Eyi ni bi wọn ṣe sin Ọba Satani,ọkunrin to niyawo mejidinlọgọta pẹlu mọto nla

Ọjọ kẹrinla, oṣu kejila, ọdun 2021 ni ọkunrin kan tawọn eeyan mọ si Ọba Satani, jade laye. Oun ni babalawo naa to fẹyawo mejidinlọgọta (58), to bimọ ọọdunrun ( 300)

Nigba ti wọn fẹẹ sinku rẹ lọsẹ to kọja yii, mọto ayọkẹlẹ bọginni kan ni wọn kọkọ gbe sinu koto ti wọn fẹẹ sin in si i, ori mọto naa ni wọn si ṣẹṣẹ waa gbe posi ti oku wa ninu rẹ le, ni wọn ba gbe baba rele o. Ẹni  ọdun mẹrinlelaaadọrin ( 74) ni.

Yatọ si pe wọn tan ina mọto naa silẹ, to n ṣiṣẹ lai kuro loju kan ninu koto naa, wọn tun gbe orin jẹlẹnkẹ kan ti Ọba Satani fẹran si i fun un pe ko maa gbọ ọ lọ ninu irin-ajo rẹ si isalu ọrun.

Gbogbo eyi ko deede ri bẹẹ nibi isinku to waye nipinlẹ Enugu ti ọkunrin alaya pupọ naa ti wa, ọmọ rẹ, Uchenna, ṣalaye pe aṣẹ baba oun niyẹn ko too ku, awọn si gbọdọ mu aṣẹ rẹ ṣẹ bo ṣe wi ni.

Babalawo to gbowọ buruku ni wọn pe Ọba Satani yii nigba to wa laye, bo si tilẹ jẹ pe Simon Odo lorukọ abisọ rẹ, ko sẹni ti i pe e bẹẹ mọ, Ọba Satani ni gbogbo aye mọ ọn si nitori orukọ to sọ ara rẹ niyẹn.

Ọkunrin ọmọ ilu Aji, nijọba ibilẹ Ariwa Igbo-Eze, nipinlẹ Enugu, naa ti figba kan ṣalaye idi rẹ to fi fẹyawo mejidinlọgọta.

Ohun to sọ ni pe oun koriira kobinrin maa fi abuku kan oun, ọpọlọpọ iwa awọn obinrin asiko yii ko si daa. Ọba Satani sọ pe bi ọkunrin mẹwaa ba ku ni Naijiria yii, marun-un pere ni iku wọn ti ọdọ Ọlọrun wa, awọn iyawo lo pa mẹẹẹdogun yooku, nibi iwakiwa to le ko ironu ati ibanujẹ ba ọkọ wọn si ni.

O waa ni bẹẹ lo ri lọdọ toun naa, bi iyawo kan ba ti huwa abuku tabi to fi ibanujẹ kan oun bayii, oun yoo fẹ omi-in le e lati fi rọpo rẹ ni, koun fi dun ara oun ninu. O ni ohun to jẹ koun fẹ wọn de ori mejidinlọgọta niyẹn.

Bi wọn ṣe waa sin in pẹlu mọto ayọkẹlẹ yii, ohun tawọn eeyan rẹ n sọ ni pe bo ti fẹran aye jijẹ nigba to wa laye naa lo tun fẹẹ jaye de ajule ọrun.

Leave a Reply