Monisọla Saka
Ijọba apapọ, labẹ iṣakoso Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe awọn akẹkọọ to wa nileewe giga Fasiti, Poli ati ileewe ti wọn ti n kọ nipa iṣẹ olukọ, to jẹ tijọba apapọ nikan ni wọn yoo jẹ anfaani eto ẹyawo tijọba gbe kalẹ ni ipele akọkọ.
Gẹgẹ bi eto naa ṣe fẹẹ gbera sọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, Ọgbẹni Akintunde Sawyer, ti i ṣe ọga agba ileeṣẹ to n mojuto ẹyawo awọn akẹkọọ, Nigerian Education Loan Fund (NELFUND), ti sọ ọ di mimọ nibi ipade ilanilọyẹ ti wọn ṣe niluu Abuja, lọjọ Aje, Mọnnde, ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe awọn akẹkọọ to le diẹ ni miliọnu kan (1.2 million), nikan ni wọn yoo kọkọ janfaani eto naa.
Awọn akẹkọọ ileewe giga ijọba apapọ ti ileewe wọn ti ṣakojọ gbogbo ohun to yẹ ni mimọ nipa wọn (data), sori ayelujara ileeṣẹ NELFUND, ni wọn yoo bẹrẹ pẹlu.
Lati ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni oju opo ayelujara naa yoo ti wa ni ṣiṣi silẹ, ati pe lẹta igbaniwọle sileewe giga lati ọdọ ajọ aṣedanwo (JAMB), nọmba idanimọ orilẹ-ede yii (NIN), nọmba akanti banki (BVN) ati fọọmu tawọn ti pese silẹ lori ayelujara ni wọn sọ pe wọn yoo fi forukọ silẹ. O ni gbogbo akẹkọọ to wa nileewe giga to jẹ ti ijọba lo wa fun, amọ to jẹ labala labala ni awọn yoo ṣe e, ti tawọn to jẹ tijọba apapọ yoo si ṣaaju.
Sawyer to sọ ọ di mimọ pe ọkan lara eto to wa labẹ ‘Ireti Isọdọtun’ ti Aarẹ Tinubu kede niyi, sọ pe ọna lati ṣe iranwọ lori owo ileewe sisan fawọn akẹkọọ ti ko ni, ki wọn si le ni ṣenji lapo, lojuna ati le gbaju mọ ẹkọ wọn lai si idaamu owo nijọba ṣe ṣagbekalẹ eto yii.
Bakan naa lo fi kun un pe eto ẹyawo naa ko ni ele lori, bẹẹ ni adapada rẹ fun ijọba rọrun. Ọdun meji ti iru akẹkọọ bẹẹ ba pari isinru ilu, to si ti riṣẹ, ni yoo bẹrẹ si i maa san owo naa pada diẹdiẹ.
Ileeṣẹ yii ni yoo maa sanwo ileewe akẹkọọ bẹẹ taara si apo ileewe ọhun, ti yoo si tun maa fun akẹkọọ bẹẹ ni owo taṣẹrẹ loṣooṣu tabi lasiko ti wọn ba wa nileewe.
“Lara awọn ohun pataki ninu eto yii ni pe ko di dandan ki ileeṣẹ NELFUND ati iru akẹkọọ bẹẹ jọ pade pọ, ori itakun ayelujara ti ko mu wahala dani lati lo wa nilẹ fun wọn lati ṣe gbogbo nnkan ti wọn ba fẹ. Saa eto ẹkọ kọọkan la o fi maa sanwo ileewe akẹkọọ kọọkan, nitori awọn mi-in le fi ileewe silẹ tabi ki wọn paarọ ileewe.
A n fi asiko yii rọ awọn akẹkọọ ileewe giga ijọba apapọ kaakiri lati ṣamulo anfaani yii nipa kikọwe beere fun iye owo yoowu ti yoo ṣeranwọ fun eto ẹkọ wọn”.
O ni ki wọn tete kọwe eto yii loju ọjọ, ki wọn le bẹrẹ iṣẹ lori ẹ ni kiakia.
Sawyer tun fi awọn akẹkọọ to ba nifẹẹ si eto yii lọkan balẹ pe wọn ko nilo oniduuro tabi ẹni ti wọn le nawọ gan dipo awọn alara (guarantor).
Ohun to ni o ṣe pataki ni pe ki ileewe wọn pese gbogbo ohun to ba yẹ nipa wọn sori ayelujara awọn.
Lojuna ati dena kudiẹ-kudiẹ ati ohun yoowu to le ba eto yii jẹ, adari ileeṣẹ NELFUND ni awọn ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ileeṣẹ adojutofo ati awọn ileeṣẹ eto aabo fun itọsọna to yẹ, nitori awọn ti yoo ba lu jibiti pẹlu ẹ.