Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ to n ri si eto irinna si orilẹ-ede Saudi lati ilẹ Naijiria, National Hajj Commission of Nigerian (NAHCON), ẹka tipinlẹ Kwara, ti kede pe awọn meji mi-in ninu awọn ọmọ ipinlẹ Kwara ti wọn ti kalẹ siluu Mẹka, lorilẹ-ede Saudi Arabia, fun iṣẹ Hajji ọdun 2024 yii, ti tun dagbere faye lẹyin aisan ranpẹ.
Ninu atẹjade kan tawọn igbimọ naa gbe jade l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, ni wọn ti ni awọn meji mi-in, Ayishat Shuib Ologele ati Salman Muhammad Alade, to tẹle ipele kẹta lati ipinlẹ Kwara, lọ si orile-ede Saudi Arabia, ni wọn ti tun ku si ileewosan kan niluu Mẹka, lẹyin aisan ranpẹ.
Abdulsalam Abubakar, ti i ṣe akọwe awọn igbimọ eleto Hajj nipinlẹọhun toun naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ sọ pe Ayishat Shuaib Ologele, ni aisan ranpẹ lasiko to n rinrin-ajo lati ilu Mẹdina lọ si Mẹka, ṣugbọn gbogbo igbiyanju awọn dokita lati doola ẹmi rẹ lo ja si pabo.
Bakan naa ni Salman Muhammad Alade naa tun ṣaisan ranpẹ niluu Mẹka, ko too di pe oun naa dagbere faye. Wọn ni bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ idi iku to pa a, ṣugbọn awọn nigbagbọ pe iku ati ọdọ Ọlọrun ni.
O gba a laduura si Ọlọrun Ọba pe ko fori gbogbo aṣiṣe awọn oloogbe jin wọn, ko si gba wọn si alujanna onidẹra
O rọ mọlẹbi awọn oloogbe naa lati gba a gẹgẹ bii amuwa Ọlọrun, nitori ko si ẹda kan ti yoo lo kọja igba ti Ẹlẹdaa ti da fun un.