Eyi ni bi wọn ṣe pa awọn obinrin meji laarin ọjọ kan ṣoṣo l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ki i ṣe ibẹru kekere niṣẹlẹ iku awọn obinrin meji kan ti wọn da ẹmi wọn legbodo laarin oru ọjọ Aje, Mọnde, mọju ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ta a wa yii, da sọkan awọn eeyan ilu Akurẹ.

Awọn eeyan olugbe Ajipowo/Ogundipẹ, ni wọn kọkọ ṣakiyesi oku ọmọbinrin kan ti wọn wọ si ṣọọbu wẹda kan lagbegbe naa laaarọ kutukutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.

Ni ibamu pẹlu alaye ti ọkan ninu awọn to mọ nipa iṣẹlẹ naa ṣe fun wa, o ni ipo ti awọn ba oku ọmọbinrin ọhun fihan pe ṣe lawọn amookunsika naa kọkọ fipa ba a lo pọ ki wọn too fun un lọrun pa.

Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ awọn ọmọ ‘Yahoo’ ni wọn lo obinrin ti ko ti i sẹni to mọ ile ati ọna rẹ ọhun fun etutu ọla, ti wọn si wọ oku rẹ si ṣọọbu ẹni ẹlẹni lẹyin ti wọn ti lo ohun ti wọn fẹ lo lara rẹ tan.

Iṣẹlẹ ọhun lo ni awọn araadugbo ti fi to awọn ọlọpaa leti ki wọn le tete gbe igbesẹ to yẹ nipa rẹ.

Alẹ ọjọ kan naa ni wọn lawọn agbebọn kan tun ṣọṣẹ laduugbo Kajọla, lagbegbe Ọda, nibi ti wọn ti yinbọn pa obinrin oniṣowo kan ti wọn porukọ rẹ ni Funmi Fọlọrunṣọ.

Wọn ní ṣe lawọn agbanipa naa dena de obinrin naa lẹnu geeti ile wọn, bẹẹ ni wọn ko ti i jẹ ko raaye sọkalẹ ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ ti wọn fi da ibọn bo o.

Oloogbe ọhun ni wọn lo jẹ iyawo ọkan ninu awọn oloye ẹgbẹ awakọ NURTW ipinlẹ Ondo.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori tiṣa to na ọmọleewe to fi ku l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko Afaimọ ni tiṣa ti wọn porukọ rẹ ni Ọgbẹni Stephen yii ko …

Leave a Reply

//dooloust.net/4/4998019
%d bloggers like this: