Eyi ni bi eeyan kan ṣe ku lasiko iwọde Yoruba Nation l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Oju ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Abiọdun Alabi, ko mu ẹrin lọwọ lasiko yii, bẹẹ lọkunrin naa ko ṣawada, niṣe lo n naka ikilọ sawọn ti wọn fẹẹ da omi alaafia ilu Eko ru, pe ki kaluku tete lọọ so ewe agbejẹ mọwọ, kọlọmọ si kilọ fọmọ rẹ, tori ẹni tawọn ba gba mu nidii iwa idaluru, tabi janduku ṣiṣẹ, tọhun yoo kan idin ninu iyọ ni.

Ọsan ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹsan-anoṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni Alabi laago ikilọ ọhun ninu atẹjade kan to fi lede nipasẹ Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjamin Hundeyin, lori lọgbọ-lọgbọ kan to waye lagbegbe Ọjọta si Ketu, nipilẹ ọhun lọjọ naa.

Alabi ni o jẹ ohun to ya oun lẹnu bawọn afurasi ọdaran kan, atawọn janduku, ṣe ko ara wọn jọ, ti wọn lawọn n ṣe iwọde, lai fi to ọlọpaa leti, ti wọn si bẹrẹ si i ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ, ati kara-kata awọn ẹni to n lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ wọn laaarọ ọjọ Mọnde naa.

O leyi to jọ oun loju ju ni bawọn eeyan naa ṣe bẹrẹ si i ṣe akọlu sawọn ọlọpaa ti wọn ko ṣẹ wọn, ti wọn ko ba wọn ja, ti wọn si n fija pẹẹta pẹlu wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa yii ni: “Loootọ la bọwọ fun ẹtọ araalu labẹ ofin lati ṣewọde wọọrọwọ, a si mọ pe wọn lẹtọọ lati kora jọ tabi ki wọn ṣe ẹgbẹ to ba wu wọn, bakan naa ni wọn lominira lati sọrọ, ṣugbọn a o ni i laju silẹ ki ẹnikan tabi ẹgbẹ kan ṣi iru ẹtọ bẹẹ lo, debi ti ọrọ, iwa tabi iṣe wọn yoo maa tẹ ẹtọ ẹlomi-in mọlẹ, tori aparo kan o ga ju ọkan lọ, ẹfọ o si gbọdọ le ẹfọ lawo.

“Latari eyi, mo parọwa sawọn obi, alagbatọ, awọn alẹnulọrọ, ẹyin olori ẹsin, adari adugbo, ẹyin ladelade ati ọtọkulu, pe kẹ ẹ ba awọn ọmọ yin niwọọ, kẹ ẹ so ewe agbejẹ mọwọ, ki wọn ma lero pe a maa fọwọ yọbọkẹ mu ẹni to ba tapa sofin, tori yiyọ ẹkun wa, tojo kọ rara.

“Bakan naa ni ki eku ile gbọ ko sọ fun toko, ki adan gbọ ko lọọ ro foobẹ, ẹnikẹni to ba ṣakọlu si ọlọpaa, to fija pẹẹta pẹlu agbofinro eyikeyii, tọhun yoo kan dudu inu ẹkọ ni,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Ọrọ ikilọ yii ko ṣẹyin rogbodiyan to ṣẹlẹ lagbegbe Ọjọta,  nibi ti Alaroye ti gbọ pe awọn kan ti wọn n ṣewọde  lori idasilẹ orileede Yoruba, ti wọn n ja fun ki Yoruba ya kuro lara Naijiria, ko asia ati akọle dani, ti wọn si n yan lọ si ọgba Gani Fawehinmi Park to wa l’Ọjọta.

Wọn ni bi wọn ṣe n yan lọ ọhun ni wọn n kọrin lati fi imọ riri wọn han si ajijangbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ti wọn si n beere fun itusilẹ rẹ kuro ni orileede Bẹnẹ ti wọn fofin de e mọ, wọn ni kijọba da a silẹ ko pada wale, ati pe boya Sunday Igboho wale o, abi ko wale o, ko sohun meji tawọn n fẹ ju ki Yoruba kuro lara Naijiria lọ.

Alaroye gbọ pe ki wọn too de Ọjọta ọhun lawọn ọlọpaa ti lọọ tẹlẹ de wọn, wọn tun lawọn ọmọọta kan atawọn janduku ti dara pọ mọ ero naa.

Ko sẹni to le sọ pato ohun to fa ija ojiji to waye lọjọ naa. Awọn kan lawọn ọlọpaa lo kọkọ ṣakọlu sawọn ajijangbara yii, lọrọ ba dija, awọn kan si ni awọn janduku lo fa a.

Asẹyinwa-asẹyinbọ, eeyan meji lo ku, ọpọ si fara pa yannayanna lasiko ti eruku ija naa n goke lala.

Ni bayii, awọn agbofinro ti dẹrọ rogbodiyan ọhun.

Leave a Reply