‘Eyi ni bi pasitọ ti gbogbo ẹbi mi fọkan tan ṣe fipa ba ọmọ mi lajọṣepọ fodidi ọdun mẹta’

Monisọla Saka

Ni ile-ẹjọ to n ri si ẹsun ifipabanilopọ atawọn iwa ọdaran abẹle to wa niluu n’Ikẹja, nipinlẹ Eko, ni obinrin oniṣowo kan ti n ṣalaye pẹlu imi ẹdun lori bi Pasitọ ijọ wọn, Chris Mcdouglas, ṣe fipa ba ọmọ ẹ ti ko ju ọmọọdun mẹtadinlogun lọ lajọṣepọ fun odidi ọdun mẹta.

Obinrin yii ṣalaye pe laarin ọdun 2017 si ọdun 2020, ni olujẹjọ yii fi n ba ọmọ oun sun laimọye igba, iyẹn lẹyin to ba ti tan oun pe awọn n jade lọ fun iṣẹ ihinrere.

O ni lẹyinkule ṣọọṣi, otẹẹli kaakiri loriṣiiriṣii ati inu ile oun funra oun, ni Pasitọ Mcdouglas ti ba ọmọ oun lajọṣepọ ri.

Iyaale ile yii ni nigba toun gbọ ọrọ yii ti oun si lọọ ba olujẹjọ lori rẹ, niṣe lo bu sẹkun gbaragada, to ni iṣẹ eṣu ni.

“Pasitọ Mcdouglas maa wa sile mi lati waa pe ọmọ mi pe kawọn jọ lọọ waasu, ko le baa lo ẹbun ẹ gẹgẹ bii akọrin ijọ lati gbadura fawọn yooku.

‘‘Ọmọ mi ṣalaye fun mi pe niṣe ni pasitọ maa mu oun ya lotẹẹli lati ba oun sun. Nigba ti emi ati awọn alagba ijọ wa kan lọọ koju rẹ pẹlu awọn ẹsun yii, o ni satani lo tan oun jẹ, pe ki n jọọ, ki n dariji oun. Gbogbo ọrọ temi ati olujẹjọ sọ lọjọ naa ati gbogbo bo ṣe jẹwọ ẹṣẹ ni mo ka sori foonu mi”.

“Pasitọ ti mo fọkan tan pẹlu gbogbo ẹbi mi, ti mo si tun ri i bii baba mi ninu Oluwa, lo n ba ọmọ mi lajọṣepọ. Ọmọ mi tun ni pasitọ maa yọ wọle to ba ti ri i pe mi o si nile, yoo fa kọtinni ko le di pa daadaa, yoo waa dawọ bo oun lẹnu, yoo si bẹrẹ si i fagidi maa ba oun lo pọ. Ọmọ mi ni ọpọ igba ni pasitọ maa pe oun wa sile pe ki oun waa ba awọn ọmọ rẹ fọṣọ, yoo si tun pada fipa ba oun sun nibẹ ni “.

Obinrin oniṣowo yii ni gbogbo awọn ibalopọ laarin olujẹjọ at’ọmọ oun yii ti ko ọmọ naa sinu ironu to lagbara, to si maa n jẹ ko daku nigba mi-in. Ati pe ni gbogbo igba tọmọ oun ba ti daku, pasitọ yii naa loun maa tun sare pe pe ko waa gbadura fun un o. Lẹyin naa ni yoo sọ foun pe koun ṣe itọrẹ aanu nitori ọmọ oun yii.

“Lọpọ igba lo jẹ pe owo-oṣu mi ni mo fi maa n sanwo ọrẹ gẹgẹ bi pasitọ ṣe maa n gba mi niyanju. Ko si sigba kan ti ki i ko ibẹru sọmọ yii lọkan pe ọjọkọjọ to ba lanu ẹ sọ fun ẹda alaye kankan, o maa ku ni”.

Mcdouglas yii ni oluṣọaguntan nile ijọsin Peculiar Generation Assembly Church, to wa nipinlẹ Eko.

Ẹsun mẹsan-an ọtọọtọ ni wọn fi kan pasitọ to n ba ọmọ to le bi ninu ara rẹ naa lo pọ. Lara rẹ ni pe oun lo sọ ọmọ naa di obinrin nitori oun lo ja ibale rẹ. Bẹẹ ni wọn fẹsun ifipabanilopọ fun odidi ọdun mẹta kan an.

Gẹgẹ bi Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, ṣe sọ, pasitọ naa ni oun ko jẹbi. Ṣugbọn wọn mu ohun ti wọn ka silẹ bii mẹfa, to jẹ itakurọsọ laarin ẹlẹrii ati olujẹjọ kalẹ gẹgẹ bii ẹri niwaju ile-ẹjọ.

Lasiko ti agbẹjọro olupẹjọ, Ọgbẹni Suleiman Salami, pe ẹlẹrii kan sita, obinrin naa ṣalaye fun kootu pe oun ti mọ olupẹjọ lati bii ọdun mejila o le sẹyin, ati pe o ti to ọdun mẹwaa tọkọ ẹ ti rinrin-ajo kuro lorilẹ-ede Naijiria. O ni olujẹjọ maa n gbowo lọwọ mọlẹbi obinrin oniṣowo ọhun, ti ko si ṣe anfaani kankan to jẹ mọ owo fun wọn ri.

O ni ọmọbinrin ti pasitọ n fipa ba lo pọ yii naa ni akọbi olupẹjọ lobinrin.

Insipẹkitọ Akikuowo Omiere, iyẹn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ to jẹ ẹlẹrii olupẹjọ ṣalaye fun kootu pe lọjọ karundinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2020, ni ọrọ olujẹjọ to fipa ba ọmọ ijọ ẹ, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, lajọṣepọ de etiigbọ awọn.

O ni lasiko iwadii lọmọbinrin naa sọ pe oun ko ti i mọ ọkunrin ṣaaju igba naa, ati pe esi ayẹwo ti wọn ṣe fọmọ naa nileewosan Mirabel Medical Centre, ti wọn fi han oun fidi ẹ mulẹ pe wọn ni ibalopọ gidigidi pẹlu ọmọ naa.

Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ Ramon Oshodi, ti sun igbẹjọ si ọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun yii.

Leave a Reply