Eyi ni idi ti mo fi da awọn kọmiṣanna mi silẹ-Makinde

Faith Adebọla

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde tu igbimọ to n ba a ṣiṣẹ ka, to si ni ki awọn kọmiṣanna mẹtadinlogun, olori awọn oṣiṣẹ atawọn kan lọọ rọọkun nile.

Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin rẹ, Taiwo Adisa, fi sita lo ti sọ pe o ṣe pataki lati paarọ awọn to ti n ba a ṣiṣẹ yii lati faaye gba awọn mi-in.

Lẹyin ipade awọn ọmọ igbimọ yii ti wọn ṣe ni ikede naa waye.

Makinde dupẹ lọwọ awọn eeyan  ipinlẹ Ọyọ ati awọn to ba a ṣiṣẹ yii fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, bẹẹ lo gbadura aṣẹyọri fun wọn ninu gbogbo idawọle wọn yooku.

Ninu oṣu kẹjọ, ọdun, ọdun 2019 yan awọn eeyan naa sipo.

Leave a Reply