Eyi ni bile-ẹjọ ṣe tun fọgbọn de awọn ọmọ ẹyin Sunday Igboho mọlẹ l’Abuja

Faith Adebọla

Ki i ṣe iroyin tuntun mọ pe ile-ẹjọ giga apapọ kan niluu Abuja ti fun awọn ọmọ ẹyin gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmọ, ni beeli, ṣugbọn titi di ba a ṣe n sọ yii, awọn eeyan naa ko ti i kuro lahaamọ awọn ẹṣọ ọtẹlẹmuyẹ DSS, bẹẹ lawọn kan n sọ pe bile-ẹjọ ṣe gba oniduuro wọn yii lọwọ kan arumọjẹ ninu, wọn niṣe nijọba tun gbọna mi-in de awọn eeyan naa mọlẹ sahaamọ.

Adajọ Obiora Egwuatu lo paṣẹ gbigba oniduuro awọn mejila ọhun lẹyin ti wọn ti wa lahaamọ, labẹ ipo ti ko bara de fun ọjọ mẹtadinlogoji gbako. Lati ọjọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdun yii, ni wọn ti mu awọn mejila yii sahaamọ awọn DSS (Department of State Security) lasiko ti wọn lọọ ṣakọlu sile Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, lọganjọ oru ọjọọ kin-in-ni, oṣu keje, ọdún yii, nile rẹ to wa ni Soka, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.

Miliọnu marun-un naira ni wọn fi gba beeli mẹjọ ninu wọn, pẹlu oniduuro meji to n gbe niluu Abuja. Nigba ti wọn gba beeli awọn mẹrin to ku ti ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni awọn ko ni i fi silẹ nitori pe awọn fura si wọn pe wọn n ko nnkan ija oloro, wọn si tun jẹ ọdaran ni miliọnu mẹwaa naira ẹni kọọkan.

Awọn oniduuro yii gbọdọ maa gbe ilu Abuja, ki ọkan ninu wọn jẹ oṣiṣẹ ijọba to wa ni ipele kejila soke. Bakan naa ni awọn eeyan naa gbọdọ pese iwe igbaniṣiṣẹ wọn ati iwe ti wọn fi sanwo-ori ni ọdun mẹta sẹyin.

Agbẹjọro awọn DSS, Ọgbẹni Idowu Awo, sọ nile-ẹjọ naa pe oun ko ta ko fifun awọn mẹjọ naa ni beeli, tori iṣẹ iwadii tawọn ọtẹlẹmuyẹ ṣe fihan pe diẹ ni ti Alaba awọn wọnyi ninu ibeji, lori ẹṣun kiko nnkan ija ogun pamọ ati hihuwa ọdaran ti wọn tori ẹ mu wọn, wọn ni ọrọ naa ko fi bẹẹ kan wọn pupọ.

Awọn mẹjọ tọrọ yii kan ni Abdulateef Ọnaọlapọ, Tajudeen Erinoye, Diẹkọla Jubril, Ayọbami Donald, Adelabu Uthman, Kazeem Raji, Bamidele Sunday ati Kunle Oluwafẹmi.

Ni ti awọn mẹrin tileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lawọn ko ni i fi silẹ, Idowu Awo sọ pe o lewu lati yọnda beeli fun wọn tori awọn mẹrin ọhun le di eto aabo ati igbẹjọ to n lọ lọwọ yii, lọwọ, wọn si le gbẹyin bẹbọ jẹ, bo tilẹ jẹ pe Agbẹjọro Sunday Igboho to ṣaaju awọn agbejọro mi-in lati ṣoju fawọn eeyan wọnyi ni kootu ta ko ẹbẹ DSS, o ni kile-ẹjọ maa feti si lọọya wọn, tori awawi lasan ni ọrọ to fẹẹ fi gbegi dina fawọn onibaara oun.

Awọn mẹrin ti wọn o fẹẹ tu silẹ ni Amudat Babatunde, Ọkọyẹmi Tajudeen, Abideen Shittu ati Jamiu Noah Oyetunji.

Ṣugbọn ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Egwuatu sọ pe adajọ ni anfaani labẹ ofin lati lo ọgbọn-inu rẹ lori ẹjọ to ba jẹ mọ bẹẹ lati fun awọn eeyan yii ni beeli, ko si pọn dandan foun lati tẹle ohun ti agbejọro eyikeyii ba sọ.

Aṣẹ yii lo mu ki ọpọ awọn ololufẹ Sunday Igboho ati awọn mọlẹbi awọn eeyan mejila naa bẹrẹ si dunnu pe ko ni i pẹ rara tawọn maa tun ri awọn eeyan awọn, bẹẹ lawọn ajijangbara ilẹ Yoruba to n ṣatilẹyin fun igbesẹ Sunday Igboho lori idasilẹ ‘Yoruba Nation’ naa n reti itusilẹ wọn lahaamọ DSS.

Ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ mọ. Niṣe lo da bii pe ile-ẹjọ naa dọgbọn da agbado silẹ fun adiẹ, wọn si tun gbe ọpa soke lọrọ naa ri. Ọgbẹni Pẹlumi Ọlajẹngbesi sọ fawọn oniroyin pe lọjọ keji toun lọ si kootu naa, ni ẹka ti wọn ti maa n ṣeto beeli, o ni alaye ti wọn ṣe foun tun yatọ patapata si ohun toun feti ara oun gbọ lasiko ti igbẹjọ waye.

O ni: “Mo ti wa awọn oniduuro mẹrin pẹlu owo ati awọn nnkan mi-in tile-ejọ sọ, ka tọwọ bọwe lo ku, ni wọn ba n ṣalaye fun mi pe ohun ti Adajọ ni lọkan ni pe a gbọdọ wa oniduuro meji meji ọtọọtọ fun ọkọọkan awọn afurasi naa, leyii to tumọ si pe ile-ẹjọ fẹ ka wa oniduuro mẹrinlelogun (24) dipo mẹrin ta a ti fọkan si.

Ẹka to n ṣiṣẹ lori beeli sọ fun mi pe awọn ṣẹṣẹ lọọ beere alaye lẹkun-un-rẹrẹ si i lọwọ Adajọ Obiora ni, wọn ni alaye to si ṣe fawọn niyẹn.

Niṣe la tun bẹrẹ si i parọwa si awọn ọmọ Yoruba to wa l’Abuja, paapaa awọn tinu wọn dun si igbesẹ ominira ti Sunday Igboho n wa fun ilẹ Yoruba, lati ṣaanu wa lori ẹjọ yii, ki wọn le ṣe oniduuro fawọn afurasi wọnyi.

Yatọ siyẹn, to ba jẹ a ti mọ pe bọrọ ṣe maa ri niyi ni, a ba ti rọ ilẹ-ẹjọ lati paṣẹ kiko awọn afurasi naa kuro lakata ati ahamọ awọn DSS, boya ki wọn fi wọn sọgba ẹwọn Abuja na, titi ti a fi maa kaju beeli, tori awọn eeyan yii royin pe iya buruku lawọn n jẹ lọwọ awọn DSS ọhun.”

Ṣugbọn Ọlajẹngbesi ni ireti wa pe awọn maa ri eeyan mẹrinlelogun ati iye owo tile-ẹjọ sọ, laipẹ. O lawọn afẹnifẹre ẹda kan ti dide labẹnu lati ṣeranwọ.

Bakan naa, Olori ẹgbẹ Afẹnifẹre nilẹ wa, Oloye Ayọ Adebanjọ, ti koro oju si ibeere ile-ẹjọ pe ki wọn wa oniduuro mẹrinlelogun ati iye owo tuulu tuulu, miliọnu marun-un marun-un naira lọna

Leave a Reply