Faith Adebọla
Agbọ-sọgba-nu niroyin iku igbakeji ọga ọlọpaa to wa ni ẹka to n mojuto iwa ọdaran lolu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Abuja, Joseph Egbunike, to ku lojiji. Gbogbo awọn to ri i lọjọ naa, ti ko si si ami pe ọlọjọ ti n kanlẹkun lara rẹ ni iku naa n jẹ ijọloju fun. Lalẹ ọjọ Iṣẹgun ni ọkunrin naa digbo lulẹ ni ọfiisi rẹ to wa ni FCID Area 10, niluu Abuja, to si ṣe bẹẹ ku patapata.
A gbọ pe o fẹ si ọkunrin naa diẹ lopin ọsẹ. Eyi lo mu ko gba ọdọ dokita rẹ lọ fun ayẹwo ara rẹ lọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii. Dokita fun un loogun, o si ni ko maa lọ sile.
Ọga ọlọpaa yii atawọn mọlẹbi rẹ ni wọn ni wọn jọ wa ninu ọkọ to gbe e kuro lọsibitu, ti ko si si ami pe ọlọjọ ti detosi. Afi bi ọkunrin naa ṣe de ọfiisi rẹ pada ti wọn ni o ṣubu lulẹ, to si ṣe bẹẹ ku.
Ọmọ ilu Onitsha, nipinlẹ Anambra, ni ọkunrin yii. Ẹka to n mojuto eto inawo ati eto gbogbo ni olu ileeṣẹ ọlọpaa lo ti kọkọ wa ki ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Usman Baba, too yan an gẹgẹ bii adari igbimọ lati ṣewadii Abba Kyari, igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa to n ri si awọn ẹsun to ba takoko lori iwa ọdaran ati ijinigbe, ti wọn fẹsun jibiti kan.
Ọrọ ọmọ Naijiria ti wọn mu lorileede Dubai pe o lu jibiti owo to le ni miliọnu kan dọla (1.1m), Hushpuppi, lawọn ọlọpaa Amẹrika n tori rẹ wa Kyari ti wọn ni ọwọ rẹ ko mọ lori iṣẹlẹ naa. Ọkunrin yii ni wọn ni ko ṣewadii ọrọ naa.