Eyi ni bi wọn ṣe tẹ Yinka Odumakin nitẹẹ ẹyẹ l’Ekoo, awọn eeyan sọrọ iwuri nipa rẹ

Adefunkẹ Adebiyi

Ka ku lọmọde ko yẹ ni, o san ju keeyan dagba ko ma ni adiẹ irana lọ. Bẹẹ lawọn eeyan n wi l’Ọjọbọ, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin yii, nigba ti wọn tẹ Oloogbe Yinka Odumakin, ogbontarigi ajẹfẹtọọ ọmọ Yoruba nni, ni itẹ ẹyẹ si ọgba awọn ọlọpaa to wa n’Ikẹja, l’Ekoo, ti gbogbo aye waa n sọ ohun ti wọn mọ nipa ẹ, ti wọn n ṣedaro lẹyin ọmọ Odumakin.

Ohun ti ọpọ eeyan kọkọ ṣakiyesi, ti wọn si n sọ nipa oku ọmọ bibi ilu Moro, nipinlẹ Ọṣun yii, ni pe niṣe lo mọ tonitoni. Ko tilẹ jọ pe o ti ku rara, bii pe o sun lo ri ninu posi ti wọn tẹ ẹ si, ti wọn si de fila rẹ fun un bo ti maa n de e nigba to wa laye gan-an.

Awọn eeyan pataki lagbo oṣelu, bẹrẹ lati ori Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, Gomina Ondo tẹlẹ, Oluṣẹgun Mimiko, Alagba Ayọ Adebanjọ, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, Amofin agba Fẹmi Falana, Tokunbọ Afikuyọmi, Jimi Agbaje ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn wa nibi eto naa, ti kalulu wọn sọrọ iwuri nipa Yinka Odumakin.

Gbangba loju gbogbo ero ni Baba Ayọ Adebanjọ to jẹ olori ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ ti bu sẹkun nigba to n sọrọ nipa Oloogbe Odumakin. Baba naa ṣalaye bo ṣe jẹ pe adanu nla ni iku Yinka jẹ, ati bi yoo ṣe ṣoro lati gbagbe rẹ laarin Afẹnifẹre ati Yoruba patapata.

Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, sọ nibẹ pe Odumakin ko di ipo oṣelu mu, ṣugbọn iyi to gba ati bawọn eeyan ṣe mọ ọn ju ti oloṣelu lọ.

Gomina Sanwo-Olu naa kin eyi lẹyin, o sọ nipa bi Odumakin ṣe ti n ba ijangbara bọ nigba to ti wa nileewe Yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ, ti ko si ṣiwọ titi to fi di pe ọlọjọ de. Koda, gẹgẹ bii akọroyin, Gomina sọ pe Oloogbe Odumakin ya ara ẹ sọtọ, o si ṣiṣẹ naa debi to lapẹẹrẹ.

Nigba ti eto fẹẹ maa kasẹ nilẹ ni wọn pe iyawo oloogbe lati waa sọrọ. Obinrin naa,Ọmọwe Joe Okei Odumakin, ya ọpọ eeyan lẹnu pẹlu bo ṣe sọrọ iwuri pupọ nipa ọkọ ẹ, ti ko si sunkun kan bayii.

Obinrin naa ṣalaye nipa bo ṣe pade ọkọ ẹ lọgba ẹwọn Alagbọn, bo ṣe jẹ pe ijijagbara lawọn jọ n ba ka titi ti opin fi de yii, ati bo ṣe jẹ pe ọdun mẹrinlelogun lawọn fi jẹ tọkọ-taya.

Iyawo Odumakin loun ko gba pe ọkọ oun ku, o ni ni gbogbo igba to wa ni mọṣuari, oun maa n lọọ wo o nibẹ, oun maa n ba a sọrọ boya yoo tiẹ ji, ṣugbọn ko ri bẹẹ mọ.

‘To ba waa jẹ pe aye mi-in tun wa lẹyin eyi, abi teeyan ba tun n pada wa saye, ‘Yinka, iwọ ni mo tun fẹẹ fẹ, iwọ ni mo fẹẹ ba lo igbesi aye mi lẹẹkan si i’’

Bẹẹ ni iyawo oloogbe wi, to si fi orin ijijagbara ti wọn jọ maa n kọ kadii ọrọ rẹ nilẹ, ti gbogbo awọn to wa nibẹ si n ki i pe o kuu jijẹ akin obinrin.

Leave a Reply