Eyi ni idi ti wọn o ṣe ti i fi Sunday Igboho silẹ ni Kutọnu

Faith Adebọla

 Pẹlu bo ṣe ku ọjọ diẹ ko pe oṣu mẹrin gbako ti gbajugbaja ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, ti wa lahaamọ ẹwọn lorileede Olominira Benin, ọkan ninu awọn aṣaaju Agbẹjọro rẹ, Amofin Agba Yọmi Aliu, ti ṣalaye idi ti wọn o ṣe ti i fi ọkunrin oniṣowo naa silẹ lahaamọ.

Ninu ọrọ kan to ba akọroyin iweeroyin Vanguard sọ lọjọ Abamẹta, Satide, to kọja yii, Aliu ṣalaye pe ki i ṣe nitori ẹjọ tabi ẹsun ọdaran eyikeyii ni wọn ṣe tori ẹ da Sunday Igboho duro siluu Kutọnu, lorileede Bẹnẹ, ti wọn o si tu u silẹ, tabi gbọ ẹjọ rẹ, o lọkunrin naa ko ni ẹjọ kankan lati jẹ lorileede ọhun.

“Igboho ṣi wa ni Kutọnu, ko lẹjọ kankan i jẹ lori ọrọ Naijiria rara, ko si ẹsun kankan lọrun ẹ titi di bi mo ṣe n sọrọ yii. Pasipọọtu arinrinajo ECOWAS lo fi wọ Kutọnu, ofin ECOWAS si faaye gba ẹnikẹni to ba niwee wọn, tabi pasipọọtu wọn lọwọ, lati duro tabi gbe nibikibi ti aṣẹ ajọ ECOWAS ba nasẹ de, orileede Benin ṣi wa lara wọn, tori naa, Sunday Igboho ko rufin kan to le mu ki wọn da a duro sibi to wa yẹn.

Ṣugbọn gẹgẹ bi mo ṣe maa n sọ tẹlẹ, Naijiria ni ko jẹ ki wọn ti fi i silẹ, Naijiria lo n paṣẹ ohun ti wọn fẹ ki orileede Kutọnu ṣe lori ẹ fun wọn, bii ọkan lara awọn ipinlẹ Naijiria ni Kutọnu ri sijọba wa. Wọn o le ba a ṣẹjọ ni Kutọnu tori ko dẹṣẹ kan nibẹ, ijọba si ti wa gbogbo ọna ti wọn aa fi gbe e pada wale, ṣugbọn ko ṣee ṣe.

Igbagbọ ati ireti wa ni pe wọn maa fi i silẹ laipẹ, tori ijọba Naijiria ti lawọn maa fi ọgbọn oṣelu yanju ọrọ oun ati ti Nnamdi Kanu, a o si lodi si i ti wọn ba ṣe bẹẹ, ṣugbọn toju tiyẹ laparo wa fi n riran lori ọrọ naa.”

Olori ẹgbẹ awọn to fẹẹ ya kuro lara Naijiria, ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Ọjọgbọn Banji Akintoye, naa sọ pe ijọba Naijiria ni ko jẹ ki wọn ti tu Oloye Sunday Adeyẹmọ silẹ.

Ninu atẹjade kan ti Agbẹnusọ rẹ, Kọmureedi Adelẹyẹ Maxwell, fi lede lopin ọsẹ yii lori ibi ti nnkan de duro lori ọrọ ọkunrin naa, Akintoye ni “bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, ko si ẹsun kan, ko si iwe ẹsun tabi ẹṣẹ kan pato, bẹẹ ni a o ri iwe pe ijọba Naijiria fẹ ki wọn gbe e pada wale.

Ilana idajọ orileede Bẹnẹ yatọ gedegede si ti Naijiria, adajọ to paṣẹ ahamọ fun Sunday Igboho ki i ṣe adajọ to n gbọ ẹjọ, adajọ oluṣewadii ni, o ni ko wa nibẹ koun fi pari iwadii toun n ṣe, wọn lawọn n wadii lati mọ idi to fi wa lorileede awọn tabi idi to fi fẹẹ gba ibẹ kọja, boya niṣe lo fẹẹ da wahala kan silẹ fawọn. A ti lero pe titi ipari oṣu kẹwaa, gbogbo ẹ yoo ti yanju, ṣugbọn oṣu kọkanla lo tun ti n lọ yii. Ṣugbọn nibi ti a ba iṣẹ de nibi, ọkan wa balẹ pe Oloye Sunday Igboho maa dẹni ominira laipẹ.

Ni ti ọrọ ijijagbara tabi yiya kuro lara orileede Naijiria, ko si biboju wẹyin o, arọni o wale, Onikoyi o sinmi ogun ni o, ajọṣe ilẹ Yoruba pẹlu Naijiria gbọdọ dopin ni, ajọṣe yii o ṣe wa lanfaani kan lati igba pipẹ, o si da mi loju pe o maa dopin laipẹ pẹlu,” bẹẹ ni Ọjọgbọn ẹni ọdun mẹrindinlaaadọrun naa sọ.

Leave a Reply