu. Bi wọn ṣe fẹ maa lọ lawọn janduku kan ti ko ara wọn jọ, wọn ko ibọn, ada, aake atawọn nnkan ija oloro loriṣiiriṣii, wọn si lugọ de awọn agbofinro naa lẹnu geeti Ajao Estate ti wọn fẹẹ gba jade, lawọn janduku naa ba bẹrẹ si i ṣakọlu sawọn ọlọpaa, wọn bẹrẹ ija, yanpọnyanrin si ṣẹlẹ.

Ninu rogbodiyan ọhun lawọn agbofinro yooku ti dọgbọn kọja, ti wọn si sa lọ pẹlu ọkọ wọn, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe oloogbe naa to bọ silẹ lati lọọ pẹtu sawọn janduku naa ninu ni wọn gba mu, wọn si bẹrẹ si i la oriṣiiriṣii nnkan ija to wa lọwọ wọn mọ ọn lori titi to fi ku.

Wọn tun ṣe awọn ọlọpaa mi-in leṣe, bo tilẹ jẹ pe ori ko wọn yọ, wọn lọsibitu ijọba to wa n’Isọlọ ni CSP Abdullahi Malla, DPO ọlọpaa to n ṣakoso teṣan Ajao Estate atawọn ẹlẹgbẹ rẹ mi-in wa ti wọn ti n gba itọju latari akọlu ọhun.

ALAROYE gbọ pe wọn ti gbe oku Oloogbe Abọnde lọ si mọṣuari ileewosan Yaba Mainland Hospital, to wa ni Yaba, fun ayẹwo.

Kọmiṣanna ọlọpaa Eko, CP Hakeem Odumosu, ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, o ni gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ika to gogo yii lawọn maa fi jofin, o si ṣeleri pe iṣẹlẹ yii ko le ko awọn laya jẹ, awọn o ni i kẹrẹ lẹnu ojuṣe awọn lati fọ ilu Eko mọ lọwọ awọn ọdaran to ba kọ lati jawọ.

Leave a Reply