Eyi ni bi eeyan meji ṣe ku lasiko ti tanka epo gbina ni marosẹ Eko s’Ibadan

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ni nnkan bii aago mẹfa aarọ kọja iṣẹju marun-un Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu keji, ọdun 2022 yii, nijamba ina kan ṣẹlẹ nikọja Interchange, loju ọna marosẹ Eko s’Ibadan, teeyan meji si doloogbe.

Epo bẹntiroolu ni tanka to fẹgbẹ lelẹ naa gbe, awọn tirela mẹta mi-in pẹlu ọkada kan naa si fara gba nibẹ pẹlu.

Ohun tawọn FRSC sọ ni pe ọkan ninu awọn tirela ọhun lo n wa iwakuwa loju popo, oun lo fi tiẹ koba awọn yooku ti eyi to gbe epo fi ṣubu.

Eeyan mẹjọ ni wọn sọ pe ijamba yii kan, ọkunrin ni gbogbo wọn, ṣugbọn awọn meji lo padanu ẹmi wọn sinu ina to ṣẹ yọ nigba ti tanka agbepo ṣubu.

Awọn panapana ti pana ọhun lasiko ta a n kọ iroyin yii, awọn FRSC si ti dari awọn ọkọ gba ibomi-in loju ọna yii.

Leave a Reply