Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Afurasi kan, Farouq Halidu, to lẹdi apopọ pẹlu aburo ẹ, Aliyu Halidu, ti wọn fi du ibatan wọn, Idris Hamah, bii ẹran Ileya, ti wọn si ji ọkada rẹ, ti sọ fun ile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ ọjọ kejidinlọgbọn, osu Kẹta, ọdun yii, pe kadara lo ṣokunfa bi oun pẹlu aburo oun ṣe ṣeku pa ibatan awọn ti awọn du bii ẹran.
Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka tipinlẹ Kwara, lo wọ tẹgbọn-taburo naa, Halidu Farouq ati aburo ẹ, Halidu Aliyu, lọ siwaju ile-ẹjọ kan niluu Ilọrin, fẹsun ipawọpọ huwa ọdaran, ipaniyan, ati idigunjale, leyii to ta ko iwe ofin ilẹ wa.
Agbefọba, Innocent Owoọla, sọ fun ile-ẹjọ pe awọn ọdaran mejeeji yii ni wọn lọọ dena de ibatan wọn, Hamah, lopopona ọja Gwasera, nijọba ibilẹ Baruten, wọn n lu u nigi titi ti ẹmi fi bọ lara ẹ, lẹyin naa ni wọn mu ọbẹ, ti wọn si du u lọrun bii ẹran, ni wọn ba ji ọkada Bajaj rẹ lọ.
Awọn Afurasi mejeeji gba pe loootọ lawọn jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Onidaajọ Ọmọtayọ Adebosin, paṣẹ pe ki wọn lọọ sọ awọn afurasi mejeeji satimọle, o sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2023 yii.