Eyi ni bi onilu Ayinla Ọmọwura, Adewọle Alao, ṣe ku gan-an

Jide Alabi ati Adefunkẹ Adebiyi
Laṣaalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2020, ni gbajumọ onilu Ayinla Ọmọwura ti orukọ rẹ han kaakiri ilẹ Yoruba nni, Alaaji Abdul-Rahman Adewọle Alao Onilu-ọla, jade laye niluu Abẹokuta.
Ninu ọrọ ti akọbi baba yii, Arabinrin Silifatu Owolabi-Adewọle, sọ f’ALAROYE lo ti fidi ẹ mulẹ pe ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin ni baba bẹrẹ aisan, ti awọn si gba dokita to n tọju wọn nile.
O ni, “Nigba to di ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ni baba mi pe mi, ohun ti wọn sọ lẹyin ti wọn dupẹ lọwọ gbogbo awa ọmọ fun itọju ti a fun wọn ni pe bi ọrọ ṣe ri yii, o da bii pe ọlọjọ ti n sun mọ, nitori awọn ko ṣaiṣan ko mu awọn mọlẹ to bayii ri.
‘‘Wọn ni a ko gbọdọ gbe awọn lọ si ọsibitu kankan nitori apẹẹrẹ tawọn n ri yii, ọlọjọ ti n sun mọ ni..”
“Laipẹ yii ti wọn ṣayẹyẹ ọdun mẹtadinlọgọrun-un (97) fun wọn, lara owo ti wọn fun wọn, niṣe ni baba tun mu ninu ẹ lọọ fun awọn agbaagba ti wọn jẹ ẹgbẹ onilu, bẹẹ ni wọn fun ẹgbẹ ọdọ onilu, atawọn mọlẹbi wọn, iru eeyan ti baba jẹ niyẹn, ki Ọlọrun ba wa foriji wọn.
“Aisan ọsẹ kan to ṣe wọn yii, mo fẹẹ le sọ pe gẹgẹ bii akọbi wọn, iru ẹ ko ṣe wọn ri loju mi. Koda, nigba ti wọn ṣisẹ abẹ fun wọn lọdun 1993, ko le to bayii, ohun naa lo mu awọn gan-an sọ fun wa pe ohun ti awọn n ri yii, o jọ pe ẹlẹmi-in ti fẹẹ gba a ni.’’

 

Kamil Adeyinka Adewọle, ọkan ninu awọn ọmọkunrin baba ti iku oloogbe ṣoju ẹ, ṣalaye pe ‘‘Wọn fẹsẹ kọ ni nnkan bii ọsẹ kan sẹyin, wọn ko waa le jade mọ latigba yẹn, nitori o yi si aarẹ agba fun wọn. Bi dokita ṣe wa n tọju wọn lojoojumọ niyẹn, nitori wọn ni a ko gbọdọ gbe awọn lọ sọsibitu bawọn ko ba ti le dide rin jade funra awọn mọ. Lalẹ ọjọ ti wọn ku yii, dokita kọ oogun ẹgbẹrun mẹwaa naira fun wa pe ka lọọ ra a fun wọn, baba ni ka ma ra a, ṣugbọn awa wo o pe a ko ṣe ni i ra ohun ti dokita kọ, ṣebi ki ara wọn le ya naa ni, ba a ṣe lọọ ra oogun yẹn niyẹn, ṣugbọn baba ko duro lo o, wọn ti ku kẹni to lọọ ra oogun too de.
‘‘Ni nnkan bii aago mẹsan-an aabọ ni wọn ku, ṣugbọn emi nikan lọkunrin to wa nibẹ, mi o si fẹẹ tufọ naa lasiko yẹn nitori awọn obinrin to wa nibẹ, o ti n lọ si bii aago mẹwaa aabọ ki n too sọ fun wọn.
‘‘Emi ati baba sun mọ ara wa pupọ, nitori tiwọn ni mo ṣe ko wa si Abẹokuta pẹlu iyawo atawọn ọmọ mi, Eko la n gbe tẹlẹ.
‘‘Awa mọkanla ni baba mi bi, ọkunrin mẹrin, obinrin meje. Ipo kẹsan-an ni mo wa, iyawo mẹrin lo bimọ fun wọn kọlọjọ too de.’’
Ile Adewọle Onilu-ọla to wa ni Arinlẹsẹ, lẹgbẹẹ Itoko, l’Abẹokuta, ni wọn yoo sin baba naa si lẹyin irun aago mẹrin irọlẹ loni-in, Ọjọruu, Wesidee, ọgbọnjọ, oṣu kejila, 2020.
Ẹ oo ranti pe ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun yii, ni ẹgbẹ kan, ‘Ayinla Omowura Music Fans Club International’, ṣayẹyẹ ọjọọbi ọdun kẹtadinlọgọrun-un (97) fun Adewọle ni Liṣabi Elite Club, l’Abẹokuta, nibi ti awọn eeyan nla nla peju si lati mọ riri iṣẹ ti baba naa ṣe loju aye wọn, ko ma baa di pe ọjọ a ku la n dere, eeyan ko sunwọn laaye.
Lọjọ ayẹyẹ naa, ọkan ninu awọn eeyan to sun mọ baba daadaa, to si mọ nipa eto yii, sọ fun ALAROYE pe boun ati baba ṣe jọ jokoo tawọn n ya fọto ni oloogbe yii fẹnu ko oun leti to si ni, ‘’Ẹru si n ba mi’. O ni baba tun pe orukọ oun lẹkẹẹji, bẹẹ lo tun ni ‘ẹru si n ba mi’
Boya ẹru iku naa waa ni tabi nnkan mi-in, baba ko la a, afi bi wọn ṣe dagbere faye lẹyin oṣu kan ati ọjọ kan ti ayẹyẹ nla naa waye.

Leave a Reply