Eyi ni bi wọn ṣe yinbọn pa ṣọja ati araalu kan ninu ija aṣọbode pẹlu onifayawọ n’Igboọra

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan meji, soja kan pẹlu ọmọ ogun orileede yii kan lo ku, nigba ti awọn aṣọbode atawọn onifayawọ oniṣowo dana ibọn funra wọn ya niluu Igboọra, nipinlẹ Ọyọ.

Yatọ si awọn meji to padanu ẹmi wọn nífọnná-fọnṣu, ọpọ eeyan lo fara gbọta ibọn ninu iṣẹlẹ yii, bẹẹ lọpọlọpọ ọlọkada tibẹ padanu alupupu wọn.

Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, la gbọ pe yanpọnyanrin ọhun bẹ silẹ nigba tawọn onifayawọ kọ lati duro fun awọn agbofinro to fẹẹ gbowo ibode lori ẹru ti wọn n ko bọ lati ilẹ okeere sapo ijọba, ti ọrọ naa si di ohun ti wọn n tori ẹ dana ibọn ranṣẹ sira wọn.

Olugbe Igboọra kan to firoyin yii to ALAROYE leti fidi ẹ mulẹ pe “Ibọn ti ọkan ninu awọn aṣọbode yin lo ba ọkan ninu awọn ṣọja to wa laarin wọn. Ṣẹ ẹ mọ pe gbogbo awọn agbofinro ni wọn jọ n ṣiṣẹ papọ lẹyin iwọde ti awọn ọdọ ṣe ta ko awọn sáàsì laipẹ yii. Awọn soja, aṣọbode, ọlọpaa atawọn sifu-difẹnsi naa ti darapọ mọ awọn kọsitọọmu ti wọn n gbowo bode kiri bayii.

“Ọkan ninu awọn onifayawọ ni kọsitọọmu kan fẹẹ yinbọn mọ ti ibọn fi ba ọkan ninu awọn ṣọja to wa laarin wọn. Ibọn ṣeeṣi ba araalu kan naa. Wọn ni loju ẹsẹ lawọn mejeeji ti ku.

“Ibọn ba ṣọja kan naa lẹsẹ ṣugbọn iyẹn ko ku ni tiẹ, ileewosan lo wa bayii to n gba itọju, adura ti a n ṣe fun un bayii ni pe k’Ọlọrun fun un lalaafia.

“Iṣẹlẹ yii lo ṣokunfa sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ atawọn ohun irinsẹ mi-in loju ọna to so Igboọra pọ mọ awọn ilu mi-in. Ọpọlọpọ ọlọkada ko si ti i tẹ́rú to n ṣiṣẹ bayii nitori mimu lawọn agbofinro n mu wọn, ti wọn n gba ọkada wọn lọwọ wọn. Aimọye iru ọkada bẹẹ la ri ti awọn agbofinro n gbe kọja lati Ọjọruu, Wẹsidee.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE, Alukooro ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ fakọroyin wa pe. Lẹfutẹnanti ṣọja kan ati ọkan ninu awọn ikọ ti wọn jọ n daabo bo bode ni wọn jọ ni ede-aiyede ti ibọn fi ba ṣọja yẹn.

“Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, atawọn iṣọmọgbe rẹ ti lọ sibẹ lati lọọ ṣewadii. A ṣi n ṣewadii lọwọ lati mọ nnkan to ṣẹlẹ nibẹ ati ohun to fa ede-aiyede yẹn ni, ka le mọ ba a ṣe maa yanju ọrọ yii ati ọna ta a le gba dẹkun iru iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju.”

Leave a Reply