Jọkẹ Amọri
O jọ pe omi ti ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP foju rena ti fẹẹ maa gbe wọn lọ bayii pẹlu bi ẹgbẹ oselu Labour ṣe tun n lewaju ni awọn ibudo idibo kan nipinlẹ Eko, nibi ti ẹgbẹ APC ti n ṣejọba.
Ni ọpọlọpọ agbegbe ibudo idibo ni Lẹkki, oludije funpo aarẹ ẹgbẹ Labour lo n rọwọ mu ju lọ nibẹ. Lara awọn agbegbe ti wọn ti ka, to si jẹ Peter Obi lo n lewaju ni ibudo idibo 035, 005 ati 005. Ni ibudo idibo mẹtẹẹta yii, Peter Obi ni ibo ẹgbẹrin le laaadọta(850), nigba ti ẹgbẹ APC ni ibo mẹtadinlogun, ti ẹgbẹ PDP si ni ibo marun-un pere.
Ọrọ ko si fi bẹẹ yatọ ni ibudo idibo Ilasan, Jakande ati Mopol Zone, ẹgbẹ Labour ti Peter Obi naa lo lewaju. Ibo mẹta lelaaadọwaa (193) ni Obi ni, ẹgbẹ APC ni ibo mẹtadinlọgọta (57), ti ẹgbẹ PDP ko si ni nnkan kan.
Bakan naa lọmọ ṣori lawọn esi ibo to jade ni ibudo idibo 046, Wọọdu E1, ni Mazamaza, nijọba ibilẹ Amuwo Ọdọfin, ẹgbẹ oṣelu Labour ni ibo mọkandinlaaadọsan-an (169) ẹgbẹ APC ni ibo mejilelọgbọn (32), nigba ti PDP ni ibo ọgọrin (80).
Bẹẹ naa lọrọ ri ni Wọọdu E1, to wa ni Benster Crescent, ni Mazamaza, l’Amuwo Ọdọfin. Labour ni ibo to fi marun-un din ni igba (195), ẹgbẹ APC ni ibo meji (2), nigba ti PDP ni ẹyọ kan (1)
Ẹgbẹ Peter Obi naa lo lewaju ni Yuniiti kejilelaaadọfa, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, ni Ogudu, pẹlu ibo mẹtadinlọgọta (57), ti APC si ni ibo mẹsan-an, PDP ni ibo ẹyo kan pere.