Ọlawale Ajao, Ibadan
Nitori oniruuru iwa ọdaran to ti ṣẹlẹ latari egboogi oloro, eyi to ti gbẹmi ọpọ èèyàn, to si ti sọ ajmọye eeyan di alaisan ọpọlọ, ajọ
to n gbogun ti egboogi oloro nilẹ yii, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ẹka tipinlẹ Ọyọ, ti ṣawari ọna lati fopin si ijanba ti egboogi ọloro n ṣe lawujọ.
Nigba to n sọrọ nibi ayajọ egboogi oloro lagbaaye, eyi to waye nileegbimọ awọn lọbalọ, ninu ọgba Sẹkiteriati ipinlẹ Ọyọ, l’Agodi, n’Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2024 yii, adari ajọ NDLEA, Ọgbẹni Ọlayinka Joe-Fadile, sọ pe lati maa fi panpẹ ọba gbe awọn oniṣowo egboogi oloro atawọn to n gbe kinni buruku ọhun lura ki i ṣe ọna to daa to lati gbogun ti okoowo yii.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ọna to dara ju ni lati maa dena egboogo oloro funra rẹ. Eyi ni ko ni i jẹ ko ṣe e ṣe fun awọn to n lo o lọna aitọ lati maa ri i.”
“A mọ pe a ko le da iṣẹ yii ṣe laṣeyọri lai jẹ pe awọn araalu fọwọsowọpọ pẹlu wa. Nitori idi eyi, a ti bẹrẹ ilanilọyẹ fawọn eeyan, awọn adugbo to to ọrinlelọọọọrun, o din meji (378) ọtọọtọ la ti ṣe ilanilọyẹ de, nnkan bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un (100,000) eeyan la si ti ṣalaye fun nipa ọna lati dena lilo egboogi oloro lawujọ.
“Aarin awọn eeyan laarin ilu naa lawọn oniṣowo egboogi oloro n gbe. Idi ree ta a ṣe ni lati ro awọn eeyan adugbo kọọkan lagbara lati le dena okoowo oogun oloro ati ilokulo oogun lawujọ”.
Kọmiṣanna feto ilera nipinlẹ Ọyọ, Dokita Oluwaṣẹrimi Ajetunmọbi, kín ọrọ naa lẹyin, o ni ọna to daa ju lati gbogun ti egboogi oloro ati ilokulo oogun naa ni lati wa ọna ọna ti awọn eeyan ko fi ni i lanfaani si awọn nnkan buruku wọnyi.
O ni nitori ẹ nijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ṣagbekalẹ ẹgbẹ ti yoo maa gbogun ti egboogi oloro ati ilokulo oogun kaakiri awọn ileewe ijọba jake-jado ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa nipinlẹ naa, ati pe aadọjọ (150) ileewe lẹgbẹ ọhun ti wa bayii.
ALAROYE gbọ pe gbogbo ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹfa, lajọ iṣọkan gbaye (UN, ya sọtọ fun ayajọ egboogi oloro kaakiri agbaye.
Lara awọn to kopa nibi eto ọhun ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera, awọn akẹkọọ, awọn àgùnbánirọ̀, atawọn aṣoju ileeṣẹ eto aabo gbogbo nipinlẹ Ọyọ.
Ninu idanilẹkọọ to ṣe nibi eto naa, olukọ imọ nipa arun ọpọlọ ati aloju oogun ni University of Ibadan, Ọjọgbọn Victor Laṣebikan, ṣalaye pe o ṣe pataki fun awọn eeyan lati ni imọ nipa awọn nnkan to le ṣakoba fun ilera wọn, nitori aini iru imọ bẹẹ lo n fa ilokulo oogun ati egboogi oloro, eyi to n da ọpọ eeyan lori ru, to si n ya awọn mi-in paapaa ni were patapata.
Ṣaaju loludari ẹka to n ri si ọrọ oogun lilo nileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Moses Adewọle, ti sọ pe afojusun apero ọhun ni lati fopin si bi awọn eeyan ṣe n lo egboogi oloro ati ilokulo oogun, nitori iwa ọdaran ati ohun aburu gbogbo ti iru igbesẹ bẹẹ n fa lawujọ.
ṣẹrimi Ajetunmọbi; Igbakeji ọga ajọ NDLEA, Ọgbẹni Anteyi John; akọwe agba ni ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Ọyọ, Dokita Kẹhinde Ayinde; ati Dokita Anifa Ibrahim, to jẹ akọwe agba igbimọ yo n ṣakoso awọn ileewosan ni ipinlẹ naa nigba ti won n kopa nibi eto ọhun.