Eyi ni ọgbọn ti awọn ajinigbe tun n lo lati ji awọn  ọmọọleewe gbe n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati le bọ lọwọ ete awọn ajinigbe, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti gba awọn obi ati alagbatọ nimọran lati maa kọ fun awọn onimọto aladaani to ba nawọ iranlọwọ si wọn lati ba wọn gbe ọmọ wọn lọ sileewe lọfẹẹ nitori ọna ti awọn ajinigbe n gba ji awọn ọmọọleewe gbe lasiko yii niyẹn.

Akọwe agba ẹka to n mojuto akanṣe iṣẹ lọfiisi Gomina Ṣeyi Makinde, Abilekọ A.B. Atẹrẹ, lo ṣekilọ ọhun ninu atẹjade kan to fọwọ si, to si fi ṣọwọ si gbogbo ẹka alamoojuto eto ẹkọ (TESCOM) nijọba ibilẹ gbogbo kaakiri ipinlẹ Ọyọ lopin ọsẹ yii.

Ọgbọn buruku ti wọn lawọn ọbayejẹ eeyan ọhun n da bayii ni lati maa wọ aṣọ ileewe kan fun ọmọ wọn kan tabi meji kaakiri lati dọgbọn ji awọn ọmọọleewe gbe, paapaa niluu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Niṣe lawọn olubi eeyan yii yoo mori le ọna ileewe to n lo iru aṣọ sukuu ti wọn wọ fun ọmọ wọn yii. Bi wọn ba waa ri obi tabi alagbatọ to n mu ọmọ rẹ lọ sileewe jẹẹjẹ, lọgan ni wọn yoo duro lati ba wọn fi mọto gbe iru ọmọ bẹẹ, niwọn igba to jẹ pe nibẹ naa lawọn paapaa n gbe ọmọ awọn to wa ninu ọkọ naa lọ.

Wọn lọpọ obi lo ti fara mọ iru iranlọwọ ojiji bẹẹ tan ki wọn too mọ pe ajinigbe pọnbele lonimọto naa nigba ti wọn ko ba gburoo ọmọ wọn nile mọ, ti awọn ọga ileewe si sọ pe awọn ko ri ọmọ ọhun ni sukuu lọjọ naa.

Gẹgẹ bo ṣe wa nunu atẹjade ọhun, “ọna ti awọn ajinigbe n gba ji awọn ọmọde, paapaa, awọn omọọleewe gbe ni lati wọ aṣọ ileewe kan fọmọ wọn ti wọn ba gbe sinu mọto lati tan awọn akẹkọọ to ba n lọ siru ileewe bẹẹ jẹ ki wọn le ri wọn ji gbe.”

Ijọba waa gba awọn obi atalagbatọ gbogbo ni ipinlẹ naa nimọran lati la awọn ọmọ wọn lọyẹ nipa ọgbọn ijanba tuntun tawọn ajinigbe n lo yii.

Leave a Reply