Monisọla Saka
Ileeṣẹ Aarẹ ti ni irọ nla to jinna si ootọ ni iroyin to n lọ kiri pe Ọgbẹni Wale Ẹdun, ti i ṣe minisita feto inawo nilẹ yii, ti gbe ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ati marun-un Naira (105,000), siwaju ijọba apapọ gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju ti wọn ni ko ṣiṣẹ le lori.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Oludamọran pataki si Aarẹ lori ọrọ iroyin, Bayọ Ọnanuga, fọrọ naa lede.
O ni, “Minisita feto inawo, to tun n dari eto ọrọ aje, Wale Ẹdun, ko ti i dabaa ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un ati marun-un Naira gẹgẹ bii owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ. Iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin to n kaakiri ọhun”.
Ko too di ọsan Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu yii, ni Ẹdun ti gbe abọ iwadii rẹ ati aba lori ọrọ owo-oṣu oṣiṣẹ tuntun siwaju Aarẹ, ni ibamu pẹlu gbedeke oni wakati mejidinlaaadọta, ti Aarẹ fun un lati ṣiṣẹ naa, ṣugbọn ti ikede ko ti i jade lati ọdọ ijọba lori iye ti owo naa jẹ.
Wale Ẹdun, ati minisita feto iṣuna nilẹ wa, Atiku Bagudu, ni wọn dijọ gbe aba naa siwaju Aarẹ Tinubu, titi kan iye ti owo-oṣu tuntun naa yoo na wọn nile ijọba l’Abuja, amọ ti wọn ni iroyin to n lọ kiri lori iye ti owo naa yoo jẹ ki i ṣe lati ileeṣẹ ijọba.
Bo tilẹ jẹ pe abọ iwadii ti wa niwaju Aarẹ bayii, wọn ni abẹ ayẹwo lo ṣi wa, nitori bẹẹ ni wọn ko ṣe ti i kede rẹ seti araalu.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrin, oṣu yii, ni apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ lorilẹ-ede yii, Nigerian Labour Congress (NLC), ati ẹgbẹ awọn oniṣowo, Trade Union Congress (TUC), so iyanṣẹlodi to mi gbogbo ilu titi kọ fun ọjọ marun-un, lẹyin ti ijọba apapọ gba lati gbọn ọwọ si ẹgbẹrun lọna ọgọta Naira, (60,000) ti wọn ta ku pe awọn fẹ maa san.