Eyi ni idi ti mi o fi le sọtan igbesi aye mi- Ibrahim Babangida 

Bi ayẹyẹ ominira ọgọta ọdun Naijiria si ṣe n tẹsiwaju, aarẹ orilẹ-ede yii nigba kan, Ibrahim Babangida, ti tu aṣiri ohun to fa a ti iwe itan igbesi aye ẹ, ati bo ṣe ṣejọba Naijiria ko ṣe ti i jade.

Babangida sọ pe o pẹ ti oun ti n ko iwe itan oun jade, ṣugbọn ẹru ile-ẹjọ to ṣee ṣe ki awọn eeyan kan wọ oun lọ gan-an lo n ba oun ti iwe naa ko fi ti i jade.

Lọdun 1985 ni Ibrahim Babangida gbajọba lọwọ Aarẹ Muhammed Buhari to wa nipo aarẹ alagbada bayii. Ọkunrin aloku ṣoja yii ṣi wa nipo ọhun titi di ọdun 1993, ko too gbe e fun ijọba fidi-hẹẹ.

Ninu awọn aarẹ orilẹ-ede yii ti awọn ọmọ Naijiria yoo nifẹẹ si lati ka itan igbesi aye ẹ ni ọkunrin ologun yii, ṣugbọn Babangida ti sọ pe ko si ki awọn eeyan ma gbe oun lọ sile-ẹjọ, nitori pe o ṣee ṣe ki awọn eeyan kan ṣi oun gbọ, tabi ki wọn sọ pe oun ko kọ nipa awọn bi ọrọ ṣe jẹ gan-an.

Babangida ni, ti eyi ba waye, o ṣee ṣe ki oun maa pooyi kootu, bẹe lawọn le fa a fun ọdun marun-un.

Lori tẹlifiṣan kan lo ti sọrọ yii nigba ti wọn n bi leere nipa ipo ti Naijiria wa loni-in.

Babangida fi kun ọrọ ẹ pe ti oun ko ba lanfaani lati ṣe e nigba aye oun, awọn ọmọ oun le ṣe e daadaa lọjọ iwaju.

Bakan naa ni aarẹ tẹlẹ yii ti sọ pe ki ẹnikẹni ma ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn ṣoja pe awọn ni wọn ba ijọba Naijiria jẹ. O ni loootọ ni ṣoja ṣe olori orilẹ-ede yii daadaa, ṣugbọn pupọ ninu awọn ileeṣẹ ijọba, awọn alagbada lo n dari ẹ.

O ni ti a ba ri ibi to ti ku diẹ kaato, ko ni i dara ti awọn eeyan ba n naka aleebu ẹ si ijọba ṣoja, nitori awọn araalu ti wọn jẹ alagbada gan-an lo n dari pupọ ninu ileeṣẹ ijọba.

 

Leave a Reply