Eyi ni bi iku ojoji ṣe yẹ lori awọn eeyan lasiko ti baaluu kan ja n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọṣẹ yii, ni baaluu kan to jẹ ti Peace airline kan to ni nọmba 5N-BQR to n bọ lati ilu Abuja ja lulẹ ni Papakọ ofurufu ti ilu Ilọrin, nigba ti taya rẹ fọ, ti ọpọ awọn ero ti baalu naa ko si mori bọ lọwọ iku ojiji.

Iroyin ti a gbọ ni pe baaluu ọhun to n bọ lati ilu Abuja lo fẹẹ balẹ si papakọ ofurufu n’llọrin, ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ owurọ ọjọ Ẹti, ni taya rẹ ba fọ, eyi lo mu ki baaluu naa fi aya sọlẹ ni opopona to yẹ ko maa tọ lọ. Niṣẹ ni gbogbo awọn ero to ko n sare sọ kalẹ, ti ẹru to ko si da le awọn ero kan lori ninu baaluu ọhun.

Titi di igba ti a n ko iroyin yii jọ, wọn ti ti opopona baaluu naa pa, ti wọn si n wa gbogbo ọgbọn lati wa opopona miiran fun baaluu miiran to ba fẹẹ ba, ṣugbọn awọn ọmọ ogun ori ofurufu ko fẹ ki iroyin naa han sita.

Ninu atẹjade kan ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun ofurufu fi sita ni ọjọ Abamẹta, Satide, ọṣẹ yii, ni wọn ti sọ pe baluu  B737-500 pẹlu nọmba 5N-BQR to n bọ lati ilu Abuja ko ja lulẹ gẹgẹ bi iroyin ṣe n gbe e kiri, ṣugbọn lẹyin to ti balẹ tan tawọn ero inu rẹ si ti sọ kalẹ layọ ati alaafia ni taya baaluu ọhun fọ, ti wọn si ti fi taya miiran si i bayii, ti nnkan kan ko si ṣe baaluu naa.

Leave a Reply