Eyi ni ileri ti Akala ṣe fun mi ko too ku- Makinde

Ọlawale Ajao, Ibadan

‘‘Ọtunba Adebayọ Alao-Akala, gomina ipinlẹ Ọyọ to doloogbe ti iṣeleri lati ṣiṣọ loju atunṣe ọna Ogbomọṣọ siluu Isẹyin, nigba ti ijọba ba fẹẹ bẹrẹ iṣẹ lori rẹ.’’

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo sọrọ yii lasiko abẹwo ibanikẹdun to ṣe si mọlẹbi oloogbe naa niluu Ogbomọṣọ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Makinde, ẹni to ṣapejuwe Akala gẹgẹ bii ẹgbọn, adari ati olutọnisọna, ṣalaye pe loootọ loun pẹlu gomina tẹlẹ yii ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa, sibẹ, ọpọ igba lọkunrin ọmọ bibi ilu Ogbomọṣọ naa ti fi iriri to ni nipa eto iṣelu tọ oun sọna.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A ṣi sọrọ nijarun-un (ọjọ mẹta ṣaaju iku Akala). Mo sọ fun ẹnikan pe Ọtunba Akala ni mo fẹ ko waa ṣi aṣọ loju eto yẹn nigba ta a ba fẹẹ kede ibẹrẹ iṣẹ atunṣe ọna Ogbomọṣọ siluu Isẹyin. Ẹni yẹn gba mi nimọran pe ki n ma dan an wo, nitori Akala maa sọ ọ dọrọ oṣelu mọ mi lọwọ.

 

“Ṣugbọn si iyalẹnu mi, mo pe Ọtunba Akala, wọn si fi tayọtayọ gba lati waa pẹlu mi nibi eto yẹn. Wọn ni iranlọwọ kan ti awọn fẹ ki n ṣe fun awọn ni pe bi eto yẹn ba ti ku ọjọ meji, ki n jẹ ki awọn mọ, ki awọn le pa ohunkohun ti awọn ba fẹẹ ṣe lọjọ naa ti.

“Ti ki i baa ṣe ti iku to pa wọn mọ wa lọwọ yii, a ba jọ ṣeto yẹn ni, nitori wọn ti fun mi ni aridaju pe awọn ti ṣetan lati kopa nibẹ. Ṣugbọn ta ni wa lati ba Ọlọrun wijọ.”

Nigba to n ṣapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bii oloṣelu to sun mọ araalu ju lọ nipinlẹ Ọyọ, Gomina Makinde sọ pe “lati ori ipo alaga kansu ni wọn (Akala) ti bẹrẹ si i wa nipo akoso ijọba. Wọn ṣe igbakeji gomina, wọn ṣe adele gomina, ki wọn too waa bọ sipo gomina gan-an. Oloṣelu wo lo tun ni iru aṣeyọri bayii ni ipinlẹ yii.

L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, l’Akala dagbere faye le lẹni ọdun mọkanlelaaadọrin (71).

Ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ rẹ ṣalaye pe awọn ati oloogbe naa lawọn jọ wo bọọlu tawọn Super Eagles gba l’Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja. Lẹyin tawọn wo bọọlu naa tan lawọn kuro nile rẹ ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ. Ko si si ami kankan to fi han pe boya ara oloogbe naa ko ya.

O ni nigba ti awọn ti wọn wa nile pẹlu rẹ ko gburoo rẹ ni asiko ti wọn ti reti pe o yẹ ko ti hade sita, ti awọn ti wọn si maa n wa lọdọ rẹ ti wọn jọ maa n jẹun aarọ ti de ti wọn n reti rẹ ti wọn ko ri i ni wọn gba yara rẹ lọ.

Kayeefi lo si jẹ pe niṣe ni wọn ba ọkunrin naa lori ijokoo to fọwọ lẹran ninu yara. Nibẹ ni wọn si ti sare gbe e lọ si ileewosan, nibi ti dokita ti fidi rẹ mulẹ pe o ti ku.

Leave a Reply