Eyi ni bi awọn kọsitọọmu ṣe gba ẹgbaagbeje ọmọ Naijiria lọwọ iku ojiji

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkẹ aimọye alaisan lorileede yii ni iba ra oogun fun iwosan ara wọn lai mọ pe majele lawọn fowo ara awọn ra, nitori oogun ọhun naa ni iba ṣeku pa wọn.

Eyi ri bẹẹ latari bi awọn onífàyàwọ́ ṣe fẹyin pọn ọpọlọpọ ayederu oogun wa lati ọkan ninu awọn orilede ilẹ Afrika to pààlà pẹlu ilẹ wa Naijiria nibi, ṣugbọn ti awọn oniṣowo naa ko sọwọ ajọ aṣọbode ilẹ yii ta a mọ si Nigeria Customs Services, ti awọn yẹn si gba gbogbo oogun naa lọwọ wọn, ki awọn oniṣowo ọhun too na papa bora.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹtadinlogun (17), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii, lọga ileeṣẹ aṣọbode ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, Ọmọwe Ben Oramalugo, fa ẹru oogun naa le Abilekọ Roseline Ajayi, ti i ṣe alakooso ajọ to n gbogun ti ijẹkujẹ ati ilokulo oogun nilẹ yii (National Agency for Food and Drug Administration and Control, NAFDAC) lọwọ.

Loju-ẹsẹ ni Abilekọ Ajayi, to jẹ alakooso ajọ NAFDAC lẹkun Iwọ-Oorun Guusu orileede yii, ti i ṣe ilẹ Yoruba nibi, si ti ṣapejuwe awọn oogun naa gẹgẹ bii ohun to lewu gidigidi fun ọmọniyan nitori ayederu pọnbele ni gbogboo wọn.

Bẹẹ naa lo ṣafihan awọn ẹru mi-in ti ileeṣẹ aṣọbode gba lọwọ awọn onifayawọ fawọn oniroyin.

Lara awọn ẹru ọhun ni ọrinlelẹẹẹdẹgbẹrun ati meji (982) apo irẹsi to jẹ tilẹ okeere, eyi ti owo ẹ fẹẹ to miliọnu lọna ẹẹdẹgbẹrun Naira (N86.416m); aloku taya ọkọ ayọkẹlẹ ati ti bọọsi, ti wọn fi ẹyọ mẹfa din ni ọtalerugba (254) niye, ṣugbọn ti owo wọn le diẹ ni miliọnu mẹrinlelogun (N24.384 m); pẹlu dọ́sìnnì kan taya ọkọ tirela, ti owo wọn to miliọnu lọna ọgọrun-un Naira.

Bakan naa ni wọn ṣafihan ojulowo igan aṣọ mẹtadinlọgbọn (27), towo wọn n lọ bii miliọnu mẹtala Naira (N12,757,500); ati apo aṣọ aloku ta a mọ sí bọ́síkọrọ̀ mẹẹẹdọgbọn (25), ti owo ẹ le diẹ ni miliọnu mọkanla Naira (N11,437,440).

Awọn nnkan yooku ni kẹẹgi nla nla to fi ẹyọ mẹfa din ni ẹẹdẹgbẹta (494), ti gbogbo wọn kun fun epo bẹtiroolu ilẹ yii, eyi ti awọn fayawọ oniṣowo n gbiyanju lati gbe lọ sorileede mi-in lọọ lu ta ni gbanjo; apo nla nla mejila, to kun fun egboogi oloro ti wọn n pe ni igbo, ati idi ogoji mi-in bàǹbàbàǹbà ti wọn di mọ́ránmọ́ran sinu ewe ati ọra; ati ogun (20) paali oogun oloro ti wọn n pe ni Tramadol, eyi ti owo ẹ to miliọnu kan Naira (₦1m).

Yatọ si awọn ẹru ti wọn gbẹsẹ le latọwọ awọn oniṣowo to n gbiyanju lati gbe ọja jade tabi wọle sorileede yii lọna aibofin mu, owo ti ajọ aṣọbode n pa wọle sapo ijọba apapọ orileede yii lati ara owo ibode lori awọn ọja to n gba ọna ẹtọ wọle silẹ yii ki i ṣe kekere.

Lẹyin naa lo fa awọn to jẹ oogun ati gbogbo egboogi oloro to wa ninu awọn ẹru naa le ọga ajọ NAFDAC lọwọ.

Nigba to n dupẹ lọwọ ileeṣẹ aṣọbode fun bi wọn ṣe ba wọn ṣiṣẹ to jẹ ojuṣe wọn, ọga ajọ NAFDAC, rọ ileeṣẹ aṣọbode lati maa mu awọn onifayawọ to ba wa nidii kiko nnkan wọle tabi jade lorileede yii, o ni iyẹn nikan lo le fopin si bi awọn eeyan ṣe n ko nnkan wọle tabi jade nilẹ yii lọna ti ko bofin mu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A maa gbe awọn oogun wọnyi lọ si yara ayẹwo lọfiisi wa fun ayẹwo, ṣugbọn lai tiẹ ti i ṣayẹwo ọhun paapaa, bi mo ṣe n fi oju lasan wo awọn oogun wọnyi ni mo ti mọ pe ayederu pọnbele ni wọn, wọn kan kọ nọnba ileeṣẹ wa (NAFDAC) sara wọn lasan ni, ayederu nọmba Náfúdáàkì ni wọn kọ si wọn lara,”.

Leave a Reply