Eyi ni ọrọ idaro ti iyawo Yinka Odumakin kọ nipa ọkọ rẹ

 

”To ba jẹ ka mi sinu mi sita la n na bii owo laye, aa jẹ pe lori ko le daa ni Yinka na eemi tiẹ si.

”Awọn dokita ni eemi to n mi ti n dinku jọjọ, ṣugbọn niṣe lọkọ mi ni ki wọn ba oun gbe kọmputa ti yoo fi kọ abala to maa n kọ loju iwe iroyin wa.

”Oun ki i ṣọ eemi rẹ lo to ba jẹ ti ka na an lori ọrọ ile aye rẹ ti i ṣe Yoruba, ati lori Naijiria, ayanfẹ rẹ tootọ.

”Mo ṣi n ranti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọ̀rọ̀ ifẹ wa pẹlu ọgbẹ́ ọkan to pọ, ifẹ to bẹrẹ ninu akolo Sanni Abacha.

”Ọkọ mi ki i ṣe ọdaran, emi naa ki i ṣe arufin pẹlu. Ẹṣẹ wa naa ko ju ti pe a n ja fẹtọọ, a n ṣaaju fun ara yooku gẹgẹ ba a ṣe ri latilẹ aye wa. A o ṣi pada maa ranti iriri wa ninu awọn atimọle naa to ba ya.

”Ta lẹni naa to pade ololufẹ tiẹ l’Alagbọn?Yinka nikan naa lo fọrọ ifẹ lọọyan nibẹ, emi naa si lobinrin kan ṣoṣo ti yoo jẹ ‘hoo’ fun un.

”Agba ọjẹ lọọya nni, ẹni to jẹ olori awa ẹlewọn ta a n bu ọla fun, Oloye Gani Fawẹhinmi( SAM , SAN) lo mu wa mọra wa.

Isọpo wa jẹ ti ajijagbara meji ti olori Àlùfáà ta a jọ wa ninu ijangbara yii so pọ, ta a si fi ibuba ṣe pẹpẹ igbeyawo wa, ti wiwa rere awọn eeyan wa si jẹ afojusun wa.

”Oloye sọ nipa mi fun Yinka pe ‘Yinka, ọkunrin ni.’ Atakọ atabo to wa lara mi ni Yinka fẹ!

”Igbeyawo ijijangbara la ṣe, igbiyanju la fi ṣakọkọ, ba o si ṣe ri daadaa ṣe fawọn eeyan wa ni lajọri ajọṣepọ wa.

 

”Yinka, o digba kọ, o daarọ ni, n oo ri ọ lodi keji lọdọ Ọlọrun Ọba.

”N o maa ṣeranti ojiji rẹ to o ya silẹ, n o maa yọ ninu rẹ lọ lai wẹyin rara.

”Nigba to jẹ wọn ki i gba ẹnikẹni laaye lati duro ti alaaarẹ lẹka iwosan nla to o wa (ICU) a fi ọ silẹ sọwọ itọju awọn agba dokita ni LASUTH, a fi ọ le Ọlọrun lọwọ pẹlu ireti pe a oo ri ọ laaarọ ọjọ keji.

”Awọn dokita lawọn ko mọ bawọn yoo ṣe tufọ iku rẹ fun mi lojukoju.

”Ni bayii ti iwe-ẹri iku rẹ ti wọn kọ lọsibitu ti wa lọwọ mi, mo ri i pe aago mọkanla ku ogun iṣẹju lo jade laye lalẹ ọjọ Ẹti rere (Good Friday) ( Iyẹn ọjọ keji, oṣu kẹrin, ọdun 2021). ”Ki i ṣe laaarọ ọjọ Satide, ọjọ kẹta, oṣu kẹrin, 2021.

”Nitori ilana sisọ otitọ ati sisọ nnkan bo ba ṣe ri, eyi ti Yinka ati emi funra mi fẹran pupọ- ti Yinka si fi gbogbo igbesi aye ẹ ni agba ṣe- o ṣe pataki lati jẹ kẹ ẹ mọ eyi ti i ṣe ọjọ iku rẹ gan- an.

”O waye, o jagun, o ṣẹgun!!! Titi lae la oo maa ba iṣẹ yii lọ, gẹ́gẹ́ bi awọn aṣaaju wa ṣe maa n wi. Naijiria ko ni i parun, Naijiria yoo yipada, yoo si di ilu nla. Naijiria yoo bọ si i nigba aye mi ati ni tiẹ naa paapaa, pẹlu bo o ṣe n gbe inu mi, inu awọn ọmọ wa atawọn ọmọ ti ko ti i waye rara.

Ọmọwe Joe Okei-Odumakin Tusidee, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa, oṣu kerin, 2021

Leave a Reply